< 2 Kings 3 >

1 Jehoramu ọmọ Ahabu sì di ọba Israẹli ní Samaria ní ọdún kejìdínlógún ti Jehoṣafati ọba Juda, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjìlá.
ויהורם בן אחאב מלך על ישראל בשמרון בשנת שמנה עשרה ליהושפט מלך יהודה וימלך שתים עשרה שנה
2 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti ìyá àti baba rẹ̀ ti ṣe. Ó gbé òkúta ère ti Baali tí baba rẹ̀ ti ṣe kúrò.
ויעשה הרע בעיני יהוה--רק לא כאביו וכאמו ויסר את מצבת הבעל אשר עשה אביו
3 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó ti fi Israẹli bú láti dẹ́ṣẹ̀; kò sì yí kúrò lọ́dọ̀ wọn.
רק בחטאות ירבעם בן נבט אשר החטיא את ישראל--דבק לא סר ממנה
4 Nísinsin yìí Meṣa ọba Moabu ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Israẹli pẹ̀lú ọ̀kẹ́ márùn-ún ọ̀dọ́-àgùntàn àti pẹ̀lú irun ọ̀kẹ́ márùn-ún àgbò.
ומישע מלך מואב היה נקד והשיב למלך ישראל מאה אלף כרים ומאה אלף אילים צמר
5 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Ahabu, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Israẹli.
ויהי כמות אחאב ויפשע מלך מואב במלך ישראל
6 Lásìkò ìgbà yìí ọba Jehoramu jáde kúrò ní Samaria ó sì yí gbogbo Israẹli ní ipò padà.
ויצא המלך יהורם ביום ההוא--משמרון ויפקד את כל ישראל
7 Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Moabu jà?” Ọba Juda sì dáhùn pé, “Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ. Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”
וילך וישלח אל יהושפט מלך יהודה לאמר מלך מואב פשע בי--התלך אתי אל מואב למלחמה ויאמר אעלה כמוני כמוך כעמי כעמך כסוסי כסוסיך
8 “Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dojúkọ wọ́n?” Ó béèrè. “Lọ́nà aginjù Edomu,” ó dáhùn.
ויאמר אי זה הדרך נעלה ויאמר דרך מדבר אדום
9 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli jáde lọ pẹ̀lú ọba Juda àti ọba Edomu. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ-ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.
וילך מלך ישראל ומלך יהודה ומלך אדום ויסבו דרך שבעת ימים ולא היה מים למחנה ולבהמה אשר ברגליהם
10 “Kí ni?” ọba Israẹli kígbe sókè. “Ṣé Olúwa pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́?”
ויאמר מלך ישראל אהה--כי קרא יהוה לשלשת המלכים האלה לתת אותם ביד מואב
11 Ṣùgbọ́n Jehoṣafati sì wí pé, “Ṣé kò sí wòlíì Olúwa níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?” Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Israẹli dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati wà níbí. Ó máa sábà bu omi sí ọwọ́ Elijah.”
ויאמר יהושפט האין פה נביא ליהוה ונדרשה את יהוה מאותו ויען אחד מעבדי מלך ישראל ויאמר פה אלישע בן שפט אשר יצק מים על ידי אליהו
12 Jehoṣafati wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Israẹli àti Jehoṣafati àti ọba Edomu sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ.
ויאמר יהושפט יש אותו דבר יהוה וירדו אליו מלך ישראל ויהושפט--ומלך אדום
13 Eliṣa wí fún ọba Israẹli pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì baba rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.” Ọba Israẹli dá a lóhùn, “Rárá, nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Moabu lọ́wọ́.”
ויאמר אלישע אל מלך ישראל מה לי ולך--לך אל נביאי אביך ואל נביאי אמך ויאמר לו מלך ישראל אל כי קרא יהוה לשלשת המלכים האלה לתת אותם ביד מואב
14 Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jehoṣafati ọba Juda, èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ.
ויאמר אלישע חי יהוה צבאות אשר עמדתי לפניו כי לולי פני יהושפט מלך יהודה אני נשא--אם אביט אליך ואם אראך
15 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, mú wá fún mi ohun èlò orin olókùn.” Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Eliṣa.
ועתה קחו לי מנגן והיה כנגן המנגן ותהי עליו יד יהוה
16 Ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ‘Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun.’
ויאמר כה אמר יהוה עשה הנחל הזה גבים גבים
17 Nítorí èyí ni Olúwa wí, o kò ní í rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.
כי כה אמר יהוה לא תראו רוח ולא תראו גשם והנחל ההוא ימלא מים ושתיתם אתם ומקניכם ובהמתכם
18 Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa, yóò sì fi Moabu lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.
ונקל זאת בעיני יהוה ונתן את מואב בידכם
19 Ìwọ yóò sì bi gbogbo ìlú olódi àti gbogbo àgbà ìlú ṣubú. Ìwọ yóò sì gé gbogbo igi dáradára ṣubú, dá gbogbo orísun omi dúró, kí o sì pa gbogbo pápá dáradára pẹ̀lú òkúta run.”
והכיתם כל עיר מבצר וכל עיר מבחור וכל עץ טוב תפילו וכל מעיני מים תסתמו וכל החלקה הטובה תכאבו באבנים
20 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní àsìkò ẹbọ, níbẹ̀ ni omí sàn láti ọ̀kánkán Edomu! Ilé náà sì kún pẹ̀lú omi.
ויהי בבקר כעלות המנחה והנה מים באים מדרך אדום ותמלא הארץ את המים
21 Nísinsin yìí gbogbo ará Moabu gbọ́ pé àwọn ọba tí dé láti bá wọn jà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn, ọmọdé àti àgbà tí ó lè ja ogun wọn pè wọ́n sókè wọ́n sì dúró ní etí ilẹ̀.
וכל מואב שמעו כי עלו המלכים להלחם בם ויצעקו מכל חגר חגרה ומעלה ויעמדו על הגבול
22 Nígbà tí wọ́n dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, oòrùn ti tàn sí orí omi náà sí àwọn ará Moabu ní ìkọjá ọ̀nà, omi náà sì pupa bí ẹ̀jẹ̀.
וישכימו בבקר והשמש זרחה על המים ויראו מואב מנגד את המים אדמים כדם
23 “Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsin yìí sí àwọn ìkógun Moabu!”
ויאמרו דם זה החרב נחרבו המלכים ויכו איש את רעהו ועתה לשלל מואב
24 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Moabu dé sí ibùdó ti Israẹli, àwọn ará Israẹli dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ. Àwọn ará Israẹli gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Moabu run.
ויבאו אל מחנה ישראל ויקמו ישראל ויכו את מואב וינסו מפניהם ויבו (ויכו) בה והכות את מואב
25 Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run. Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára. Kiri-Hareseti nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní ààyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kànnàkànnà yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà.
והערים יהרסו וכל חלקה טובה ישליכו איש אבנו ומלאוה וכל מעין מים יסתמו וכל עץ טוב יפילו עד השאיר אבניה בקיר חרשת ויסבו הקלעים ויכוה
26 Nígbà tí ọba Moabu rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin onídà láti jà pẹ̀lú ọba Edomu, ṣùgbọ́n wọn kò yege.
וירא מלך מואב כי חזק ממנו המלחמה ויקח אותו שבע מאות איש שלף חרב להבקיע אל מלך אדום--ולא יכלו
27 Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú. Wọ́n sì bínú lórí Israẹli púpọ̀púpọ̀; wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn.
ויקח את בנו הבכור אשר ימלך תחתיו ויעלהו עלה על החמה ויהי קצף גדול על ישראל ויסעו מעליו וישבו לארץ

< 2 Kings 3 >