< Acts 5 >

1 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan.
But a certain man named Ananias, with Sappirah, his wife, sold a possession,
2 Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
and kept back part of the price, his wife also being aware of it, and brought a certain part, and put it at the apostles' feet.
3 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà?
But Peter said, "Ananias, why has Satan filled your heart to lie to the Holy Spirit, and to keep back part of the price of the land?
4 Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”
While you kept it, did not it remain your own? After it was sold, was not it in your power? How is it that you have conceived this thing in your heart? You have not lied to people, but to God."
5 Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́.
Ananias, hearing these words, fell down and died. Great fear came on all who heard it.
6 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.
The young men arose and wrapped him up, and they carried him out and buried him.
7 Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé.
About three hours later, his wife, not knowing what had happened, came in.
8 Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?” Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
Peter answered her, "Tell me whether you sold the land for so much." She said, "Yes, for so much."
9 Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”
But Peter asked her, "How is it that you have agreed together to tempt the Spirit of the Lord? Look, the feet of those who have buried your husband are at the door, and they will carry you out."
10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀.
She fell down immediately at his feet, and died. The young men came in and found her dead, and they carried her out and buried her by her husband.
11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
Great fear came on the whole church, and on all who heard these things.
12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni.
By the hands of the apostles many signs and wonders were done among the people. They were all with one accord in Solomon's porch.
13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn.
None of the rest dared to join them, however the people honored them.
14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i.
More believers were added to the Lord, crowds of both men and women.
15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ.
They even carried out the sick into the streets, and put them on cots and mats, so that as Peter came by at the least his shadow would fall on some of them.
16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Crowds also came together from the cities around Jerusalem, bringing sick people, and those who were tormented by unclean spirits: and they were all healed.
17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀.
But the high priest rose up, and all those who were with him (which is the sect of the Sadducees), and they were filled with jealousy,
18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú.
and laid hands on the apostles, and put them in public custody.
19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde.
But an angel of the Lord opened the prison doors by night, and brought them out, and said,
20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
"Go stand and speak in the temple to the people all the words of this life."
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni. Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá.
When they heard this, they entered into the temple about daybreak, and taught. But the high priest came, and those who were with him, and called the council together, and all the elders of the children of Israel, and sent to the prison to have them brought.
22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé,
But the officers who came did not find them in the prison. They returned and reported,
23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.”
"We found the prison shut and locked, and the guards standing before the doors, but when we opened them, we found no one inside."
24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
Now when the captain of the temple, and the chief priests heard these words, they were very perplexed about them and what might become of this.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.”
One came and told them, "Look, the men whom you put in prison are in the temple, standing and teaching the people."
26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.
Then the captain went with the officers, and brought them without violence, for they were afraid that the people might stone them.
27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè.
When they had brought them, they set them before the council. The high priest questioned them,
28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”
saying, "Did we not strictly command you not to teach in this name? And look, you have filled Jerusalem with your teaching, and intend to bring this man's blood on us."
29 Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ!
But Peter and the apostles answered, "We must obey God rather than people.
30 Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.
The God of our fathers raised up Jesus, whom you killed, hanging him on a tree.
31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli.
God exalted him with his right hand to be a Leader and a Savior, to give repentance to Israel, and forgiveness of sins.
32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”
We are witnesses of these things; and so also is the Holy Spirit, whom God has given to those who obey him."
33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n.
But they, when they heard this, were furious, and wanted to kill them.
34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀.
But one stood up in the council, a Pharisee named Gamaliel, a teacher of the Law, honored by all the people, and commanded to put the men out for a little while.
35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí.
He said to them, "You men of Israel, be careful concerning these men, what you are about to do.
36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irinwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán.
For before these days Todah rose up, making himself out to be somebody; to whom a number of men, about four hundred, joined themselves: who was slain; and all, as many as obeyed him, were dispersed, and came to nothing.
37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká.
After this man, Judas of Galilee rose up in the days of the enrollment, and drew away some people after him. He also perished, and all, as many as obeyed him, were scattered abroad.
38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú.
Now I tell you, withdraw from these men, and leave them alone. For if this counsel or this work is of human origin, it will be overthrown.
39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”
But if it is of God, you will not be able to overthrow them, and you would be found even to be fighting against God."
40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.
They agreed with him. Summoning the apostles, they beat them and commanded them not to speak in the name of Jesus, and let them go.
41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀.
They therefore departed from the presence of the council, rejoicing that they were counted worthy to suffer dishonor for the Name.
42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìyìnrere náà pé Jesu ni Kristi.
Every day, in the temple and at home, they never stopped teaching and proclaiming that Jesus is the Christ.

< Acts 5 >