< Esther 8 >
1 Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba.
Die illo dedit rex Assuerus Esther reginae domum Aman adversarii Iudaeorum, et Mardochaeus ingressus est ante faciem regis. Confessa est enim ei Esther quod esset patruus suus.
2 Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani.
Tulitque rex annulum, quem ab Aman recipi iusserat, et tradidit Mardochaeo. Esther autem constituit Mardochaeum super domum suam.
3 Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù.
Nec his contenta, procidit ad pedes regis, flevitque et locuta ad eum oravit ut malitiam Aman Agagitae, et machinationes eius pessimas, quas excogitaverat contra Iudaeos, iuberet irritas fieri.
4 Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀.
At ille ex more sceptrum aureum protendit manu, quo signum clementiae monstrabatur: illaque consurgens stetit ante eum,
5 Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run.
et ait: Si placet regi, et si inveni gratiam in oculis eius, et deprecatio mea non ei videtur esse contraria, obsecro, ut novis epistolis, veteres Aman litterae, insidiatoris et hostis Iudaeorum, quibus eos in cunctis regis provinciis perire praeceperat, corrigantur.
6 Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?”
Quo modo enim potero sustinere necem et interfectionem populi mei?
7 Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi.
Responditque rex Assuerus Esther reginae, et Mardochaeo Iudaeo: Domum Aman concessi Esther, et ipsum iussi affigi cruci, quia ausus est manum mittere in Iudaeos.
8 Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.”
Scribite ergo Iudaeis, sicut vobis placet, regis nomine, signantes litteras annulo meo. Haec enim consuetudo erat, ut epistolis, quae ex regis nomine mittebantur, et illius annulo signatae erant, nemo auderet contradicere.
9 Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tàdínláàádóje tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn.
Accitisque scribis et librariis regis (erat autem tempus tertii mensis, qui appellatur Siban) vigesima et tertia die illius scriptae sunt epistolae, ut Mardochaeus voluerat, ad Iudaeos, et ad principes, procuratoresque et iudices, qui centum vigintiseptem provinciis ab India usque ad Aethiopiam praesidebant: provinciae atque provinciae, populo et populo iuxta linguas et litteras suas, et Iudaeis, prout legere poterant, et audire.
10 Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.
Ipsaeque epistolae, quae regis nomine mittebantur, annulo ipsius obsignatae sunt, et missae per veredarios: qui per omnes provincias discurrentes, veteres litteras novis nunciis praevenirent.
11 Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀-èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbèríko tí ó bá fẹ́ kọlù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá wọn.
Quibus imperavit rex, ut convenirent Iudaeos per singulas civitates, et in unum praeciperent congregari ut starent pro animabus suis, et omnes inimicos suos cum coniugibus ac liberis et universis domibus, interficerent atque delerent.
12 Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣù kejìlá, oṣù Addari.
Et constituta est per omnes provincias una ultionis dies, id est tertiadecima mensis duodecimi Adar.
13 Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò le è múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn.
Summaque epistolae haec fuit, ut in omnibus terris ac populis, qui regis Assueri subiacebant imperio, notum fieret, paratos esse Iudaeos ad capiendam vindictam de hostibus suis.
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba tiwọn yára bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa.
Egressique sunt veredarii celeres nuncia perferentes, et edictum regis pependit in Susan.
15 Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá.
Mardochaeus autem de palatio, et de conspectu regis egrediens, fulgebat vestibus regiis, hyacinthinis videlicet et aeriis, coronam auream portans in capite, et amictus serico pallio atque purpureo. Omnisque civitas exultavit, atque laetata est.
16 Àsìkò ìdùnnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù.
Iudaeis autem nova lux oriri visa est, gaudium, honor, et tripudium.
17 Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrín àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tókù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.
Apud omnes populos, urbes, atque provincias, quocumque regis iussa veniebant, mira exultatio, epulae atque convivia, et festus dies: in tantum ut plures alterius gentis et sectae eorum religioni et ceremoniis iungerentur. Grandis enim cunctos Iudaici nominis terror invaserat.