< Acts 13 >

1 Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu.
Now at the church in Antioch there were certain prophets and teachers: Barnabas, Simeon (who was called Niger), Lucius of Cyrene, Manaen (who had been brought up with Herod the tetrarch), and Saul.
2 Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”
As they were serving the Lord and fasting, the Holy Spirit said, “Set apart for me Barnabas and Saul for the work to which I have called them.”
3 Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.
So after they had fasted and prayed, they laid their hands on them and sent them off.
4 Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi.
Being sent out by the Holy Spirit, the two of them went down to Seleucia, and from there they sailed to Cyprus.
5 Nígbà ti wọ́n sì wà ni Salami, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Sinagọgu àwọn Júù. Johanu náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn.
When they arrived at Salamis, they proclaimed the word of God in the synagogues of the Jews. (They also had John as their assistant.)
6 Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Pafosi, wọ́n rí ọkùnrin oṣó àti wòlíì èké kan ti i ṣe Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Bar-Jesu.
When they had gone across the island to Paphos, they came across a certain magician, a Jewish false prophet named Bar-Jesus.
7 Ó wà lọ́dọ̀ Segiu Paulusi baálẹ̀ ìlú náà tí í ṣe amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Barnaba àti Saulu, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
He was with the proconsul Sergius Paulus, an intelligent man, who summoned Barnabas and Saul, seeking to hear the word of God.
8 Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́.
But the magician Elymas (for that is what his name means) opposed them, seeking to turn the proconsul away from the faith.
9 Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé,
But Saul, also known as Paul, filled with the Holy Spirit, looked intently at Elymas
10 “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?
and said, “O son of the devil, full of all deceit and all trickery, enemy of all righteousness, will yoʋ not cease perverting the straight paths of the Lord?
11 Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!” Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.
And now, behold, the hand of the Lord is against yoʋ, and yoʋ will be blind, unable to see the sun for a period of time.” Immediately a mist and darkness fell upon him, and he was going around seeking people to lead him by the hand.
12 Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.
When the proconsul saw what had happened, he believed, for he was astonished at the teaching of the Lord.
13 Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni Pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.
Then Paul and his companions set sail from Paphos and went to Perga in Pamphylia, but John left them and returned to Jerusalem.
14 Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.
Continuing on from Perga, they came to Antioch in Pisidia. On the Sabbath day they went into the synagogue and sat down.
15 Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”
After the reading of the Law and the Prophets, the rulers of the synagogue sent them a message, saying, “Brothers, if you have any word of exhortation for the people, speak it.”
16 Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!
Standing up, Paul motioned with his hand and said, “Men of Israel, and you who fear God, listen.
17 Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,
The God of this people chose our fathers and exalted the people during their sojourn in the land of Egypt, and with an uplifted arm he led them out of that country.
18 ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù,
For about forty years, he put up with them in the wilderness,
19 nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.
and after destroying seven nations in the land of Canaan, he gave his people their land as an inheritance.
20 Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta lé ní irinwó ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì.
After that he gave them judges for about four hundred and fifty years, up to the time of the prophet Samuel.
21 Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.
Then the people asked for a king, and God gave them Saul the son of Kish, a man of the tribe of Benjamin, who reigned for forty years.
22 Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’
After removing Saul, God raised up David as their king, about whom he testified, ‘I have found David the son of Jesse to be a man after my own heart; he will do all that I want him to do.’
23 “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.
From this man's offspring God brought salvation to Israel, according to his promise,
24 Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli.
after John had first preached a baptism of repentance to Israel in advance of the coming Savior.
25 Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’
Now as John was completing his course, he said, ‘Who do you suppose that I am? I am not he. But behold, one is coming after me, the sandals of whose feet I am not worthy to untie.’
26 “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.
“Brothers, sons of the family of Abraham, and those among you who fear God, to you the message of this salvation has been sent.
27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.
Since those who dwell in Jerusalem, along with their rulers, failed to recognize this man and the voices of the prophets that are read every Sabbath, they fulfilled their words by condemning him.
28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á.
Even though they found no grounds for a death sentence, they asked Pilate to have him killed.
29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.
When they had fulfilled all that was written about him, they took him down from the cross and laid him in a tomb.
30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,
But God raised him from the dead,
31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
and for many days he was seen by those who had come up with him from Galilee to Jerusalem, who are his witnesses to the people.
32 “Àwa sì mú ìyìnrere wá fún yín pé, ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,
And we preach to you the good news that what God promised to our fathers, he has fulfilled to us, their children, by raising up Jesus,
33 èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde, bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé, “‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’
just as it is written in the second Psalm, ‘Yoʋ are my son; today I have begotten yoʋ.’
34 Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
As for the fact that he raised him from the dead, no longer to return to corruption, God has spoken in this way: ‘I will give you the holy and sure blessings of David.’
35 Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé, “‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’
Therefore it also says in another place: ‘Yoʋ will not let yoʋr Holy One see corruption.’
36 “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
For when David had served God's purpose in his own generation, he fell asleep, was added to his fathers, and saw corruption.
37 Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́.
But he whom God raised up did not see corruption.
38 “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.
Therefore let it be known to you, brothers, that through this man remission of sins is proclaimed to you,
39 Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose.
and by this man everyone who believes is set free from everything from which you could not be set free by the law of Moses.
40 Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
So beware that what is said in the prophets does not happen to you:
41 “‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’”
‘Behold, you scoffers, be amazed and perish, for I am doing a work in your days that you will certainly not believe, even if someone tells you about it.’”
42 Bí Paulu àti Barnaba sì ti ń jáde láti inú Sinagọgu, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.
Now as Paul and Barnabas were going out from the synagogue of the Jews, the Gentiles were urging them to speak about these things on the next Sabbath.
43 Nígbà tí wọn sì jáde nínú Sinagọgu, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀lé Paulu àti Barnaba, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
And when the meeting of the synagogue was dispersed, many of the Jews and the devout converts to Judaism followed Paul and Barnabas, who spoke to them and persuaded them to continue in the grace of God.
44 Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ péjọ tan láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
On the following Sabbath, nearly the entire city was gathered together to hear the word of God.
45 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Paulu ń sọ.
But when the Jews saw the crowds, they were filled with jealousy and began to contradict what Paul was saying, opposing him and slandering him.
46 Paulu àti Barnaba sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà. (aiōnios g166)
But Paul and Barnabas spoke boldly, saying, “It was necessary for the word of God to be spoken first to you. But since you are rejecting it and do not judge yourselves to be worthy of eternal life, behold, we are turning to the Gentiles. (aiōnios g166)
47 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’”
For this is what the Lord has commanded us: ‘I have appointed yoʋ to be a light to the Gentiles, so that yoʋ may bring salvation to the ends of the earth.’”
48 Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. (aiōnios g166)
When the Gentiles heard this, they began rejoicing and glorifying the word of the Lord, and all who were appointed to eternal life believed. (aiōnios g166)
49 A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà.
So the word of the Lord spread throughout that entire region.
50 Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Paulu àti Barnaba, wọ́n sì le wọn kúrò ni agbègbè wọn.
But the Jews incited the devout women of high standing and the prominent men of the city. They stirred up persecution against Paul and Barnabas, and drove them out of their region.
51 Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikoniomu.
But Paul and Barnabas shook off the dust from their feet in protest against them and went to Iconium.
52 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.
And the disciples were filled with joy and with the Holy Spirit.

< Acts 13 >