< Exodus 11 >

1 Nísinsin yìí, Olúwa sọ fún Mose pé èmi yóò mú ààrùn kan sí i wá sí orí Farao àti ilẹ̀ Ejibiti. Lẹ́yìn náà yóò jẹ́ kí ẹ̀yin kí ó lọ kúrò níhìn-ín yìí, nígbà tí ó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ yóò lé yín jáde pátápátá.
ויאמר יהוה אל משה עוד נגע אחד אביא על פרעה ועל מצרים אחרי כן ישלח אתכם מזה כשלחו כלה גרש יגרש אתכם מזה׃
2 Sọ fún àwọn ènìyàn náà pé kí tọkùnrin tobìnrin wọn béèrè fún ohun èlò fàdákà àti wúrà lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀.
דבר נא באזני העם וישאלו איש מאת רעהו ואשה מאת רעותה כלי כסף וכלי זהב׃
3 (Olúwa jẹ́ kí wọn rí ojúrere àwọn ará Ejibiti, pàápàá, Mose fúnra rẹ̀ di ènìyàn pàtàkì ní ilẹ̀ Ejibiti ní iwájú àwọn ìjòyè Farao àti ní iwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú).
ויתן יהוה את חן העם בעיני מצרים גם האיש משה גדול מאד בארץ מצרים בעיני עבדי פרעה ובעיני העם׃
4 Nígbà náà ni Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Ní ọ̀gànjọ́ òru èmi yóò la ilẹ̀ Ejibiti kọjá.
ויאמר משה כה אמר יהוה כחצת הלילה אני יוצא בתוך מצרים׃
5 Gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni yóò kùú, bẹ̀rẹ̀ lórí àkọ́bí ọkùnrin Farao tí ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀, tí ó fi dé orí àkọ́bí ọmọkùnrin ti ẹrúbìnrin tí ń lọ ọlọ àti gbogbo àkọ́bí ẹran ọ̀sìn pẹ̀lú.
ומת כל בכור בארץ מצרים מבכור פרעה הישב על כסאו עד בכור השפחה אשר אחר הרחים וכל בכור בהמה׃
6 Igbe ẹkún ńlá yóò sọ jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Irú ohun búburú tí kò ṣẹlẹ̀ rí tí kò sí tún ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
והיתה צעקה גדלה בכל ארץ מצרים אשר כמהו לא נהיתה וכמהו לא תסף׃
7 Ṣùgbọ́n láàrín àwọn ará Israẹli ajá lásán kò ní gbó àwọn ènìyàn tàbí àwọn ẹran wọn.’ Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ti fi ìyàtọ̀ sáàrín àwọn ará Ejibiti àti Israẹli.
ולכל בני ישראל לא יחרץ כלב לשנו למאיש ועד בהמה למען תדעון אשר יפלה יהוה בין מצרים ובין ישראל׃
8 Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ wọ̀nyí yóò tọ̀ mí wá, wọn yóò wólẹ̀ ni iwájú, mi wọn yóò sì máa wí pé, ‘Lọ àti àwọn ènìyàn tí ó tẹ̀lé ọ!’ Lẹ́yìn náà èmi yóò jáde.” Nígbà náà ni Mose fi ìbínú jáde kúrò ní iwájú Farao.
וירדו כל עבדיך אלה אלי והשתחוו לי לאמר צא אתה וכל העם אשר ברגליך ואחרי כן אצא ויצא מעם פרעה בחרי אף׃
9 Olúwa ti sọ fún Mose pé, “Farao yóò kọ̀ láti fetísílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Ejibiti.”
ויאמר יהוה אל משה לא ישמע אליכם פרעה למען רבות מופתי בארץ מצרים׃
10 Mose àti Aaroni ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Farao, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Farao le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Israẹli jáde kúrò ni orílẹ̀-èdè rẹ̀.
ומשה ואהרן עשו את כל המפתים האלה לפני פרעה ויחזק יהוה את לב פרעה ולא שלח את בני ישראל מארצו׃

< Exodus 11 >