< Esther 1 >
1 Èyí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà Ahaswerusi, tí ó jẹ ọba lórí ẹ̀tàdínláàdóje ìletò bẹ̀rẹ̀ láti India títí ó fi dé Etiopia.
亚哈随鲁作王,从印度直到古实,统管一百二十七省。
2 Ní àkókò ìgbà náà ọba Ahaswerusi ń ṣe ìjọba ní orí ìtẹ́ ẹ rẹ̀ ní ilé ìṣọ́ ti Susa,
亚哈随鲁王在书珊城的宫登基;
3 ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti ìjòyè. Àwọn olórí ológun láti Persia àti Media, àwọn ọmọ-aládé, àti àwọn ọlọ́lá ìletò wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
在位第三年,为他一切首领臣仆设摆筵席,有波斯和米底亚的权贵,就是各省的贵胄与首领,在他面前。
4 Ó ṣe àfihàn púpọ̀ ọrọ̀ ìjọba rẹ̀ àti dídán àti ògo ọláńlá rẹ̀ fún ọgọ́sàn-án ọjọ́ gbáko.
他把他荣耀之国的丰富和他美好威严的尊贵给他们看了许多日,就是一百八十日。
5 Nígbà tí ọjọ́ wọ̀nyí kọjá, ọba ṣe àsè fún ọjọ́ méje, nínú ọgbà tí ó wà nínú àgbàlá ààfin ọba, gbogbo ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni tí ó lọ́lá jùlọ, tí wọ́n wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa.
这日子满了,又为所有住书珊城的大小人民在御园的院子里设摆筵席七日。
6 Ọgbà náà ní aṣọ fèrèsé funfun àti aláwọ̀ òféfèé. Àwọn okùn tí a fi aṣọ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ elése àlùkò rán ni a fi ta á mọ́ òrùka fàdákà lára àwọn òpó mabu. Àwọn ibùsùn tí a fi wúrà àti fàdákà ṣe wà níbi pèpéle òkúta tí a fi ń tẹ́lẹ̀ ilé tí ó jẹ́ mabu, píálì àti òkúta olówó iyebíye mìíràn.
有白色、绿色、蓝色的帐子,用细麻绳、紫色绳从银环内系在白玉石柱上;有金银的床榻摆在红、白、黄、黑玉石的铺石地上。
7 Kọ́ọ̀bù wúrà onídìí-odó ni a fi ń bu wáìnì fún wọn mu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì yàtọ̀ sí èkejì, wáìnì ọba pọ̀ púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba ṣe lawọ́ sí.
用金器皿赐酒,器皿各有不同。御酒甚多,足显王的厚意。
8 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba a fi ààyè gba àlejò kọ̀ọ̀kan láti mu tó bí ó bá ti fẹ́, nítorí ọba ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn ti ń bu wáìnì láti bù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan bí wọ́n bá ṣe béèrè fún mọ.
喝酒有例,不准勉强人,因王吩咐宫里的一切臣宰,让人各随己意。
9 Ayaba Faṣti náà ṣe àsè fún àwọn obìnrin ní ààfin ọba Ahaswerusi.
王后瓦实提在亚哈随鲁王的宫内也为妇女设摆筵席。
10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bista, Harbona, Bigta àti Abagta, Setari àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń jíṣẹ́ fún Ahaswerusi.
第七日,亚哈随鲁王饮酒,心中快乐,就吩咐在他面前侍立的七个太监米户幔、比斯他、哈波拿、比革他、亚拔他、西达、甲迦,
11 Kí wọn mú ayaba Faṣti wá síwájú rẹ̀, ti òun ti adé ọba rẹ̀, kí ó lè wá fi ẹwà rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn àti àwọn ọlọ́lá, nítorí tí ó rẹwà.
请王后瓦实提头戴王后的冠冕到王面前,使各等臣民看她的美貌,因为她容貌甚美。
12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ jẹ́ iṣẹ́ ọba, ayaba Faṣti kọ̀ láti wá. Nígbà náà ni ọba bínú gidigidi, ìbínú náà sì pọ̀ jọjọ.
王后瓦实提却不肯遵太监所传的王命而来,所以王甚发怒,心如火烧。
13 Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ní ìgbà gbogbo, ọba máa ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ìmọ̀ òfin àti ìdájọ́, ó sọ ọ́ fún àwọn amòye tí wọ́n mòye àkókò,
那时,在王左右常见王面、国中坐高位的,有波斯和米底亚的七个大臣,就是甲示拿、示达、押玛他、他施斯、米力、玛西拿、米母干,都是达时务的明哲人。按王的常规,办事必先询问知例明法的人。王问他们说:
14 àwọn tí wọ́n súnmọ́ ọba àwọn wọ̀nyí ni Karṣina, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena àti Memukani, àwọn ọlọ́lá méje ti Persia àti Media tí wọ́n ṣe pàtàkì sí ọba, wọ́n sì tún wà ní ibi gíga ní ìjọba.
15 Ó béèrè pé, “Kí ni a lè ṣe sí ayaba Faṣti gẹ́gẹ́ bí òfin? Nítorí kò tẹríba fún àṣẹ ọba Ahaswerusi tí àwọn ìwẹ̀fà ọba sọ fún un.”
“王后瓦实提不遵太监所传的王命,照例应当怎样办理呢?”
16 Memukani sì dáhùn níwájú ọba àti àwọn ọlọ́lá pé, “Ayaba Faṣti ti ṣe búburú, kì í ṣe sí ọba nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba Ahaswerusi.
米母干在王和众首领面前回答说:“王后瓦实提这事,不但得罪王,并且有害于王各省的臣民;
17 Nítorí ìwà ayaba yìí yóò tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn obìnrin, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ wọn yóò di gígàn lójú u wọn, wọn yóò sì sọ pé, ọba Ahaswerusi pàṣẹ pé kí á mú ayaba Faṣti wá síwájú òun, ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti wá.
因为王后这事必传到众妇人的耳中,说:‘亚哈随鲁王吩咐王后瓦实提到王面前,她却不来’,她们就藐视自己的丈夫。
18 Ní ọjọ́ yìí gan an ni àwọn ọlọ́lá obìnrin Persia àti ti Media tí wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ayaba wọn yóò ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ìjòyè ọba bákan náà. Àfojúdi àti àìnírẹ́pọ̀ tí kò lópin yóò wà.
今日波斯和米底亚的众夫人听见王后这事,必向王的大臣照样行;从此必大开藐视和忿怒之端。
19 “Nítorí náà, bí ó bá tọ́ lójú ọba, jẹ́ kí ó gbé àṣẹ ọba jáde, kí ó sì jẹ́ kí ó wà ní àkọsílẹ̀ pẹ̀lú òfin Persia àti Media, èyí tí kò le é parẹ́, pé kí Faṣti kí ó má ṣe wá síwájú ọba Ahaswerusi. Kí ọba sì fi oyè ayaba rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ.
王若以为美,就降旨写在波斯和米底亚人的例中,永不更改,不准瓦实提再到王面前,将她王后的位分赐给比她还好的人。
20 Nígbà náà tí a bá kéde òfin tí ọba ṣe ká gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀, gbogbo àwọn obìnrin ni yóò bọ̀wọ̀ fún ọkọ wọn, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré títí dé ọ̀dọ̀ ẹni ńlá.”
所降的旨意传遍通国(国度本来广大),所有的妇人,无论丈夫贵贱都必尊敬他。”
21 Ìmọ̀ràn yìí sì tẹ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ́rùn, nítorí náà ọba ṣe gẹ́gẹ́ bí Memukani ṣé sọ.
王和众首领都以米母干的话为美,王就照这话去行,
22 Ó kọ̀wé ránṣẹ́ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ọba rẹ̀, ó kọ̀wé sí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé, ó kọ̀wé sí àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, Ó tẹnumọ́ ní èdè oníkálùkù pé kí olúkúlùkù ọkùnrin máa ṣàkóso ilé rẹ̀.
发诏书,用各省的文字、各族的方言通知各省,使为丈夫的在家中作主,各说本地的方言。