< Exodus 34 >

1 Olúwa sọ fún Mose pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, Èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn.
ויאמר יהוה אל משה פסל לך שני לחת אבנים כראשנים וכתבתי על הלחת את הדברים אשר היו על הלחת הראשנים אשר שברת׃
2 Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Sinai. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà.
והיה נכון לבקר ועלית בבקר אל הר סיני ונצבת לי שם על ראש ההר׃
3 Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.”
ואיש לא יעלה עמך וגם איש אל ירא בכל ההר גם הצאן והבקר אל ירעו אל מול ההר ההוא׃
4 Bẹ́ẹ̀ Mose sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sinai lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀.
ויפסל שני לחת אבנים כראשנים וישכם משה בבקר ויעל אל הר סיני כאשר צוה יהוה אתו ויקח בידו שני לחת אבנים׃
5 Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọsánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa.
וירד יהוה בענן ויתיצב עמו שם ויקרא בשם יהוה׃
6 Ó sì kọjá níwájú Mose, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,
ויעבר יהוה על פניו ויקרא יהוה יהוה אל רחום וחנון ארך אפים ורב חסד ואמת׃
7 Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún, ó sì ń dáríjì àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń ṣọ̀tẹ̀ àti ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ẹ̀kẹrin.”
נצר חסד לאלפים נשא עון ופשע וחטאה ונקה לא ינקה פקד עון אבות על בנים ועל בני בנים על שלשים ועל רבעים׃
8 Mose foríbalẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà ó sì sìn.
וימהר משה ויקד ארצה וישתחו׃
9 Ó wí pé, “Olúwa, bí èmi bá rí ojúrere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí Olúwa lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”
ויאמר אם נא מצאתי חן בעיניך אדני ילך נא אדני בקרבנו כי עם קשה ערף הוא וסלחת לעוננו ולחטאתנו ונחלתנו׃
10 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ Èmi yóò ṣe ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀-èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrín wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí Èmi Olúwa yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó.
ויאמר הנה אנכי כרת ברית נגד כל עמך אעשה נפלאת אשר לא נבראו בכל הארץ ובכל הגוים וראה כל העם אשר אתה בקרבו את מעשה יהוה כי נורא הוא אשר אני עשה עמך׃
11 Ṣe ohun tí Èmi pàṣẹ fún ọ lónìí. Èmi lé àwọn ará Amori, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hiti, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi jáde níwájú rẹ.
שמר לך את אשר אנכי מצוך היום הנני גרש מפניך את האמרי והכנעני והחתי והפרזי והחוי והיבוסי׃
12 Máa ṣọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ̀ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdẹwò láàrín rẹ.
השמר לך פן תכרת ברית ליושב הארץ אשר אתה בא עליה פן יהיה למוקש בקרבך׃
13 Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Aṣerah wọn. (Ère òrìṣà wọn.)
כי את מזבחתם תתצון ואת מצבתם תשברון ואת אשריו תכרתון׃
14 Ẹ má ṣe sin ọlọ́run mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ Òjòwú, Ọlọ́run owú ni.
כי לא תשתחוה לאל אחר כי יהוה קנא שמו אל קנא הוא׃
15 “Máa ṣọ́ra kí ẹ má ṣe bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, tí wọ́n sì rú ẹbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.
פן תכרת ברית ליושב הארץ וזנו אחרי אלהיהם וזבחו לאלהיהם וקרא לך ואכלת מזבחו׃
16 Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò ṣe àgbèrè tọ òrìṣà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
ולקחת מבנתיו לבניך וזנו בנתיו אחרי אלהיהן והזנו את בניך אחרי אלהיהן׃
17 “Ìwọ kò gbọdọ̀ dá ère òrìṣàkórìṣà fún ara rẹ.
אלהי מסכה לא תעשה לך׃
18 “Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí Èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú oṣù Abibu, nítorí ní oṣù náà ni ẹ jáde láti Ejibiti wá.
את חג המצות תשמר שבעת ימים תאכל מצות אשר צויתך למועד חדש האביב כי בחדש האביב יצאת ממצרים׃
19 “Gbogbo àkọ́bí inú kọ̀ọ̀kan tèmi ní i ṣe, pẹ̀lú àkọ́bí gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ, bóyá ti màlúù tàbí ti àgùntàn.
כל פטר רחם לי וכל מקנך תזכר פטר שור ושה׃
20 Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́-àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá síwájú mi ní ọwọ́ òfo.
ופטר חמור תפדה בשה ואם לא תפדה וערפתו כל בכור בניך תפדה ולא יראו פני ריקם׃
21 “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ keje ìwọ yóò sinmi; kódà ní àkókò ìfúnrúgbìn àti ní àkókò ìkórè ìwọ gbọdọ̀ sinmi.
ששת ימים תעבד וביום השביעי תשבת בחריש ובקציר תשבת׃
22 “Ṣe àjọ ọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àkọ́so èso alikama àti àjọ ìkórè ní òpin ọdún.
וחג שבעת תעשה לך בכורי קציר חטים וחג האסיף תקופת השנה׃
23 Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa Olódùmarè, Ọlọ́run Israẹli.
שלש פעמים בשנה יראה כל זכורך את פני האדן יהוה אלהי ישראל׃
24 Èmi yóò lé orílẹ̀-èdè jáde níwájú rẹ, Èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.
כי אוריש גוים מפניך והרחבתי את גבולך ולא יחמד איש את ארצך בעלתך לראות את פני יהוה אלהיך שלש פעמים בשנה׃
25 “Má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sí mi pẹ̀lú ohunkóhun tí ó bá ní ìwúkàrà, kí o má sì ṣe jẹ́ kí ẹbọ ìrékọjá kù títí di òwúrọ̀.
לא תשחט על חמץ דם זבחי ולא ילין לבקר זבח חג הפסח׃
26 “Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.”
ראשית בכורי אדמתך תביא בית יהוה אלהיך לא תבשל גדי בחלב אמו׃
27 Olúwa sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.”
ויאמר יהוה אל משה כתב לך את הדברים האלה כי על פי הדברים האלה כרתי אתך ברית ואת ישראל׃
28 Mose wà níbẹ̀ pẹ̀lú Olúwa fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru láìjẹ oúnjẹ tàbí mu omi. Ó sì kọ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú náà òfin mẹ́wàá sára wàláà.
ויהי שם עם יהוה ארבעים יום וארבעים לילה לחם לא אכל ומים לא שתה ויכתב על הלחת את דברי הברית עשרת הדברים׃
29 Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Sinai pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀.
ויהי ברדת משה מהר סיני ושני לחת העדת ביד משה ברדתו מן ההר ומשה לא ידע כי קרן עור פניו בדברו אתו׃
30 Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn.
וירא אהרן וכל בני ישראל את משה והנה קרן עור פניו וייראו מגשת אליו׃
31 Ṣùgbọ́n Mose pè wọn; Aaroni àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.
ויקרא אלהם משה וישבו אליו אהרן וכל הנשאים בעדה וידבר משה אלהם׃
32 Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún un lórí òkè Sinai.
ואחרי כן נגשו כל בני ישראל ויצום את כל אשר דבר יהוה אתו בהר סיני׃
33 Nígbà tí Mose parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.
ויכל משה מדבר אתם ויתן על פניו מסוה׃
34 Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí Mose bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli ohun tí a ti pàṣẹ fún un,
ובבא משה לפני יהוה לדבר אתו יסיר את המסוה עד צאתו ויצא ודבר אל בני ישראל את אשר יצוה׃
35 àwọn ọmọ Israẹli sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mose á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.
וראו בני ישראל את פני משה כי קרן עור פני משה והשיב משה את המסוה על פניו עד באו לדבר אתו׃

< Exodus 34 >