< Ephesians 3 >
1 Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.
For this reason, I, Paul, the prisoner of Jesus Christ for you Gentiles,
2 Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín;
if, indeed, you have heard of the administration of the favor of God, which was given me for you,
3 bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí.
that by revelation the secret was made known to me, (as I wrote before in a few words;
4 Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi.
by which, when you read, you may perceive my knowledge of the secret of Christ, )
5 Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;
which in former ages was not made known to the sons of men, as it is now revealed to his holy Apostles and prophets by the Spirit;
6 pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìyìnrere.
that the Gentiles should be fellow-heirs, and of the same body, and joint partakers of his promise in Christ by the gospel;
7 Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.
of which I was made a minister, according to the gift of the favor of God which was given to me, according to the energy of his power; --
8 Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà;
to me, the least of saints, was this favor given, to publish among the Gentiles, the unsearchable riches of Christ;
9 àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi. (aiōn )
and to make all see what is the administration of the secret, which has been hid from the ages by God, who created all things. (aiōn )
10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,
That now, to the government and powers in the heavenly regions, might be made known by the congregation the manifold wisdom of God;
11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa. (aiōn )
according to the predisposition of the ages, which he made in Christ Jesus our Lord: (aiōn )
12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.
in whom we have liberty of speech, and introduction with confidence, through the faith of him.
13 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.
Wherefore, I request that you faint not at my afflictions for you, which is your glory.
14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi.
On this account, I bow my knees to the Father of our Lord Jesus Christ;
15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.
from whom the whole family in heaven and upon earth is named;
16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
praying that, according to the riches of his glory, he would grant you to be mightily strengthened by his Spirit in the inward man:
17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;
that Christ may dwell in your hearts through faith; that, being rooted and founded in love, you
18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́.
may be completely able to apprehend, with all the saints, what is the breadth, and length, and depth, and hight, --
19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.
even to know the love of Christ; which surpasses knowledge; that you might be filled with all the fullness of God.
20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.
Now, to him who is able to do exceeding abundantly beyond all that we ask or think, according to the power which works effectually in us, --
21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín. (aiōn )
to him be glory in the congregation by Christ Jesus, during all the endless successions of ages. Amen. (aiōn )