< Ecclesiastes 4 >
1 Mo sì tún wò ó, mo sì rí gbogbo ìnilára tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, mo rí ẹkún àwọn tí ara ń ni, wọn kò sì ní olùtùnú kankan, agbára wà ní ìkápá àwọn tí ó ń ni wọ́n lára, wọn kò sì ní olùtùnú kankan.
我又轉目注視在太陽下所行的一切暴行:看,受壓迫者眼淚汪流,卻無人安慰;壓迫人者手中只有權勢,卻無人加以援助。
2 Mo jowú àwọn tí wọ́n ti kú tí wọ́n sì ti lọ, ó sàn fún wọn ju àwọn tí wọ́n sì wà láààyè lọ.
於是我聲稱那已死去的人,比現今還活著的人更為有福。
3 Nítòótọ́, ẹni tí kò tí ì sí sàn ju àwọn méjèèjì lọ: ẹni tí kò tí ì rí iṣẹ́ búburú tí ó ń lọ ní abẹ́ oòrùn.
那還沒有出世的人,比這兩等人更為有福,因為他還沒有見到太陽下所行的惡事。
4 Mo sì tún mọ̀ pẹ̀lú, ìdí tí ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ tagbára tagbára láti ṣe àṣeyọrí, nítorí pé wọn ń jowú àwọn aládùúgbò wọn ni. Ṣùgbọ́n, asán ni, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́.
我也看出各種勞苦和一切工作的技巧,都是出於人彼此間的競爭:這也是空虛,也是追風。
5 Aṣiwèrè ká ọwọ́ rẹ̀ kò ó sì ba tara rẹ̀ jẹ́.
愚人交臂叉手,是自食己肉。
6 Oúnjẹ ẹ̀kúnwọ́ kan pẹ̀lú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì pẹ̀lú wàhálà, àti gbígba ìyànjú àti lé afẹ́fẹ́ lọ.
捧一把安逸,勝過兩把勞苦和追風。
7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo tún rí ohun asán kan lábẹ́ oòrùn.
我又轉睛,看見在太陽下有件空虛的事:
8 Ọkùnrin kan ṣoṣo dá wà; kò ní ọmọkùnrin kankan tàbí ẹbí. Kò sí òpin nínú làálàá rẹ̀ gbogbo, síbẹ̀, ọrọ̀ kò tẹ́ ojú rẹ̀ lọ́rùn. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì wí pé, “Nítorí ta ni èmí ṣe ń ṣe làálàá, àti wí pé, èétiṣe tí mo fi ń fi ìgbádùn du ara mi?” Eléyìí náà asán ni, iṣẹ́ òsì!
有個孤獨無伴的人,既沒有兒子,又沒有兄弟,卻時常勞苦不息,他的眼總是貪得無厭,從來不問:「我辛辛苦苦,節制享樂,究竟是為誰﹖」這也是空虛和大不幸。
9 Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn.
兩人勝過一人,因為兩人工作,酬報優厚:
10 Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́!
若一個跌倒了,另一個可扶起自己的同伴。哀哉孤獨者! 他若跌倒了,沒有另一人扶起他來。
11 Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru?
又如兩人同眠,都感溫暖;若孤獨一人,怎能暖和﹖
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.
若一人抵不住一人,兩人就能抵住。--三股繩,不易斷。
13 Òtòṣì ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ tí ó ṣe ọlọ́gbọ́n, ó sàn ju arúgbó àti aṣiwèrè ọba lọ tí kò mọ bí yóò ti ṣe gba ìmọ̀ràn.
一個貧寒而明智的青年,勝過一個年老昏愚,而總不採納忠言的君王。
14 Nítorí pé láti inú túbú ni ó ti jáde láti jẹ ọba, bí a tilẹ̀ bí i ní tálákà ní ìjọba rẹ̀.
這青年雖在國中出身貧寒,但由獄中出來,執政為王;
15 Mo rí gbogbo alààyè tí ń rìn lábẹ́ oòrùn, pẹ̀lú ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ kejì tí yóò gba ipò ọba yìí.
我看見一切在太陽下行走的活人,都擁護青年人,新繼位者,來代替老王。
16 Gbogbo àwọn tí ó wà níwájú wọn kò sì lópin, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ní ó jẹ ọba lé lórí, ẹni tí ó wà ní ipò yìí kò dùn mọ́ àwọn tí ó tẹ̀lé wọn nínú. Asán ni eléyìí pẹ̀lú jẹ́, ó dàbí ẹni ń gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
擁護他為領袖的人民,多得無數;但日後,那些後來的人卻不喜歡他:這也是空虛,也是追風。