< 2 Samuel 9 >

1 Dafidi sì béèrè pé, ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ń ṣe ìdílé Saulu kù síbẹ̀ bí? Kí èmi lè ṣe oore fún un nítorí Jonatani.
ויאמר דוד--הכי יש עוד אשר נותר לבית שאול ואעשה עמו חסד בעבור יהונתן
2 Ìránṣẹ́ kan sì ti wà ní ìdílé Saulu, orúkọ rẹ̀ sí ń jẹ́ Ṣiba, wọ́n sì pè é wá sọ́dọ̀ Dafidi, ọba sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ìwọ ni Ṣiba bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni.”
ולבית שאול עבד ושמו ציבא ויקראו לו אל דוד ויאמר המלך אליו האתה ציבא ויאמר עבדך
3 Ọba sì wí pé, “Kò ha sí ọ̀kan nínú ìdílé Saulu síbẹ̀, kí èmi ṣe oore Ọlọ́run fún un?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Jonatani ní ọmọ kan síbẹ̀ tó ya arọ.”
ויאמר המלך האפס עוד איש לבית שאול ואעשה עמו חסד אלהים ויאמר ציבא אל המלך עוד בן ליהונתן נכה רגלים
4 Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?” Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Makiri, ọmọ Ammieli, ní Lo-Debari.”
ויאמר לו המלך איפה הוא ויאמר ציבא אל המלך הנה הוא בית מכיר בן עמיאל בלו דבר
5 Dafidi ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Makiri ọmọ Ammieli láti Lo-Debari wá.
וישלח המלך דוד ויקחהו מבית מכיר בן עמיאל--מלו דבר
6 Mefiboṣeti ọmọ Jonatani ọmọ Saulu sì tọ Dafidi wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un. Dafidi sì wí pé, “Mefiboṣeti!” Òun sì dáhùn wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”
ויבא מפיבשת בן יהונתן בן שאול אל דוד ויפל על פניו וישתחו ויאמר דוד מפיבשת ויאמר הנה עבדך
7 Dafidi sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jonatani baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Saulu baba rẹ fún ọ, ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”
ויאמר לו דוד אל תירא כי עשה אעשה עמך חסד בעבור יהונתן אביך והשבתי לך את כל שדה שאול אביך ואתה תאכל לחם על שלחני--תמיד
8 Mefiboṣeti sì tẹríba, ó sì wí pé, “Kí ni ìránṣẹ́ rẹ jásí, tí ìwọ ó fi máa wo òkú ajá bí èmi.”
וישתחו ויאמר מה עבדך כי פנית אל הכלב המת אשר כמוני
9 Ọba sì pe Ṣiba ìránṣẹ́ Saulu, ó sì wí fún un pé, “Gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Saulu, àti gbogbo èyí tí í ṣe ti ìdílé rẹ̀ ni èmi fi fún ọmọ olúwa rẹ.
ויקרא המלך אל ציבא נער שאול--ויאמר אליו כל אשר היה לשאול ולכל ביתו נתתי לבן אדניך
10 Ìwọ, àti àwọn ọmọ rẹ, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni yóò sì máa ro ilẹ̀ náà fún un, ìwọ ni yóò sì máa mú ìkórè wá, ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa rí oúnjẹ jẹ, ṣùgbọ́n Mefiboṣeti ọmọ olúwa rẹ yóò sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.” (Ṣiba sì ní ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ogún ìránṣẹ́kùnrin.)
ועבדת לו את האדמה אתה ובניך ועבדיך והבאת והיה לבן אדניך לחם ואכלו ומפיבשת בן אדניך יאכל תמיד לחם על שלחני ולציבא חמשה עשר בנים--ועשרים עבדים
11 Ṣiba sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí olúwa mi ọba ti pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Mefiboṣeti, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
ויאמר ציבא אל המלך ככל אשר יצוה אדני המלך את עבדו כן יעשה עבדך ומפיבשת אכל על שלחני כאחד מבני המלך
12 Mefiboṣeti sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Ṣiba ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Mefiboṣeti.
ולמפיבשת בן קטן ושמו מיכא וכל מושב בית ציבא עבדים למפיבשת
13 Mefiboṣeti sì ń gbé ní Jerusalẹmu, òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ ọba; òun sì yarọ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.
ומפיבשת ישב בירושלם כי על שלחן המלך תמיד הוא אכל והוא פסח שתי רגליו

< 2 Samuel 9 >