< Exodus 23 >

1 “Ìwọ kò gbọdọ̀ tan ìròyìn èké kalẹ̀. Ìwọ kò gbọdọ̀ ran ènìyàn búburú lọ́wọ́ láti jẹ́rìí èké.
« Tu ne répandras pas de fausses nouvelles. Ne joins pas ta main au méchant pour être un témoin malveillant.
2 “Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ṣe aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn.
« Tu ne suivras pas une foule pour faire le mal. Tu ne témoigneras pas au tribunal pour te ranger du côté d'une multitude afin de pervertir la justice.
3 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúsàájú sí tálákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.
Tu ne favoriseras pas un pauvre dans sa cause.
4 “Bí ìwọ bá ṣe alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀tá rẹ tí ó ṣìnà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un.
« Si tu rencontres le bœuf de ton ennemi ou son âne qui s'égare, tu le ramèneras à lui.
5 Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó kórìíra rẹ tí ẹrù ṣubú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.
Si tu vois l'âne de celui qui te hait tomber sous son fardeau, ne le laisse pas. Tu l'aideras à le porter.
6 “Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo.
« Tu ne refuseras pas la justice à tes pauvres gens dans leurs procès.
7 Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbí olódodo ènìyàn, nítorí Èmi kò ní dá ẹlẹ́bi láre.
« Éloigne-toi d'une fausse accusation, et ne tue pas l'innocent et le juste, car je ne justifierai pas les méchants.
8 “Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ń fọ́ ojú ọlọ́gbọ́n, ó sì ń ba ọ̀rọ̀ olódodo jẹ́.
« Tu ne prendras pas de pot-de-vin, car le pot-de-vin aveugle les voyants et pervertit les paroles des justes.
9 “Ìwọ kò gbọdọ̀ pọ́n àjèjì kan lójú, ẹ̀yin sa ti mọ inú àjèjì, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti.
« Tu n'opprimeras pas l'étranger, car tu connais le cœur de l'étranger, puisque vous étiez étrangers au pays d'Égypte.
10 “Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀.
« Pendant six ans, tu ensemenceras ta terre et tu en recueilleras le produit,
11 Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni tálákà láàrín yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà àjàrà rẹ àti ọgbà olifi rẹ.
mais la septième année, tu la laisseras en repos et en jachère, afin que les pauvres de ton peuple puissent manger; et ce qu'ils laisseront, les animaux des champs le mangeront. De même, tu traiteras ta vigne et ton oliveraie de la même manière.
12 “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.
« Six jours tu feras ton travail, et le septième jour tu te reposeras, afin que ton bœuf et ton âne se reposent, et que le fils de ton serviteur et l'étranger se rafraîchissent.
13 “Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má ṣe pe orúkọ òrìṣà, kí a má ṣe gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.
« Prends garde de faire tout ce que je t'ai dit; n'invoque pas le nom d'autres dieux et ne les fais pas entendre de ta bouche.
14 “Ní ìgbà mẹ́ta ni ìwọ yóò ṣe àjọ fún mi nínú ọdún.
« Vous célébrerez une fête en mon honneur trois fois par an.
15 “Ṣe àjọ àkàrà àìwú; jẹ àkàrà ti kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje, bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní àkókò tí a ti yàn ní oṣù Abibu, nítorí ni oṣù yìí ni ìwọ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.
Vous observerez la fête des pains sans levain. Pendant sept jours, vous mangerez des pains sans levain, comme je vous l'ai ordonné, au moment fixé dans le mois d'Abib (car c'est pendant ce mois que vous êtes sortis d'Égypte), et personne ne se présentera devant moi à vide.
16 “Ṣe àjọ ìkórè pẹ̀lú èso àkọ́so ọ̀gbìn oko rẹ. “Ṣe àjọ àkójọ oko rẹ ní òpin ọdún, nígbà tí ìwọ bá kó ìre oko rẹ jọ tan.
Et la fête de la moisson, des prémices de vos travaux, que vous avez semés dans les champs; et la fête de la récolte, à la fin de l'année, quand vous rassemblez vos travaux des champs.
17 “Ní ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ọkùnrin yín yóò máa wá fi ara hàn ní iwájú Olúwa Olódùmarè.
Trois fois par an, tous vos mâles se présenteront devant le Seigneur Yahvé.
18 “Ìwọ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ ẹ̀jẹ̀ sí mi ti òun ti àkàrà tó ní ìwúkàrà. “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rá ẹbọ àjọ mi ni kò gbọdọ̀ kù títí di òwúrọ̀.
« Tu n'offriras pas le sang de mon sacrifice avec du pain levé. La graisse de mon festin ne restera pas toute la nuit jusqu'au matin.
19 “Mú àkọ́ká èso ilẹ̀ rẹ tí ó dára jùlọ wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ. “Ìwọ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ewúrẹ́ nínú omi ọmú ìyá rẹ̀.
Tu apporteras les premiers fruits de ton sol dans la maison de l'Éternel, ton Dieu. « Tu ne feras pas bouillir un chevreau dans le lait de sa mère.
20 “Kíyèsi èmi rán angẹli kan lọ ní iwájú rẹ, láti ṣọ́ ọ ni ọ̀nà àti láti mú ọ dé ibi ti mo ti pèsè sílẹ̀ fún.
« Voici, j'envoie un ange devant toi, pour te garder en chemin et te faire entrer dans le lieu que j'ai préparé.
21 Fi ara balẹ̀, kí o sì fetísílẹ̀ sí i, kí o sì gba ohùn rẹ̀ gbọ́; má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí i, nítorí kò ní fi àìṣedéédéé yín jì yín, orúkọ mi wà lára rẹ̀.
Prends garde à lui, et écoute sa voix. Ne le provoque pas, car il ne pardonnera pas ta désobéissance, car mon nom est en lui.
22 Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohùn rẹ̀ tí ẹ sì ṣe ohun gbogbo ti mo ní kí ẹ ṣe, èmi yóò jẹ́ ọ̀tá àwọn ọ̀tá yín. Èmi yóò sì fóòro àwọn tí ń fóòro yín.
Mais si vous écoutez vraiment sa voix, et si vous faites tout ce que je dis, alors je serai l'ennemi de vos ennemis, et l'adversaire de vos adversaires.
23 Angẹli mi yóò lọ níwájú rẹ, yóò sì mú ọ dé ọ̀dọ̀ àwọn ará: Amori, Hiti, Peresi, Kenaani, Hifi àti Jebusi, èmi a sì gé wọn kúrò.
Car mon ange marchera devant toi, et te conduira vers l'Amoréen, le Héthien, le Phérézien, le Cananéen, le Hévien et le Jébusien, et je les exterminerai.
24 Ìwọ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún òrìṣà wọn, bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, tàbí kí ẹ tẹ̀lé ìṣe wọn. Kí ìwọ kí ó si wó wọn lulẹ̀, kí ìwọ kí ó sì fọ́ ère òkúta wọ́n túútúú.
Tu ne te prosterneras pas devant leurs dieux, tu ne les serviras pas et tu ne suivras pas leurs pratiques, mais tu les écraseras et tu détruiras leurs piliers.
25 Ẹ̀yin yóò sí máa sin Olúwa Ọlọ́run yin, òun yóò si bùsi oúnjẹ rẹ. Èmi yóò mú àìsàn kúrò láàrín rẹ.
Tu serviras Yahvé ton Dieu, il bénira ton pain et ton eau, et j'éloignerai la maladie du milieu de toi.
26 Oyún kò ní bàjẹ́ lára obìnrin kan, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan kì yóò yàgàn ni ilẹ̀ rẹ. Èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.
Personne ne fera de fausse couche ni ne sera stérile dans votre pays. J'accomplirai le nombre de vos jours.
27 “Èmi yóò rán ẹ̀rù mi lọ ṣáájú rẹ, ìdàrúdàpọ̀ yóò sì wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ bá da ojú kọ. Èmi yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ yí ẹ̀yìn padà sí ọ, kí wọn sì sá ní iwájú rẹ.
J'enverrai ma terreur devant toi, je confondrai tous les peuples que tu rencontreras, et je ferai en sorte que tous tes ennemis te tournent le dos.
28 Èmi yóò rán oyin ṣáájú rẹ láti lé àwọn ará: Hifi, Kenaani àti Hiti kúrò ni ọ̀nà rẹ.
J'enverrai devant toi le frelon qui chassera devant toi l'Hivvite, le Cananéen et le Héthien.
29 Ṣùgbọ́n, Èmi kò ni lé gbogbo wọn jáde ni ọdún kan ṣoṣo, ki ilẹ̀ náà má ba à di ahoro, àwọn ẹranko búburú yóò sì ti pọ̀jù fún ọ.
Je ne les chasserai pas devant toi en une seule année, de peur que le pays ne devienne désert et que les animaux des champs ne se multiplient contre toi.
30 Díẹ̀díẹ̀ ni èmi yóò máa lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ, títí ìwọ yóò fi pọ̀ tó láti gba gbogbo ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ìní.
Je les chasserai peu à peu de devant toi, jusqu'à ce que tu aies augmenté et que tu aies hérité du pays.
31 “Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun Pupa títí dé òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate, Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.
Je fixerai tes limites depuis la mer Rouge jusqu'à la mer des Philistins, et depuis le désert jusqu'au fleuve; car je livrerai entre tes mains les habitants du pays, et tu les chasseras devant toi.
32 Ìwọ kò gbọdọ̀ dá májẹ̀mú kankan pẹ̀lú wọn tàbí pẹ̀lú àwọn òrìṣà wọn.
Tu ne feras aucune alliance avec eux, ni avec leurs dieux.
33 Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn gbé ni ilẹ̀ rẹ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò mú ọ dẹ́ṣẹ̀ sí mi: nítorí bí ìwọ bá sin òrìṣà wọn, èyí yóò jẹ́ ìdẹ̀kùn fun ọ nítòótọ́.”
Ils n'habiteront pas dans ton pays, de peur qu'ils ne te fassent pécher contre moi, car si tu sers leurs dieux, ce sera un piège pour toi. »

< Exodus 23 >