< 2 Samuel 6 >
1 Dafidi sì tún kó gbogbo àwọn akọni ọkùnrin ní Israẹli jọ, wọ́n sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.
После скупи опет Давид све људе изабране из Израиља, тридесет хиљада.
2 Dafidi sì dìde, ó sì lọ àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ́ lọ́dọ̀ rẹ́, láti Baalahi ní Juda wá, láti mú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run tí ibẹ̀ wá, èyí tí a ń pe orúkọ rẹ̀ ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó jókòó láàrín àwọn kérúbù.
Па се подиже Давид и сав народ што беше с њим и отиде из Вале Јудине да пренесе отуда ковчег Божји, код ког се призива име, име Господа над војскама, који седи на херувимима.
3 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run náà gun kẹ̀kẹ́ tuntun kan, wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu wá, èyí tí ó wà ní Gibeah: Ussa àti Ahio, àwọn ọmọ Abinadabu sì ń dá kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
И метнуше ковчег Божји на нова кола, и повезоше га из куће Авинадавове, која беше на брду; а Уза и Ахијо синови Авинадавови управљаху новим колима.
4 Wọ́n sì mú un láti ilé Abinadabu jáde wá, tí ó wà ní Gibeah, pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, Ahio sì ń rìn níwájú àpótí ẹ̀rí náà.
И одвезоше ковчег Божји из куће Авинадавове, која беше на брду, и Ахијо иђаше пред ковчегом.
5 Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì ṣiré níwájú Olúwa lára gbogbo onírúurú ohun èlò orin tí a fi igi arère ṣe àti lára ìlù haapu, ní ara tambori, sisitirumu àti lára kimbali.
А Давид и сав дом Израиљев удараху пред Господом у свакојаке справе од дрвета кедровог, у гусле, у псалтире, у бубње, у свирале и у кимвале.
6 Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Nakoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, ó sì dìímú, nítorí tí màlúù kọsẹ̀.
А кад дођоше до гумна Нахоновог, Уза се маши за ковчег Божји и прихвати га, јер волови потегоше на страну.
7 Ìbínú Olúwa sì ru sí Ussa; Ọlọ́run sì pa á níbẹ̀ nítorí ìṣísẹ̀ rẹ̀; níbẹ̀ ni ó sì kù ní ẹ̀bá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.
И Господ се разгневи на Узу, и удари га Бог онде за ту непажњу, те умре онде код ковчега Божијег.
8 Inú Dafidi sì bàjẹ́ nítorí tí Olúwa gé Ussa kúrò, ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Peresi-Usa títí ó fi di òní yìí.
И ожалости се Давид што Господ уби Узу. Зато се прозва оно место Фарес-Уза до данас.
9 Dafidi sì bẹ̀rù Olúwa ní ọjọ́ náà, ó sì wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò ti ṣe tọ̀ mí wá?”
И уплаши се Давид од Господа у онај дан, и рече: Како ће доћи к мени ковчег Господњи?
10 Dafidi kò sì fẹ́ mú àpótí ẹ̀rí Olúwa sọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìlú Dafidi; ṣùgbọ́n Dafidi sì mú un yà sí ilé Obedi-Edomu ará Gitti.
И не хте Давид одвести ковчег Господњи к себи у град Давидов; него га склони Давид у кућу Овид-Едома Гетејина.
11 Àpótí ẹ̀rí Olúwa sì gbé ní ilé Obedi-Edomu ará Gitti ní oṣù mẹ́ta; Olúwa sì bùkún fún Obedi-Edomu, àti gbogbo ilé rẹ̀.
И оста ковчег Господњи у кући Овид-Едома Гетејина три месеца, и благослови Господ Овид-Едома и сав дом његов.
12 A sì rò fún Dafidi ọba pé, “Olúwa ti bùkún fún ilé Obedi-Edomu, àti gbogbo èyí tí í ṣe tirẹ̀, nítorí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run.” Dafidi sì lọ, ó sì mú àpótí ẹ̀rí náà gòkè láti ilé Obedi-Edomu wá sí ìlú Dafidi pẹ̀lú ayọ̀.
И јавише цару Давиду говорећи: Господ благослови дом Овид-Едомов и све што има ради ковчега Божијег. Тада отиде Давид, и пренесе ковчег Божји из куће Овид-Едомове у град Давидов с весељем.
13 Ó sì ṣe nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ru àpótí ẹ̀rí Olúwa bá sì ṣí ẹsẹ̀ mẹ́fà, òun a sì fi màlúù àti ẹran àbọ́pa rú ẹbọ.
И кад они који ношаху ковчег Господњи поступише шест корака, принесе на жртву вола и дебела овна.
14 Dafidi sì fi gbogbo agbára rẹ̀ jó níwájú Olúwa; Dafidi sì wọ efodu ọ̀gbọ̀.
И Давид играше из све снаге пред Господом, и беше огрнут оплећком ланеним.
15 Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti gbogbo ilé Israẹli sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.
Тако Давид и сав дом Израиљев ношаху ковчег Господњи подвикујући и трубећи у трубе.
16 Bí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dafidi wá; Mikali ọmọbìnrin Saulu sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dafidi ọba ń fò sókè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.
А кад ковчег Господњи улажаше у град Давидов, Михала кћи Саулова гледајући с прозора виде цара Давида где скаче и игра пред Господом, и подругну му се у срцу свом.
17 Wọ́n sì mú àpótí ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrín àgọ́ náà tí Dafidi pa fún un. Dafidi sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa.
А кад донесоше ковчег Господњи, наместише га на његово место у шатору који му разапе Давид. И принесе Давид жртве захвалне пред Господом.
18 Dafidi sì parí ìṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà, ó sì súre fún àwọn ènìyàn náà ní orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Потом принесавши Давид жртве паљенице и жртве захвалне благослови народ у име Господа над војскама.
19 Ó sì pín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà, àní fún gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn Israẹli, àti ọkùnrin àti obìnrin; fún olúkúlùkù ìṣù àkàrà kan àti ekìrí ẹran kan, àti àkàrà díndín kan. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì túká lọ, olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
И раздаде међу сав народ, међу све мноштво Израиљево, и људима и женама, сваком по један хлеб и комад меса и жбан вина. Потом отиде народ, свак својој кући.
20 Dafidi sì yípadà láti súre fún àwọn ará ilé rẹ̀, Mikali ọmọbìnrin Saulu sì jáde láti wá pàdé Dafidi, ó sì wí pé, “Báwo ni ọba Israẹli ṣe ṣe ara rẹ̀ lógo bẹ́ẹ̀ lónìí, tí ó bọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ lónìí lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn lásán tí ń bọ́ra rẹ̀ sílẹ̀.”
И Давид се врати да благослови свој дом; а Михала кћи Саулова изиђе на сусрет Давиду, и рече: Како је славан био данас цар Израиљев, кад се данас откривао пред слушкињама слуга својих, као што се откривају никакви људи!
21 Dafidi sì wí fún Mikali pé, “Níwájú Olúwa ni, ẹni tí ó yàn mí fẹ́ ju baba rẹ lọ, àti ju gbogbo ìdílé rẹ lọ, láti fi èmi ṣe olórí àwọn ènìyàn Olúwa, àní lórí Israẹli, èmi ó sì súre níwájú Olúwa.
А Давид рече Михали: Пред Господом, који ме је изабрао преко оца твог и преко свега дома његовог, те ми заповедио да будем вођ народу Господњем, Израиљу, играо сам, и играћу пред Господом.
22 Èmi ó sì tún rẹ ara mi sílẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ, èmi ó sì ṣe aláìníyìn lójú ara mi, àti lójú àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà ti ìwọ wí, lọ́dọ̀ wọn náà ni èmi ó sì ní ògo.”
И још ћу се већма понизити, и још ћу мањи себи бити; и опет ћу бити славан пред слушкињама, за које говориш.
23 Mikali ọmọbìnrin Saulu kò sì bí ọmọ, títí o fi di ọjọ́ ikú rẹ̀ nítorí tí ó sọ̀rọ̀-òdì yìí sí Dafidi.
И Михала кћи Саулова не има порода до смрти своје.