< Deuteronomy 20 >
1 Nígbà tí o bá lọ sí ogun pẹ̀lú ọ̀tá rẹ, tí o sì rí ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ológun tí ó jù ọ́ lọ, má ṣe bẹ̀rù u wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ń mú ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, yóò wà pẹ̀lú rẹ.
When you go forth to battle against your enemies, and see horses, chariots, and a people more than you, you shall not be afraid of them; for YHWH your God is with you, who brought you up out of the land of Egypt.
2 Nígbà tí o bá fẹ́ lọ jagun, àlùfáà yóò wá síwájú, yóò sì bá ọmọ-ogun sọ̀rọ̀,
It shall be, when you draw near to the battle, that the priest shall approach and speak to the people,
3 yóò sì wí pé, “Gbọ́, ìwọ Israẹli, lónìí ò ń jáde lọ sójú ogun sí ọ̀tá rẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín ṣojo tàbí bẹ̀rù; ẹ má ṣe jáyà tàbí kí ẹ fi ààyè fún ìjayà níwájú u wọn.
and shall tell them, "Hear, Israel, you draw near this day to battle against your enemies: do not let your heart faint; do not be afraid, nor tremble, neither be scared of them;
4 Nítorí Olúwa Ọlọ́run yín ní bá yín lọ, láti bá àwọn ọ̀tá yín jà fún yín, láti gbà yín là.”
for YHWH your God is he who goes with you, to fight for you against your enemies, to save you."
5 Àwọn olórí ogun yóò sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó kọ́ ilé tuntun tí kò sì tì ì yà á sọ́tọ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí ó lè kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbà á.
The officers shall speak to the people, saying, "What man is there who has built a new house, and has not dedicated it? Let him go and return to his house, lest he die in the battle, and another man dedicate it.
6 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó gbin ọgbà àjàrà kan tí kò sì tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ń gbádùn rẹ̀? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì gbádùn rẹ̀.
What man is there who has planted a vineyard, and has not used its fruit? Let him go and return to his house, lest he die in the battle, and another man use its fruit.
7 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tí ó wá ògo obìnrin kan tí kò ì tí ì fẹ́ ẹ? Jẹ́ kí ó lọ ilé, tàbí kí ó kú sójú ogun kí ẹlòmíràn sì fẹ́ ẹ.”
What man is there who has pledged to be married a wife, and has not taken her? Let him go and return to his house, lest he die in the battle, and another man take her."
8 Nígbà náà ni olórí yóò tún fi kún un pé, “Ǹjẹ́ ọkùnrin kankan ń bẹ̀rù tàbí páyà? Jẹ́ kí ó lọ ilé nítorí kí arákùnrin rẹ̀ má ba à wá tún dáyà fò ó.”
The officers shall speak further to the people, and they shall say, "What man is there who is fearful and fainthearted? Let him go and return to his house, lest his brother's heart melt as his heart."
9 Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.
It shall be, when the officers have made an end of speaking to the people, that they shall appoint captains of armies at the head of the people.
10 Nígbà tí ó bá súnmọ́ iwájú láti dojúkọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.
When you draw near to a city to fight against it, then proclaim peace to it.
11 Tí wọ́n bá dá ọ lóhùn àlàáfíà, tí wọ́n sì ṣí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.
It shall be, if it makes you answer of peace, and opens to you, then it shall be, that all the people who are found in it shall become tributary to you, and shall serve you.
12 Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbóguntì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.
If it will make no peace with you, but will make war against you, then you shall besiege it:
13 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, kí ẹ̀yin kí ó fi ojú idà pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.
and when YHWH your God delivers it into your hand, you shall strike every male of it with the edge of the sword:
14 Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógun fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá rẹ.
but the women, and the little ones, and the livestock, and all that is in the city, even all its spoil, you shall take for a prey to yourself; and you shall eat the spoil of your enemies, which YHWH your God has given you.
15 Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.
Thus you shall do to all the cities which are very far off from you, which are not of the cities of these nations.
16 Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.
But of the cities of these peoples, that YHWH your God gives you for an inheritance, you shall save alive nothing that breathes;
17 Pa wọ́n run pátápátá, àwọn ọmọ Hiti, ọmọ Amori, ọmọ Kenaani, ọmọ Peresi, ọmọ Hifi, ọmọ Jebusi gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.
but you shall utterly destroy them: the Hethite, and the Amorite, and the Canaanite, and the Girgashite, and the Perizzite, and the Hivite, and the Jebusite; as YHWH your God has commanded you;
18 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sí sin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
that they not teach you to do after all their abominations, which they have done to their gods; so would you sin against YHWH your God.
19 Nígbà tí o bá dó ti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má ṣe gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi igbó ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dó tì rẹ̀.
When you shall besiege a city a long time, in making war against it to take it, you shall not destroy its trees by wielding an axe against them; for you may eat of them, and you shall not cut them down; for is the tree of the field man, that it should be besieged of you?
20 Ṣùgbọ́n ìwọ lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléso lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.
Only the trees of which you know that they are not trees for food, you shall destroy and cut them down; and you shall build siege works against the city that makes war with you, until it fall.