< Acts 23 >

1 Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.”
ἀτενίσας δὲ τῷ συνεδρίῳ ὁ Παῦλος εἶπεν, ἄνδρες ἀδελφοί, ἐγὼ πάσῃ συνειδήσει ἀγαθῇ πεπολίτευμαι τῷ θεῷ ἄχρι ταύτης τῆς ἡμέρας.
2 Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.
ὁ δὲ ἀρχιερεὺς Ἀνανίας ἐπέταξεν τοῖς παρεστῶσιν αὐτῷ τύπτειν αὐτοῦ τὸ στόμα.
3 Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”
τότε ὁ Παῦλος πρὸς αὐτὸν εἶπεν· τύπτειν σε μέλλει ὁ θεός, τοῖχε κεκονιαμένε· καὶ σὺ κάθῃ κρίνων με κατὰ τὸν νόμον, καὶ παρανομῶν κελεύεις με τύπτεσθαι;
4 Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
οἱ δὲ παρεστῶτες εἶπαν, τὸν ἀρχιερέα τοῦ θεοῦ λοιδορεῖς;
5 Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’”
ἔφη τε ὁ Παῦλος, οὐκ ᾔδειν, ἀδελφοί, ὅτι ἐστὶν ἀρχιερεύς· γέγραπται γὰρ ὅτι ἄρχοντα τοῦ λαοῦ σου οὐκ ἐρεῖς κακῶς.
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”
γνοὺς δὲ ὁ Παῦλος ὅτι τὸ ἓν μέρος ἐστὶν Σαδδουκαίων τὸ δὲ ἕτερον Φαρισαίων ἔκραζεν ἐν τῷ συνεδρίῳ, ἄνδρες ἀδελφοί, ἐγὼ Φαρισαῖός εἰμι, υἱὸς Φαρισαίων· περὶ ἐλπίδος καὶ ἀναστάσεως νεκρῶν ἐγὼ κρίνομαι.
7 Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì.
τοῦτο δὲ αὐτοῦ λαλήσαντος ἐγένετο στάσις τῶν Φαρισαίων καὶ Σαδδουκαίων, καὶ ἐσχίσθη τὸ πλῆθος.
8 Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì.
Σαδδουκαῖοι μὲν γὰρ λέγουσιν μὴ εἶναι ἀνάστασιν μήτε ἄγγελον μήτε πνεῦμα, Φαρισαῖοι δὲ ὁμολογοῦσιν τὰ ἀμφότερα.
9 Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?”
ἐγένετο δὲ κραυγὴ μεγάλη, καὶ ἀναστάντες τινὲς τῶν γραμματέων τοῦ μέρους τῶν Φαρισαίων διεμάχοντο λέγοντες, οὐδὲν κακὸν εὑρίσκομεν ἐν τῷ ἀνθρώπῳ τούτῳ· εἰ δὲ πνεῦμα ἐλάλησεν αὐτῷ ἢ ἄγγελος
10 Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.
πολλῆς δὲ γινομένης στάσεως φοβηθεὶς ὁ χιλίαρχος μὴ διασπασθῇ ὁ Παῦλος ὑπ’ αὐτῶν ἐκέλευσεν τὸ στράτευμα καταβὰν ἁρπάσαι αὐτὸν ἐκ μέσου αὐτῶν, ἄγειν τε εἰς τὴν παρεμβολήν.
11 Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”
τῇ δὲ ἐπιούσῃ νυκτὶ ἐπιστὰς αὐτῷ ὁ κύριος εἶπεν· θάρσει· ὡς γὰρ διεμαρτύρω τὰ περὶ ἐμοῦ εἰς Ἱερουσαλήμ, οὕτω σε δεῖ καὶ εἰς Ῥώμην μαρτυρῆσαι.
12 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Paulu.
Γενομένης δὲ ἡμέρας ποιήσαντες συστροφὴν οἱ Ἰουδαῖοι ἀνεθεμάτισαν ἑαυτοὺς, λέγοντες μήτε φαγεῖν μήτε πιεῖν ἕως οὗ ἀποκτείνωσιν τὸν Παῦλον.
13 Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ.
ἦσαν δὲ πλείους τεσσεράκοντα οἱ ταύτην τὴν συνωμοσίαν ποιησάμενοι·
14 Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu.
οἵτινες προσελθόντες τοῖς ἀρχιερεῦσιν καὶ τοῖς πρεσβυτέροις εἶπαν, ἀναθέματι ἀνεθεματίσαμεν ἑαυτοὺς μηδενὸς γεύσασθαι ἕως οὗ ἀποκτείνωμεν τὸν Παῦλον.
15 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”
νῦν οὖν ὑμεῖς ἐμφανίσατε τῷ χιλιάρχῳ σὺν τῷ συνεδρίῳ ὅπως καταγάγῃ αὐτὸν εἰς ὑμᾶς ὡς μέλλοντας διαγινώσκειν ἀκριβέστερον τὰ περὶ αὐτοῦ· ἡμεῖς δὲ πρὸ τοῦ ἐγγίσαι αὐτὸν ἕτοιμοί ἐσμεν τοῦ ἀνελεῖν αὐτόν.
16 Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.
Ἀκούσας δὲ ὁ υἱὸς τῆς ἀδελφῆς Παύλου τὴν ἐνέδραν παραγενόμενος καὶ εἰσελθὼν εἰς τὴν παρεμβολὴν ἀπήγγειλεν τῷ Παύλῳ.
17 Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”
προσκαλεσάμενος δὲ ὁ Παῦλος ἕνα τῶν ἑκατονταρχῶν ἔφη, τὸν νεανίαν τοῦτον ἄπαγε πρὸς τὸν χιλίαρχον, ἔχει γὰρ τι ἀπαγγεῖλαι αὐτῷ.
18 Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
ὁ μὲν οὖν παραλαβὼν αὐτὸν ἤγαγεν πρὸς τὸν χιλίαρχον καὶ φησίν, ὁ δέσμιος Παῦλος προσκαλεσάμενός με ἠρώτησεν τοῦτον τὸν νεανίσκον ἀγαγεῖν πρὸς σέ, ἔχοντά τι λαλῆσαί σοι.
19 Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”
ἐπιλαβόμενος δὲ τῆς χειρὸς αὐτοῦ ὁ χιλίαρχος καὶ ἀναχωρήσας κατ’ ἰδίαν ἐπυνθάνετο, τί ἐστιν ὃ ἔχεις ἀπαγγεῖλαί μοι;
20 Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.
εἶπεν δὲ ὅτι οἱ Ἰουδαῖοι συνέθεντο τοῦ ἐρωτῆσαί σε ὅπως αὔριον τὸν Παῦλον καταγάγῃς εἰς τὸ συνέδριον ὡς μέλλων τι ἀκριβέστερον πυνθάνεσθαι περὶ αὐτοῦ.
21 Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn, nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”
σὺ οὖν μὴ πεισθῇς αὐτοῖς· ἐνεδρεύουσιν γὰρ αὐτὸν ἐξ αὐτῶν ἄνδρες πλείους τεσσεράκοντα, οἵτινες ἀνεθεμάτισαν ἑαυτοὺς μήτε φαγεῖν μήτε πιεῖν ἕως οὗ ἀνέλωσιν αὐτόν, καὶ νῦν εἰσιν ἕτοιμοι προσδεχόμενοι τὴν ἀπὸ σοῦ ἐπαγγελίαν.
22 Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”
ὁ μὲν οὖν χιλίαρχος ἀπέλυσε τὸν νεανίσκον παραγγείλας μηδενὶ ἐκλαλῆσαι ὅτι ταῦτα ἐνεφάνισας πρός ἐμέ.
23 Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru.
Καὶ προσκαλεσάμενος τινας δύο τῶν ἑκατονταρχῶν εἶπεν, ἑτοιμάσατε στρατιώτας διακοσίους ὅπως πορευθῶσιν ἕως Καισαρίας, καὶ ἱππεῖς ἑβδομήκοντα καὶ δεξιολάβους διακοσίους, ἀπὸ τρίτης ὥρας τῆς νυκτός,
24 Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”
κτήνη τε παραστῆσαι ἵνα ἐπιβιβάσαντες τὸν Παῦλον διασώσωσι πρὸς Φήλικα τὸν ἡγεμόνα,
25 Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé,
γράψας ἐπιστολὴν ἔχουσαν τὸν τύπον τοῦτον·
26 Kilaudiu Lisia, sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ, àlàáfíà.
Κλαύδιος Λυσίας τῷ κρατίστῳ ἡγεμόνι Φήλικι χαίρειν.
27 Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á, nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Romu ni í ṣe.
τὸν ἄνδρα τοῦτον συλλημφθέντα ὑπὸ τῶν Ἰουδαίων καὶ μέλλοντα ἀναιρεῖσθαι ὑπ’ αὐτῶν ἐπιστὰς σὺν τῷ στρατεύματι ἐξειλάμην, μαθὼν ὅτι Ῥωμαῖός ἐστιν·
28 Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn.
βουλόμενός τε ἐπιγνῶναι τὴν αἰτίαν δι’ ἣν ἐνεκάλουν αὐτῷ κατήγαγον εἰς τὸ συνέδριον αὐτῶν·
29 Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fi sùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n.
ὃν εὗρον ἐγκαλούμενον περὶ ζητημάτων τοῦ νόμου αὐτῶν, μηδὲν δὲ ἄξιον θανάτου ἢ δεσμῶν ἔχοντα ἔγκλημα.
30 Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.
μηνυθείσης δέ μοι ἐπιβουλῆς εἰς τὸν ἄνδρα ἔσεσθαι, ἐξ αὐτῶν, ἔπεμψα πρὸς σέ, παραγγείλας καὶ τοῖς κατηγόροις λέγειν αὐτοὺς ἐπὶ σοῦ.
31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn.
Οἱ μὲν οὖν στρατιῶται κατὰ τὸ διατεταγμένον αὐτοῖς ἀναλαβόντες τὸν Παῦλον ἤγαγον διὰ νυκτὸς εἰς τὴν Ἀντιπατρίδα·
32 Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun.
τῇ δὲ ἐπαύριον ἐάσαντες τοὺς ἱππεῖς ἀπέρχεσθαι σὺν αὐτῷ ὑπέστρεψαν εἰς τὴν παρεμβολήν·
33 Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀.
οἵτινες εἰσελθόντες εἰς τὴν Καισάριαν καὶ ἀναδόντες τὴν ἐπιστολὴν τῷ ἡγεμόνι παρέστησαν καὶ τὸν Παῦλον αὐτῷ.
34 Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó béèrè pé agbègbè ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kilikia ni;
ἀναγνοὺς δὲ καὶ ἐπερωτήσας ἐκ ποίας ἐπαρχείας ἐστὶν καὶ πυθόμενος ὅτι ἀπὸ Κιλικίας,
35 Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.
διακούσομαί σου, ἔφη, ὅταν καὶ οἱ κατήγοροί σου παραγένωνται· κελεύσας ἐν τῷ πραιτωρίῳ τοῦ Ἡρῴδου φυλάσσεσθαι αὐτόν.

< Acts 23 >