< Amos 3 >
1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:
2 “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí; nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”
3 Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀ láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?
4 Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó, bí kò bá ní ohun ọdẹ? Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀ bí kò bá rí ohun kan mú?
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀ nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un? Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀ nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?
6 Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú, àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù? Tí ewu bá wa lórí ìlú kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?
7 Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan láìfi èrò rẹ̀ hàn fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.
8 Kìnnìún ti bú ramúramù ta ni kì yóò bẹ̀rù? Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀ ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?
9 Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti. “Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria; kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀ àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”
10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí, “àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”
11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run; yóò wó ibi gíga yín palẹ̀ a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli, tí ń gbé Samaria kúrò ní igun ibùsùn wọn ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run; ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò yóò sì wó lulẹ̀.
15 Èmi yóò wó ilé òtútù lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru; ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé a ó sì pa ilé ńlá náà run,” ni Olúwa wí.