< 2 Samuel 1 >

1 Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì.
factum est autem postquam mortuus est Saul ut David reverteretur a caede Amalech et maneret in Siceleg dies duos
2 Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.
in die autem tertia apparuit homo veniens de castris Saul veste conscissa et pulvere aspersus caput et ut venit ad David cecidit super faciem suam et adoravit
3 Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?” “Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.”
dixitque ad eum David unde venis qui ait ad eum de castris Israhel fugi
4 Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.” Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.”
et dixit ad eum David quod est verbum quod factum est indica mihi qui ait fugit populus e proelio et multi corruentes e populo mortui sunt sed et Saul et Ionathan filius eius interierunt
5 Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.”
dixitque David ad adulescentem qui nuntiabat unde scis quia mortuus est Saul et Ionathan filius eius
6 Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “Mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀.
ait adulescens qui narrabat ei casu veni in montem Gelboe et Saul incumbebat super hastam suam porro currus et equites adpropinquabant ei
7 Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’
et conversus post tergum suum vidensque me vocavit cui cum respondissem adsum
8 “Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’ “Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’
dixit mihi quisnam es tu et aio ad eum Amalechites sum
9 “Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’
et locutus est mihi sta super me et interfice me quoniam tenent me angustiae et adhuc tota anima in me est
10 “Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.”
stansque super eum occidi illum sciebam enim quod vivere non poterat post ruinam et tuli diadema quod erat in capite eius et armillam de brachio illius et adtuli ad te dominum meum huc
11 Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya.
adprehendens autem David vestimenta sua scidit omnesque viri qui erant cum eo
12 Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.
et planxerunt et fleverunt et ieiunaverunt usque ad vesperam super Saul et super Ionathan filium eius et super populum Domini et super domum Israhel quod corruissent gladio
13 Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?” O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.”
dixitque David ad iuvenem qui nuntiaverat ei unde es qui respondit filius hominis advenae amalechitae ego sum
14 Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni àmì òróró Olúwa?”
et ait ad eum David quare non timuisti mittere manum tuam ut occideres christum Domini
15 Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú.
vocansque David unum de pueris ait accedens inrue in eum qui percussit illum et mortuus est
16 Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé, ‘Mo pa ẹni àmì òróró Olúwa.’”
et ait ad eum David sanguis tuus super caput tuum os enim tuum locutum est adversum te dicens ego interfeci christum Domini
17 Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀,
planxit autem David planctum huiuscemodi super Saul et super Ionathan filium eius
18 Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari):
et praecepit ut docerent filios Iuda arcum sicut scriptum est in libro Iustorum
19 “Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ. Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!
incliti Israhel super montes tuos interfecti sunt quomodo ceciderunt fortes
20 “Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati, ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni, kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀, kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú.
nolite adnuntiare in Geth neque adnuntietis in conpetis Ascalonis ne forte laetentur filiae Philisthim ne exultent filiae incircumcisorum
21 “Ẹ̀yin òkè Gilboa, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò, tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá. Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé, asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.
montes Gelboe nec ros nec pluviae veniant super vos neque sint agri primitiarum quia ibi abiectus est clypeus fortium clypeus Saul quasi non esset unctus oleo
22 “Ọrun Jonatani kì í padà bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán, láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa, àti ẹran àwọn alágbára.
a sanguine interfectorum ab adipe fortium sagitta Ionathan numquam rediit retrorsum et gladius Saul non est reversus inanis
23 Saulu àti Jonatani— ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn, ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n. Wọ́n yára ju idì lọ, wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.
Saul et Ionathan amabiles et decori in vita sua in morte quoque non sunt divisi aquilis velociores leonibus fortiores
24 “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli, ẹ sọkún lórí Saulu, ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín, ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín.
filiae Israhel super Saul flete qui vestiebat vos coccino in deliciis qui praebebat ornamenta aurea cultui vestro
25 “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun! Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.
quomodo ceciderunt fortes in proelio Ionathan in excelsis tuis occisus est
26 Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi; ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi. Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu, ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.
doleo super te frater mi Ionathan decore nimis et amabilis super amorem mulierum
27 “Wò ó bí alágbára ti ṣubú! Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”
quomodo ceciderunt robusti et perierunt arma bellica

< 2 Samuel 1 >