< Ecclesiastes 7 >

1 Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ, ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ.
טוב שם משמן טוב ויום המות מיום הולדו
2 Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju ibi àsè, nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn; kí alààyè ní èyí ní ọkàn.
טוב ללכת אל בית אבל מלכת אל בית משתה--באשר הוא סוף כל האדם והחי יתן אל לבו
3 Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ, ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú, ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
טוב כעס משחוק כי ברע פנים ייטב לב
4 Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
לב חכמים בבית אבל ולב כסילים בבית שמחה
5 Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
טוב לשמע גערת חכם--מאיש שמע שיר כסילים
6 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò ni ẹ̀rín òmùgọ̀. Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
כי כקול הסירים תחת הסיר כן שחק הכסיל וגם זה הבל
7 Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.
כי העשק יהולל חכם ויאבד את לב מתנה
8 Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
טוב אחרית דבר מראשיתו טוב ארך רוח מגבה רוח
9 Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.
אל תבהל ברוחך לכעוס כי כעס בחיק כסילים ינוח
10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?” Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.
אל תאמר מה היה--שהימים הראשנים היו טובים מאלה כי לא מחכמה שאלת על זה
11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
טובה חכמה עם נחלה ויתר לראי השמש
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.
כי בצל החכמה בצל הכסף ויתרון דעת החכמה תחיה בעליה
13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe: “Ta ni ó le è to ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
ראה את מעשה האלהים כי מי יוכל לתקן את אשר עותו
14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn, ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó: Ọlọ́run tí ó dá èkínní náà ni ó dá èkejì. Nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.
ביום טובה היה בטוב וביום רעה ראה גם את זה לעמת זה עשה האלהים על דברת שלא ימצא האדם אחריו מאומה
15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀ ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
את הכל ראיתי בימי הבלי יש צדיק אבד בצדקו ויש רשע מאריך ברעתו
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
אל תהי צדיק הרבה ואל תתחכם יותר למה תשומם
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè, èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
אל תרשע הרבה ואל תהי סכל למה תמות בלא עתך
18 Ó dára láti mú ọ̀kan kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀. Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.
טוב אשר תאחז בזה וגם מזה אל תנח את ידך כי ירא אלהים יצא את כלם
19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.
החכמה תעז לחכם--מעשרה שליטים אשר היו בעיר
20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.
כי אדם אין צדיק בארץ--אשר יעשה טוב ולא יחטא
21 Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
גם לכל הדברים אשר ידברו אל תתן לבך אשר לא תשמע את עבדך מקללך
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.
כי גם פעמים רבות ידע לבך אשר גם את (אתה) קללת אחרים
23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé, “Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”; ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
כל זה נסיתי בחכמה אמרתי אחכמה והיא רחוקה ממני
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́, ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
רחוק מה שהיה ועמק עמק מי ימצאנו
25 Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀, láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́ búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.
סבותי אני ולבי לדעת ולתור ובקש חכמה וחשבון ולדעת רשע כסל והסכלות הוללות
26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì, tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n, ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.
ומוצא אני מר ממות את האשה אשר היא מצודים וחרמים לבה--אסורים ידיה טוב לפני האלהים ימלט ממנה וחוטא ילכד בה
27 Oniwaasu wí pé, “Wò ó, eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí: “Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
ראה זה מצאתי אמרה קהלת אחת לאחת למצא חשבון
28 Nígbà tí mo sì ń wá a kiri ṣùgbọ́n tí n kò rí i mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún, ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin, kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.
אשר עוד בקשה נפשי ולא מצאתי אדם אחד מאלף מצאתי--ואשה בכל אלה לא מצאתי
29 Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí: Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára, ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”
לבד ראה זה מצאתי אשר עשה האלהים את האדם ישר והמה בקשו חשבנות רבים

< Ecclesiastes 7 >