< 2 Samuel 22 >

1 Dafidi sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Saulu.
וידבר דוד ליהוה את דברי השירה הזאת ביום הציל יהוה אתו מכף כל איביו ומכף שאול׃
2 Ó sì wí pé, “Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;
ויאמר יהוה סלעי ומצדתי ומפלטי לי׃
3 Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwo ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi. Àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.
אלהי צורי אחסה בו מגני וקרן ישעי משגבי ומנוסי משעי מחמס תשעני׃
4 “Èmi ké pe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.
מהלל אקרא יהוה ומאיבי אושע׃
5 Nígbà tí ìbìlù ìrora ikú yí mi káàkiri; tí àwọn ìṣàn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
כי אפפני משברי מות נחלי בליעל יבעתני׃
6 Ọ̀já isà òkú yí mi káàkiri; ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. (Sheol h7585)
חבלי שאול סבני קדמני מקשי מות׃ (Sheol h7585)
7 “Nínú ìpọ́njú mi, èmi ké pé Olúwa, èmi sì gbé ohùn mi sókè sí Ọlọ́run mi. Ó sí gbóhùn mi láti tẹmpili rẹ̀ igbe mí wọ etí rẹ̀.
בצר לי אקרא יהוה ואל אלהי אקרא וישמע מהיכלו קולי ושועתי באזניו׃
8 Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì; ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì, ó sì mì, nítorí tí ó bínú.
ותגעש ותרעש הארץ מוסדות השמים ירגזו ויתגעשו כי חרה לו׃
9 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá, iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
עלה עשן באפו ואש מפיו תאכל גחלים בערו ממנו׃
10 Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀; òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
ויט שמים וירד וערפל תחת רגליו׃
11 Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò, a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
וירכב על כרוב ויעף וירא על כנפי רוח׃
12 Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi, àní ìṣúdudu ìkùùkuu àwọ̀ sánmọ̀.
וישת חשך סביבתיו סכות חשרת מים עבי שחקים׃
13 Nípasẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ ẹ̀yín iná ràn.
מנגה נגדו בערו גחלי אש׃
14 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá, Ọ̀gá-ògo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.
ירעם מן שמים יהוה ועליון יתן קולו׃
15 Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká; ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.
וישלח חצים ויפיצם ברק ויהמם׃
16 Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn, ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn, nípa ìbáwí Olúwa, nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.
ויראו אפקי ים יגלו מסדות תבל בגערת יהוה מנשמת רוח אפו׃
17 “Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
ישלח ממרום יקחני ימשני ממים רבים׃
18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
יצילני מאיבי עז משנאי כי אמצו ממני׃
19 Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi, ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀yìntì mi.
יקדמני ביום אידי ויהי יהוה משען לי׃
20 Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá, ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.
ויצא למרחב אתי יחלצני כי חפץ בי׃
21 “Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.
יגמלני יהוה כצדקתי כבר ידי ישיב לי׃
22 Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
כי שמרתי דרכי יהוה ולא רשעתי מאלהי׃
23 Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.
כי כל משפטו לנגדי וחקתיו לא אסור ממנה׃
24 Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.
ואהיה תמים לו ואשתמרה מעוני׃
25 Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀.
וישב יהוה לי כצדקתי כברי לנגד עיניו׃
26 “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo.
עם חסיד תתחסד עם גבור תמים תתמם׃
27 Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.
עם נבר תתבר ועם עקש תתפל׃
28 Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
ואת עם עני תושיע ועיניך על רמים תשפיל׃
29 Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
כי אתה נירי יהוה ויהוה יגיה חשכי׃
30 Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.
כי בכה ארוץ גדוד באלהי אדלג שור׃
31 “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dánwò. Òun sì ni asà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.
האל תמים דרכו אמרת יהוה צרופה מגן הוא לכל החסים בו׃
32 Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa? Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.
כי מי אל מבלעדי יהוה ומי צור מבלעדי אלהינו׃
33 Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára, ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.
האל מעוזי חיל ויתר תמים דרכו׃
34 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó sì mú mi dúró ní ibi gíga mi.
משוה רגליו כאילות ועל במותי יעמדני׃
35 Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà; tó bẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.
מלמד ידי למלחמה ונחת קשת נחושה זרעתי׃
36 Ìwọ sì ti fún mi ní asà ìgbàlà rẹ̀; ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.
ותתן לי מגן ישעך וענתך תרבני׃
37 Ìwọ sì sọ ìtẹ̀lẹ̀ di ńlá ní abẹ́ mi; tó bẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.
תרחיב צעדי תחתני ולא מעדו קרסלי׃
38 “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n, èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.
ארדפה איבי ואשמידם ולא אשוב עד כלותם׃
39 Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn, wọn kò sì le dìde mọ́, wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.
ואכלם ואמחצם ולא יקומון ויפלו תחת רגלי׃
40 Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà; àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.
ותזרני חיל למלחמה תכריע קמי תחתני׃
41 Ìwọ sì mú àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà fún mi, èmi ó sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
ואיבי תתה לי ערף משנאי ואצמיתם׃
42 Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n; wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.
ישעו ואין משיע אל יהוה ולא ענם׃
43 Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.
ואשחקם כעפר ארץ כטיט חוצות אדקם ארקעם׃
44 “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi, ìwọ pa mi mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn tí èmi kò tí mọ̀ yóò máa sìn mí.
ותפלטני מריבי עמי תשמרני לראש גוים עם לא ידעתי יעבדני׃
45 Àwọn àjèjì wá láti tẹríba fún mi; bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọ́n á sì gbọ́ tèmi.
בני נכר יתכחשו לי לשמוע אזן ישמעו לי׃
46 Àyà yóò pá àwọn àlejò, wọ́n ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.
בני נכר יבלו ויחגרו ממסגרותם׃
47 “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi! Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.
חי יהוה וברוך צורי וירם אלהי צור ישעי׃
48 Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi, àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.
האל הנתן נקמת לי ומוריד עמים תחתני׃
49 Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó kórìíra mi lọ; ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.
ומוציאי מאיבי ומקמי תרוממני מאיש חמסים תצילני׃
50 Nítorí náà èmi ó fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa, láàrín àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè, èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.
על כן אודך יהוה בגוים ולשמך אזמר׃
51 “Òun ni ilé ìṣọ́ ìgbàlà fún ọba rẹ̀; ó sì fi àánú hàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀, fún Dafidi, àti fún irú-ọmọ rẹ̀ títí láéláé.”
מגדיל ישועות מלכו ועשה חסד למשיחו לדוד ולזרעו עד עולם׃

< 2 Samuel 22 >