< Acts 15 >

1 Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.”
Quelques disciples, venus de Judée, se mirent à enseigner les frères, disant: «Si vous ne vous faites circoncire suivant l'institution de Moïse, vous ne pouvez être sauvés.»
2 Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.
Mais un dissentiment et une dispute assez vive s'étant élevés entre Paul et Barnabas d'un côté, et ces gens de l’autre, on décida que Paul, Barnabas et quelques autres d'entre eux monteraient à Jérusalem vers les apôtres et les anciens, pour conférer sur cette question.
3 Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà, wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.
En conséquence, après avoir été accompagnés par l'église, ils traversèrent la Phénicie et la Samarie, où ils causèrent une grande joie à tous les frères en leur racontant la conversion des Gentils.
4 Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.
Arrivés à Jérusalem, ils furent reçus par l'église, les apôtres et les anciens, et ils rapportèrent tout ce que Dieu avait fait par leur moyen.
5 Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”
Mais quelques-uns du parti des pharisiens, qui avaient embrassé la foi, se levèrent en disant: «Il faut les circoncire et leur enjoindre d'observer la loi de Moïse.»
6 Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.
Les apôtres et les anciens s'assemblèrent pour examiner la question.
7 Nígbà tí iyàn sì di púpọ̀, Peteru dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ará, ẹ̀yin mọ̀ pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn nínú yín pé, kí àwọn aláìkọlà lè gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìnrere láti ẹnu mi, kí wọn sì gbàgbọ́.
Une longue discussion s'étant engagée, Pierre se leva et leur dit: «Frères, vous savez que, dès longtemps déjà, Dieu m'a choisi parmi vous pour faire entendre aux Gentils, par ma bouche, la parole de l'évangile, afin qu'ils croient:
8 Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olùmọ̀-ọkàn, sì jẹ́ wọn lẹ́rìí, ó fún wọn ni Ẹ̀mí Mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwa.
or Dieu, qui connaît les coeurs, a témoigné en leur faveur, en leur donnant le Saint-Esprit aussi bien qu'à nous;
9 Kò sí fi ìyàtọ̀ sí àárín àwa àti àwọn, ó ń fi ìgbàgbọ́ wẹ̀ wọ́n lọ́kàn mọ́.
il n'a point fait de différence entre eux et nous, ayant purifié leurs coeurs par la foi.
10 Ǹjẹ́ nítorí náà èéṣe tí ẹ̀yin o fi dán Ọlọ́run wò, láti fi àjàgà bọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́rùn, èyí tí àwọn baba wa àti àwa kò lè rù?
Pourquoi donc tentez-vous Dieu maintenant, en mettant sur le cou des disciples un joug, que ni nos pères ni nous n'avons pu porter?
11 Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jesu àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”
Nous croyons, au contraire, que c'est par la grâce du Seigneur Jésus que nous sommes sauvés, comme eux le croient aussi.»
12 Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi etí sí Barnaba àti Paulu, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrín àwọn aláìkọlà.
Toute l'assemblée garda le silence, et elle écouta Barnabas et Paul, qui racontèrent tous les miracles et les prodiges que Dieu avait faits par leur ministère au milieu des Gentils.
13 Lẹ́yìn tí wọn sì dákẹ́, Jakọbu dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi,
Quand ils eurent cessé de parler, Jacques prit la parole, et dit: «Frères, écoutez-moi:
14 Simeoni ti ròyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojú wo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.
Syméon a raconté comment Dieu a commencé de mettre à exécution son dessein de tirer du milieu des Gentils un peuple qui portât son nom.
15 Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe déédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:
Les déclarations des prophètes concordent avec ce fait, selon qu'il est écrit:
16 “‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà, èmi ó sì tún àgọ́ Dafidi pa tí ó ti wó lulẹ̀: èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́, èmi ó sì gbé e ró.
«Après cela je reviendrai, et je réédifierai la maison de David, qui est tombée; je réédifierai ses ruines, et je la relèverai,
17 Kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa, àti gbogbo àwọn kèfèrí, lára ẹni tí a ń pe orúkọ mi,’ ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí,
afin que le reste des hommes cherche le Seigneur, ainsi que toutes les nations auxquelles on donne mon nom, dit le Seigneur qui exécuté ces choses, »
18 ẹni tí ó sọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá. (aiōn g165)
lesquelles sont connues de toute antiquité. (aiōn g165)
19 “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.
En conséquence j'estime qu'il ne faut point inquiéter les Gentils qui se convertissent à Dieu,
20 Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú oúnjẹ tí a ṣe fún òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.
mais leur écrire de s'abstenir des souillures des idoles, du libertinage, des animaux étouffés et du sang.
21 Nítorí òfin Mose nígbà àtijọ́ ṣá ní a ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú Sinagọgu ni ọjọọjọ́ ìsinmi.”
Car, pour Moïse, depuis nombre de générations, il y a dans chaque ville des gens qui le prêchent, puisqu'on le lit chaque sabbat dans les synagogues.»
22 Nígbà nà án ni ó tọ́ lójú àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà pẹ̀lú gbogbo ìjọ, láti yan ènìyàn nínú wọn, àti láti rán wọ́n lọ sí Antioku pẹ̀lú Paulu àti Barnaba: Judasi ti a ń pè àpèlé rẹ̀ ní Barsaba, àti Sila, ẹni tí ó lórúkọ nínú àwọn arákùnrin.
Alors les apôtres et les anciens avec toute l'église arrêtèrent de choisir parmi eux quelques personnes qu'on enverrait à Antioche avec Paul et Barnabas. Ils choisirent Jude dit Barsabas et Silas, personnages éminents parmi les frères,
23 Wọn sì kọ ìwé lé wọn lọ́wọ́ báyìí pé, Àwọn aposteli, àti àwọn alàgbà, tí ó jẹ́ ti aláìkọlà tí ó wà ní Antioku, àti ní Siria, àti ní Kilikia.
et les chargèrent de la lettre que voici: «Les Apôtres, les Anciens et les frères, aux frères d'entre les Gentils qui sont à Antioche, en Syrie et en Cilicie, salut!
24 Níwọ́n bí àwa ti gbọ́ pé, àwọn kan ti ó ti ọ̀dọ̀ wa jáde wá ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, tí wọ́n ń yí yín ní ọkàn padà (wí pé, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàìmá kọ ilà, àti ṣàìmá pa òfin Mose mọ́), ẹni tí àwa kò fún ní àṣẹ.
— Ayant appris que quelques-uns des nôtres sont venus, sans notre aveu, vous troubler par des discours qui ont bouleversé vos âmes,
25 Ó yẹ lójú àwa, bí wa ti fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti yan ènìyàn láti rán wọn sí yín, pẹ̀lú Barnaba àti Paulu àwọn olùfẹ́ wa.
nous avons arrêté, en assemblée générale, de choisir des représentants et de vous les envoyer avec nos bien-aimés Barnabas et Paul,
26 Àwọn ọkùnrin ti ó fi ọkàn wọn wéwu nítorí orúkọ Olúwa wa Jesu Kristi.
ces hommes qui ont exposé leur vie pour le nom de notre Seigneur Jésus-Christ.
27 Nítorí náà àwa rán Judasi àti Sila àwọn tí yóò sì fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ ohun kan náà fún yín.
Nous vous avons donc député Jude et Silas, qui vous diront de bouche ce que nous vous écrivons,
28 Nítorí ó dára lójú Ẹ̀mí Mímọ́, àti lójú wa, kí a má ṣe di ẹrù le é yin lórí, bí kò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì;
c'est qu'il a semblé bon au Saint-Esprit et à nous, de ne vous point imposer de nouvelles charges, excepté ceci, qui est indispensable,
29 í ẹ̀yin fàsẹ́yìn kúrò nínú ẹran ti à pa bọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùnpa, àti nínú àgbèrè. Bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere. Àlàáfíà.
savoir, de vous abstenir de ce qui est sacrifié aux idoles, du sang, des animaux étouffés et du libertinage; toutes choses dont vous vous trouverez bien de vous garder. Adieu.»
30 Ǹjẹ́ nígbà tí wọ́n sì fi wọ́n sílẹ̀ láti lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá si Antioku. Nígbà tí wọn sì pé àwọn ìjọ papọ̀, wọn fi ìwé náà fún wọn.
Les députés ayant pris congé de l’église, allèrent à Antioche, et remirent la lettre à la multitude assemblée.
31 Nígbà tí wọn sì kà á, wọ́n yọ̀ fún ìtùnú náà.
On en fit lecture, et tous furent heureux de l'invitation qu'elle renfermait.
32 Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.
Jude et Silas, qui étaient eux-mêmes prophètes, exhortèrent les frères et les affermirent par un long discours.
33 Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.
Après avoir passé quelque temps avec eux, ils revinrent, avec les voeux des frères, vers ceux qui les avaient envoyés.
[Pour Silas, il trouva bon de rester à Antioche.]
35 Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.
Paul et Barnabas séjournèrent à Antioche, enseignant et annonçant, avec plusieurs autres, la parole du Seigneur.
36 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”
Mais, au bout de quelque temps, Paul dit à Barnabas: «Retournons visiter les frères dans les différentes villes où nous avons annoncé la parole du Seigneur, pour voir dans quel état ils se trouvent.»
37 Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku.
Barnabas fut d'avis de prendre aussi Jean dit Marc;
38 Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.
mais Paul estimait qu'il n'était pas juste de prendre avec eux un homme qui les avait abandonnés en Pamphylie, et qui ne les avait pas accompagnés dans leur oeuvre.
39 Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì, Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.
Il en résulta de l'irritation, au point qu'ils se séparèrent l'un de l'autre, et que Barnabas, prenant Marc avec lui, fit voile pour l'Ile de Chypre.
40 Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.
Paul, ayant fait choix de Silas, partit, après avoir été remis à la grâce du Seigneur par les frères.
41 Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.
Il parcourut la Syrie et la Cilicie, affermissant les églises, et arriva à Derbe et à Lystres.

< Acts 15 >