< Deuteronomy 19 >
1 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo.
When the LORD your God has cut off the nations whose land He is giving you, and when you have driven them out and settled in their cities and houses,
2 Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrín ilẹ̀ rẹ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ láti ni.
then you are to set apart for yourselves three cities within the land that the LORD your God is giving you to possess.
3 Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.
You are to build roads for yourselves and divide into three regions the land that the LORD your God is giving you as an inheritance, so that any manslayer can flee to these cities.
4 Èyí ni òfin nípa apànìyàn, tí ó sì sá síbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
Now this is the situation regarding the manslayer who flees to one of these cities to save his life, having killed his neighbor accidentally, without intending to harm him:
5 Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
If he goes into the forest with his neighbor to cut timber and swings his axe to chop down a tree, but the blade flies off the handle and strikes and kills his neighbor, he may flee to one of these cities to save his life.
6 Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lé e bá nítorí pé ọ̀nà jì, kí ó sì pa á bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣe é sí aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́.
Otherwise, the avenger of blood might pursue the manslayer in a rage, overtake him if the distance is great, and strike him dead though he did not deserve to die, since he did not intend any harm.
7 Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.
This is why I am commanding you to set apart for yourselves three cities.
8 Tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn,
And if the LORD your God enlarges your territory, as He swore to your fathers, and gives you all the land He promised them,
9 nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀.
and if you carefully keep all these commandments I am giving you today, loving the LORD your God and walking in His ways at all times, then you are to add three more cities to these three.
10 Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.
Thus innocent blood will not be shed in the land that the LORD your God is giving you as an inheritance, so that you will not be guilty of bloodshed.
11 Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí,
If, however, a man hates his neighbor and lies in wait, attacks him and kills him, and then flees to one of these cities,
12 àwọn àgbàgbà ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú.
the elders of his city must send for him, bring him back, and hand him over to the avenger of blood to die.
13 Má ṣe ṣàánú fún un. O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Israẹli, kí ó bá à lè dára fún ọ.
You must show him no pity. You are to purge from Israel the guilt of shedding innocent blood, that it may go well with you.
14 Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.
You must not move your neighbor’s boundary marker, which was set up by your ancestors to mark the inheritance you shall receive in the land that the LORD your God is giving you to possess.
15 Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.
A lone witness is not sufficient to establish any wrongdoing or sin against a man, regardless of what offense he may have committed. A matter must be established by the testimony of two or three witnesses.
16 Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan,
If a false witness testifies against someone, accusing him of a crime,
17 àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà.
both parties to the dispute must stand in the presence of the LORD, before the priests and judges who are in office at that time.
18 Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀,
The judges shall investigate thoroughly, and if the witness is proven to be a liar who has falsely accused his brother,
19 nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.
you must do to him as he intended to do to his brother. So you must purge the evil from among you.
20 Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrín yín.
Then the rest of the people will hear and be afraid, and they will never again do anything so evil among you.
21 Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.
You must show no pity: life for life, eye for eye, tooth for tooth, hand for hand, and foot for foot.