< Exodus 15 >

1 Nígbà náà ni Mose àti àwọn ọmọ Israẹli kọ orin yìí sí Olúwa, Èmi yóò kọrin sí Olúwa, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún ni ó ti sọ sínú Òkun.
那时,摩西和以色列人向耶和华唱歌说: 我要向耶和华歌唱,因他大大战胜, 将马和骑马的投在海中。
2 Olúwa ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.
耶和华是我的力量,我的诗歌, 也成了我的拯救。 这是我的 神,我要赞美他, 是我父亲的 神,我要尊崇他。
3 Ológun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,
耶和华是战士; 他的名是耶和华。
4 kẹ̀kẹ́ ogun Farao àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú Òkun. Àwọn ọmọ-ogun Farao tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú Òkun Pupa.
法老的车辆、军兵,耶和华已抛在海中; 他特选的军长都沉于红海。
5 Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.
深水淹没他们; 他们如同石头坠到深处。
6 “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa, fọ́ àwọn ọ̀tá túútúú.
耶和华啊,你的右手施展能力,显出荣耀; 耶和华啊,你的右手摔碎仇敌。
7 “Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; tí ó run wọ́n bí àgémọ́lẹ̀ ìdí koríko.
你大发威严,推翻那些起来攻击你的; 你发出烈怒如火,烧灭他们像烧碎秸一样。
8 Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀. Ìṣàn omi dìde dúró bí odi; ibú omi sì dìpọ̀ láàrín Òkun.
你发鼻中的气,水便聚起成堆, 大水直立如垒, 海中的深水凝结。
9 Ọ̀tá ń gbéraga, ó ń wí pé, ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. èmi ó pín ìkógun; èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’
仇敌说:我要追赶,我要追上; 我要分掳物,我要在他们身上称我的心愿。 我要拔出刀来,亲手杀灭他们。
10 Ìwọ fẹ́ èémí rẹ, òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀. Wọ́n rì bí òjé ni àárín omi ńlá.
你叫风一吹,海就把他们淹没; 他们如铅沉在大水之中。
11 Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn, tí ń ṣe ohun ìyanu?
耶和华啊,众神之中,谁能像你? 谁能像你—至圣至荣, 可颂可畏,施行奇事?
12 “Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ, ilẹ̀ si gbé wọn mì.
你伸出右手, 地便吞灭他们。
13 Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í sákí Ìwọ ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn náà tí Ìwọ ti rà padà. Nínú agbára rẹ Ìwọ yóò tọ́ wọn, lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.
你凭慈爱领了你所赎的百姓; 你凭能力引他们到了你的圣所。
14 Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì. Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn Filistia.
外邦人听见就发颤; 疼痛抓住非利士的居民。
15 Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Edomu, àwọn olórí Moabu yóò wárìrì. Àwọn ènìyàn Kenaani yóò sì yọ́ dànù.
那时,以东的族长惊惶, 摩押的英雄被战兢抓住, 迦南的居民心都消化了。
16 Ìbẹ̀rù bojo yóò ṣubú lù wọ́n, nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ẹ́ láì mira bí i òkúta, títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi rékọjá, Olúwa, títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi rékọjá.
惊骇恐惧临到他们。 耶和华啊,因你膀臂的大能, 他们如石头寂然不动, 等候你的百姓过去, 等候你所赎的百姓过去。
17 Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni orí òkè ti ìwọ jogún, ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbé kalẹ̀, Olúwa.
你要将他们领进去,栽于你产业的山上— 耶和华啊,就是你为自己所造的住处; 主啊,就是你手所建立的圣所。
18 “Olúwa yóò jẹ ọba láé àti láéláé.”
耶和华必作王,直到永永远远!
19 Nígbà ti ẹṣin Farao, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ wọ inú Òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.
法老的马匹、车辆,和马兵下到海中,耶和华使海水回流,淹没他们;惟有以色列人在海中走干地。
20 Miriamu wòlíì obìnrin, arábìnrin Aaroni, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin sì jáde tẹ̀lé e pẹ̀lú ìlù òun ijó.
亚伦的姊姊,女先知米利暗,手里拿着鼓;众妇女也跟她出去拿鼓跳舞。
21 Miriamu kọrin sí wọn báyìí pé, “Ẹ kọrin sí Olúwa, nítorí òun ni ológo jùlọ. Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún, ni òun bi ṣubú sínú Òkun.”
米利暗应声说: 你们要歌颂耶和华,因他大大战胜, 将马和骑马的投在海中。
22 Nígbà náà ni Mose ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Israẹli jáde láti Òkun Pupa lọ sínú ijù Ṣuri. Wọ́n lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.
摩西领以色列人从红海往前行,到了书珥的旷野,在旷野走了三天,找不着水。
23 Nígbà tí wọ́n dé Mara, wọn kò lè mu omi Mara nítorí omi náà korò. (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Mara: ibi ìkorò.)
到了玛拉,不能喝那里的水;因为水苦,所以那地名叫玛拉。
24 Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mose wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”
百姓就向摩西发怨言,说:“我们喝什么呢?”
25 Mose sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni Olúwa ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
摩西呼求耶和华,耶和华指示他一棵树。他把树丢在水里,水就变甜了。 耶和华在那里为他们定了律例、典章,在那里试验他们;
26 Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin Olúwa Ọlọ́run, ti ìwọ sì ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn ààrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Ejibiti wá sí ara rẹ, nítorí Èmi ni Olúwa ti ó mú ọ láradá.”
又说:“你若留意听耶和华—你 神的话,又行我眼中看为正的事,留心听我的诫命,守我一切的律例,我就不将所加与埃及人的疾病加在你身上,因为我—耶和华是医治你的。”
27 Nígbà ti wọ́n dé Elimu, níbi ti kànga omi méjìlá àti àádọ́rin ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ni etí omi.
他们到了以琳,在那里有十二股水泉,七十棵棕树;他们就在那里的水边安营。

< Exodus 15 >