< Exodus 24 >

1 Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Gòkè tọ Olúwa wá, ìwọ àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.
耶和华对摩西说:“你和亚伦、拿答、亚比户,并以色列长老中的七十人,都要上到我这里来,远远地下拜。
2 Ṣùgbọ́n Mose nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ Olúwa; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”
惟独你可以亲近耶和华;他们却不可亲近;百姓也不可和你一同上来。”
3 Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin Olúwa, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti Olúwa wí ni àwa yóò ṣe.”
摩西下山,将耶和华的命令典章都述说与百姓听。众百姓齐声说:“耶和华所吩咐的,我们都必遵行。”
4 Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí Olúwa sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.
摩西将耶和华的命令都写上。清早起来,在山下筑一座坛,按以色列十二支派立十二根柱子,
5 Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si Olúwa.
又打发以色列人中的少年人去献燔祭,又向耶和华献牛为平安祭。
6 Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.
摩西将血一半盛在盆中,一半洒在坛上;
7 Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí Olúwa wí. Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.”
又将约书念给百姓听。他们说:“耶和华所吩咐的,我们都必遵行。”
8 Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Olúwa ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
摩西将血洒在百姓身上,说:“你看!这是立约的血,是耶和华按这一切话与你们立约的凭据。”
9 Mose àti Aaroni, Nadabu àti Abihu àti àádọ́rin àwọn àgbàgbà Israẹli gòkè lọ.
摩西、亚伦、拿答、亚比户,并以色列长老中的七十人,都上了山。
10 Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀.
他们看见以色列的 神,他脚下仿佛有平铺的蓝宝石,如同天色明净。
11 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbàgbà Israẹli wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
他的手不加害在以色列的尊者身上。他们观看 神;他们又吃又喝。
12 Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhìn-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní wàláà òkúta pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”
耶和华对摩西说:“你上山到我这里来,住在这里,我要将石版并我所写的律法和诫命赐给你,使你可以教训百姓。”
13 Nígbà náà ni Mose jáde lọ pẹ̀lú Joṣua arákùnrin rẹ̀. Mose lọ sí orí òkè Ọlọ́run.
摩西和他的帮手约书亚起来,上了 神的山。
14 Ó sì wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsi i, Aaroni àti Huri ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnìkan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.”
摩西对长老说:“你们在这里等着,等到我们再回来,有亚伦、户珥与你们同在。凡有争讼的,都可以就近他们去。”
15 Nígbà tí Mose gun orí òkè lọ, ìkùùkuu bo orí òkè náà.
摩西上山,有云彩把山遮盖。
16 Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Sinai. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mose láti inú ìkùùkuu náà wá.
耶和华的荣耀停于西奈山;云彩遮盖山六天,第七天他从云中召摩西。
17 Ni ojú àwọn ọmọ Israẹli ògo Olúwa náà dàbí iná ajónirun ni orí òkè.
耶和华的荣耀在山顶上,在以色列人眼前,形状如烈火。
18 Nígbà náà ni Mose wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
摩西进入云中上山,在山上四十昼夜。

< Exodus 24 >