< Amos 7 >

1 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀.
Thus hath the Lord Yhwh shewed unto me; and, behold, he formed grasshoppers in the beginning of the shooting up of the latter growth; and, lo, it was the latter growth after the king’s mowings.
2 Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
And it came to pass, that when they had made an end of eating the grass of the land, then I said, O Lord Yhwh, forgive, I beseech thee: by whom shall Jacob arise? for he is small.
3 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.
Yhwh repented for this: It shall not be, saith Yhwh.
4 Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run.
Thus hath the Lord Yhwh shewed unto me: and, behold, the Lord Yhwh called to contend by fire, and it devoured the great deep, and did eat up a part.
5 Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”
Then said I, O Lord Yhwh, cease, I beseech thee: by whom shall Jacob arise? for he is small.
6 Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí. “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.
Yhwh repented for this: This also shall not be, saith the Lord Yhwh.
7 Èyí ni ohun tí ó fihàn mí: Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ odi ti a fi okùn ìwọ̀n mọ́, ti òun ti okùn ìwọ̀n tí ó rún ni ọwọ́ rẹ̀.
Thus he shewed me: and, behold, the Lord stood upon a wall made by a plumbline, with a plumbline in his hand.
8 Olúwa sì bi mi pé, “Amosi, kí ni ìwọ rí?” Mo dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n.” Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wò ó, Èmí ń gbé okùn ìwọ̀n kalẹ̀ láàrín àwọn Israẹli ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́.
And Yhwh said unto me, Amos, what seest thou? And I said, A plumbline. Then said the Lord, Behold, I will set a plumbline in the midst of my people Israel: I will not again pass by them any more:
9 “Ibi gíga Isaaki wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoro àti ibi mímọ Israẹli wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro. Èmi yóò sì fi idà dìde sí ilé Jeroboamu.”
And the high places of Isaac shall be desolate, and the sanctuaries of Israel shall be laid waste; and I will rise against the house of Jeroboam with the sword.
10 Nígbà náà Amasiah àlùfáà Beteli ránṣẹ́ sí Jeroboamu ọba Israẹli, wí pé: “Amosi ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárín gbùngbùn Israẹli. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Then Amaziah the priest of Beth–el sent to Jeroboam king of Israel, saying, Amos hath conspired against thee in the midst of the house of Israel: the land is not able to bear all his words.
11 Nítorí èyí ni ohun ti Amosi ń sọ: “‘Jeroboamu yóò ti ipa idà kú, lóòtítọ́ Israẹli yóò lọ sí ìgbèkùn, jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’”
For thus Amos saith, Jeroboam shall die by the sword, and Israel shall surely be led away captive out of their own land.
12 Nígbà náà ni Amasiah sọ fún Amosi pé, “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Juda. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀, kí o sì máa sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.
Also Amaziah said unto Amos, O thou seer, go, flee thee away into the land of Judah, and there eat bread, and prophesy there:
13 Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Beteli nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹmpili ìjọba rẹ̀.”
But prophesy not again any more at Beth–el: for it is the king’s chapel, and it is the king’s court.
14 Amosi dá Amasiah lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ sikamore.
Then answered Amos, and said to Amaziah, I was no prophet, neither was I a prophet’s son; but I was an herdman, and a gatherer of sycomore fruit:
15 Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́lẹ̀ fun àwọn Israẹli ènìyàn mi.’
And Yhwh took me as I followed the flock, And Yhwh said unto me, Go, prophesy unto my people Israel.
16 Nítorí náà nísinsin yìí, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. Ìwọ wí pé, “‘Má ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí Israẹli, má sì ṣe wàásù sí ilé Isaaki.’
Now therefore hear thou the word of Yhwh: Thou sayest, Prophesy not against Israel, and drop not thy word against the house of Isaac.
17 “Nítorí náà, èyí ni ohun ti Olúwa wí: “‘Ìyàwó rẹ yóò di panṣágà ni ìlú, àwọn ọmọ ọkùnrin àti obìnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú. A ó fi okùn wọn ilẹ̀ rẹ, a ó sì pín in àti ìwọ pẹ̀lú yóò kú ni ilẹ̀ àìmọ́. Israẹli yóò sì lọ sí ìgbèkùn, kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’”
Therefore thus saith Yhwh; Thy wife shall be an harlot in the city, and thy sons and thy daughters shall fall by the sword, and thy land shall be divided by line; and thou shalt die in a polluted land: and Israel shall surely go into captivity forth of his land.

< Amos 7 >