< Amos 5 >

1 Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
Hear this word that I take up as a lament over you, house of Israel.
2 “Wúńdíá Israẹli ṣubú láì kò sì le padà dìde ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
The virgin Israel has fallen; she will rise no more; she is forsaken on her land; there is no one to raise her up.
3 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìlú tí ẹgbẹ̀rún alágbára ti jáde, yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli. Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
For this is what the Lord Yahweh says: “The city that went out with a thousand will have a hundred left, and the one that went out with a hundred will have ten left belonging to the house of Israel.”
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli: “Wá mi kí o sì yè;
For this is what Yahweh says to the house of Israel: “Seek me and live!
5 ẹ má ṣe wá Beteli, ẹ má ṣe lọ sí Gilgali, ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba. Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn, A ó sì sọ Beteli di asán.”
Do not seek Bethel; nor enter Gilgal; do not journey to Beersheba. For Gilgal will surely go into captivity, and Bethel will become nothing.
6 Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè, kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu a sì jó o run Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.
Seek Yahweh and live, or he will break out like fire in the house of Joseph. It will devour, and there will be no one to quench it in Bethel.
7 Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.
Those people turn justice into a bitter thing and throw righteousness down to the ground!”
8 Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀,
God made the Pleiades and Orion; he turns darkness into the morning; he makes the day dark with night and calls for the waters of the sea; he pours them out on the surface of the earth. Yahweh is his name!
9 Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.
He brings sudden destruction on the strong so that destruction comes on the fortresses.
10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
They hate anyone who corrects them in the city gate, and they abhor anyone who speaks the truth.
11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.
Because you trample down the poor and take portions of wheat from him— although you have built houses of worked stone, you will not live in them. You have delightful vineyards, but you will not drink their wine.
12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
For I know how many are your offenses and how great are your sins— you who afflict the just, take bribes, and turn aside the needy in the city gate.
13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí, nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
Therefore any prudent person is silent at such a time, for it is an evil time.
14 Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ. Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.
Seek good and not evil, so that you may live. So Yahweh, the God of hosts, will really be with you, as you say he is.
15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
Hate evil, love good, establish justice in the city gate. Perhaps Yahweh, the God of hosts, will be gracious to the remnant of Joseph.
16 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.
Therefore, this is what Yahweh says, the God of hosts, the Lord, “Wailing will be in all the squares, and they will say in all the streets, 'Woe! Woe!' They will call the farmers to mourning and the mourners to wail.
17 Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí.
In all vineyards there will be wailing, for I will pass through your midst,” says Yahweh.
18 Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa? Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.
Woe to you who desire the day of Yahweh! Why do you long for the day of Yahweh? It will be darkness and not light,
19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.
as when a man flees from a lion and a bear meets him, or he goes in a house and puts his hand on the wall and a snake bites him.
20 Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀? Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
Will not the day of Yahweh be darkness and not light? Gloom and no brightness?
21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín, Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.
“I hate, I despise your festivals, I take no delight in your solemn assemblies.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá. Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá. Èmi kò ní náání wọn.
Even though you offer me your burnt offerings and grain offerings, I will not accept them, neither will I look at the fellowship offerings of your fattened animals.
23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn! Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
Remove from me the noise of your songs; I will not listen to the sound of your harps.
24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
Instead, let justice flow like water, and righteousness like a constantly flowing stream.
25 “Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
Did you bring me sacrifices and offerings in the wilderness for forty years, house of Israel?
26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè, ibùgbé àwọn òrìṣà yín, àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ, èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
You have lifted up the images of Sikkuth, your king, and Kaiwan, your star god, which you made for yourselves.
27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,” ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.
Therefore I will exile you beyond Damascus,” says Yahweh, whose name is the God of hosts.

< Amos 5 >