< Exodus 28 >
1 “Ìwọ sì mú Aaroni arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárín àwọn ọmọ Israẹli, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nadabu, Abihu, Eleasari, àti Itamari, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
“Next, have your brother Aaron brought to you from among the Israelites, along with his sons Nadab, Abihu, Eleazar, and Ithamar, to serve Me as priests.
2 Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá.
Make holy garments for your brother Aaron, to give him glory and splendor.
3 Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Aaroni, fún ìyàsímímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
You are to instruct all the skilled craftsmen, whom I have filled with a spirit of wisdom, to make garments for Aaron’s consecration, so that he may serve Me as priest.
4 Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù efodu, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Aaroni arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
These are the garments that they shall make: a breastpiece, an ephod, a robe, a woven tunic, a turban, and a sash. They are to make these holy garments for your brother Aaron and his sons, so that they may serve Me as priests.
5 Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.
They shall use gold, along with blue, purple, and scarlet yarn, and fine linen.
6 “Wọn yóò sì dá ẹ̀wù efodu ti wúrà, tí aṣọ aláró, elése àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́, iṣẹ́ ọlọ́nà.
They are to make the ephod of finely spun linen embroidered with gold, and with blue, purple, and scarlet yarn.
7 Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.
It shall have two shoulder pieces attached at two of its corners, so it can be fastened.
8 Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.
And the skillfully woven waistband of the ephod must be of one piece, of the same workmanship—with gold, with blue, purple, and scarlet yarn, and with finely spun linen.
9 “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkìsì méjì, ìwọ yóò sì fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sára wọn.
Take two onyx stones and engrave on them the names of the sons of Israel:
10 Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì.
six of their names on one stone and the remaining six on the other, in the order of their birth.
11 Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.
Engrave the names of the sons of Israel on the two stones the way a gem cutter engraves a seal. Then mount the stones in gold filigree settings.
12 Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.
Fasten both stones on the shoulder pieces of the ephod as memorial stones for the sons of Israel. Aaron is to bear their names on his two shoulders as a memorial before the LORD.
13 Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà,
Fashion gold filigree settings
14 àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.
and two chains of pure gold, made of braided cord work; and attach these chains to the settings.
15 “Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinnu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù efodu ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára.
You are also to make a breastpiece of judgment with the same workmanship as the ephod. Construct it with gold, with blue, purple, and scarlet yarn, and with finely spun linen.
16 Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ìka kan ní ìnà àti ìwọ̀n ìka kan ní ìbú, kí o sì ṣe é ní ìṣẹ́po méjì.
It must be square when folded over double, a span long and a span wide.
17 Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta oníyebíye mẹ́rin sára ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, topasi àti berili wà;
And mount on it a setting of gemstones, four rows of stones: In the first row there shall be a ruby, a topaz, and an emerald;
18 ní ẹsẹ̀ kejì turikuose, emeradi, safire, àti diamọndi;
in the second row a turquoise, a sapphire, and a diamond;
19 ní ẹsẹ̀ kẹta, jasiniti, agate, àti ametisiti;
in the third row a jacinth, an agate, and an amethyst;
20 ní ẹsẹ̀ kẹrin, topasi, àti óníkìsì àti jasperi. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn.
and in the fourth row a beryl, an onyx, and a jasper. Mount these stones in gold filigree settings.
21 Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
The twelve stones are to correspond to the names of the sons of Israel, each engraved like a seal with the name of one of the twelve tribes.
22 “Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò ṣe okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè.
For the breastpiece, make braided chains like cords of pure gold.
23 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà.
You are also to make two gold rings and fasten them to the two corners of the breastpiece.
24 Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà,
Then fasten the two gold chains to the two gold rings at the corners of the breastpiece,
25 àti etí ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù efodu náà níwájú.
and fasten the other ends of the two chains to the two filigree settings, attaching them to the shoulder pieces of the ephod at the front.
26 Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì ìgbàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù efodu náà.
Make two more gold rings and attach them to the other two corners of the breastpiece, on the inside edge next to the ephod.
27 Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù efodu méjèèjì ní ìsàlẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó súnmọ́ ojú sí ìránṣọ náà, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu náà.
Make two additional gold rings and attach them to the bottom of the two shoulder pieces of the ephod, on its front, near its seam just above its woven waistband.
28 Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù efodu pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù efodu náà.
The rings of the breastpiece shall be tied to the rings of the ephod with a cord of blue yarn, so that the breastpiece is above the waistband of the ephod and does not swing out from the ephod.
29 “Nígbàkígbà tí Aaroni bá wọ Ibi Mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinnu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.
Whenever Aaron enters the Holy Place, he shall bear the names of the sons of Israel over his heart on the breastpiece of judgment, as a continual reminder before the LORD.
30 Bákan náà ìwọ yóò sì mu Urimu àti Tumimu sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Aaroni nígbàkígbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Aaroni yóò sì máa ru ohun ti a ń fi ṣe ìpinnu fún àwọn ọmọ Israẹli ní ọkàn rẹ̀ nígbà gbogbo níwájú Olúwa.
And place the Urim and Thummim in the breastpiece of judgment, so that they will also be over Aaron’s heart whenever he comes before the LORD. Aaron will continually carry the judgment of the sons of Israel over his heart before the LORD.
31 “Ìwọ yóò ṣì ṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù efodu náà ní kìkì aṣọ aláró,
You are to make the robe of the ephod entirely of blue cloth,
32 pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrín rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìṣẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.
with an opening at its top in the center. Around the opening shall be a woven collar with an opening like that of a garment, so that it will not tear.
33 Ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú ṣaworo wúrà láàrín wọn.
Make pomegranates of blue, purple, and scarlet yarn all the way around the lower hem, with gold bells between them,
34 Àwọn ṣaworo wúrà àti àwọn pomegiranate ni kí ó yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.
alternating the gold bells and pomegranates around the lower hem of the robe.
35 Aaroni gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń ṣiṣẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ Ibi Mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.
Aaron must wear the robe whenever he ministers, and its sound will be heard when he enters or exits the sanctuary before the LORD, so that he will not die.
36 “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fínfín èdìdì àmì pé. Mímọ́ sí Olúwa.
You are to make a plate of pure gold and engrave on it as on a seal: HOLY TO THE LORD.
37 Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà.
Fasten to it a blue cord to mount it on the turban; it shall be on the front of the turban.
38 Kí ó wà níwájú orí Aaroni, kí ó sì lè máa ru ẹ̀bi tí ó jẹ mọ́ ẹ̀bùn mímọ́ ti àwọn ọmọ Israẹli ti yà sí mímọ́, èyíkéyìí tí ẹ̀bùn wọn lè jẹ́. Yóò máa wà níwájú orí Aaroni nígbà gbogbo, kí wọn lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa.
And it will be worn on Aaron’s forehead, so that he may bear the iniquity of the holy things that the sons of Israel consecrate with regard to all their holy gifts. It shall always be on his forehead, so that they may be acceptable before the LORD.
39 “Ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára hun ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fi ọ̀gbọ̀ dáradára ṣe fìlà. Ìwọ yóò sì fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ọ̀já àmùrè.
You are to weave the tunic with fine linen, make the turban of fine linen, and fashion an embroidered sash.
40 Ìwọ yóò sì dá ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀já àmùrè àti ìgbàrí fún àwọn ọmọ Aaroni, láti fún wọn ní ọ̀ṣọ́ àti ọlá.
Make tunics, sashes, and headbands for Aaron’s sons, to give them glory and splendor.
41 Lẹ́yìn tí ìwọ ti fi àwọn aṣọ wọ̀nyí wọ Aaroni arákùnrin rẹ, ìwọ yóò sì fi wọ àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ ó ta òróró sí wọn ní orí, ìwọ yóò sì ya wọ́n sí mímọ́. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, kí wọn kí o lè máa ṣe iṣẹ́ àlùfáà.
After you put these garments on your brother Aaron and his sons, anoint them, ordain them, and consecrate them so that they may serve Me as priests.
42 “Ìwọ yóò dá ṣòkòtò ọ̀gbọ̀ fún wọn, kí wọn lè máa fi bo ìhòhò wọn, kí ó dé ìbàdí dé itan.
Make linen undergarments to cover their bare flesh, extending from waist to thigh.
43 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọ̀ wọ́n nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ lọ tàbí nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́ kí wọn kí ó má ba à dẹ́ṣẹ̀, wọn a sì kú. “Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún Aaroni àti fún irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
Aaron and his sons must wear them whenever they enter the Tent of Meeting or approach the altar to minister in the Holy Place, so that they will not incur guilt and die. This is to be a permanent statute for Aaron and his descendants.