< 2 Kings 16 >

1 Ní ọdún kẹtàdínlógún Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ ọba.
La dix-septième année de Pékach, fils de Remalia, Achaz, fils de Jotham, roi de Juda, commença à régner.
2 Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìndínlógún ní Jerusalẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀.
Achaz avait vingt ans lorsqu'il devint roi, et il régna seize ans à Jérusalem. Il ne fit pas ce qui est droit aux yeux de l'Éternel, son Dieu, comme David, son père.
3 Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
Mais il marcha dans la voie des rois d'Israël et fit même passer son fils par le feu, selon les abominations des nations que l'Éternel avait chassées devant les enfants d'Israël.
4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèké àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
Il offrait des sacrifices et brûlait des parfums sur les hauts lieux, sur les collines et sous tout arbre vert.
5 Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀.
Alors Retsin, roi de Syrie, et Pékah, fils de Remalia, roi d'Israël, montèrent à Jérusalem pour faire la guerre. Ils assiégèrent Achaz, mais ne purent le vaincre.
6 Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
En ce temps-là, Retsin, roi de Syrie, récupéra Élath au profit de la Syrie et chassa les Juifs d'Élath; les Syriens s'installèrent à Élath et y ont vécu jusqu'à ce jour.
7 Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.”
Achaz envoya des messagers à Tiglath Pileser, roi d'Assyrie, en disant: « Je suis ton serviteur et ton fils. Monte et sauve-moi de la main du roi de Syrie et de la main du roi d'Israël, qui s'élèvent contre moi. »
8 Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ.
Achaz prit l'argent et l'or qui se trouvaient dans la maison de l'Éternel et dans les trésors de la maison du roi, et il les envoya en cadeau au roi d'Assyrie.
9 Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.
Le roi d'Assyrie l'écouta; et le roi d'Assyrie monta contre Damas et s'en empara, emmena son peuple captif à Kir, et fit mourir Rezin.
10 Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀.
Le roi Achaz alla à Damas pour rencontrer Tiglath Pileser, roi d'Assyrie, et il vit l'autel qui était à Damas. Le roi Achaz envoya au prêtre Urie un dessin de l'autel et les plans pour le construire.
11 Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku.
Le prêtre Urie construisit l'autel. Selon tout ce que le roi Achaz avait envoyé de Damas, le prêtre Urie le construisit pour l'arrivée du roi Achaz de Damas.
12 Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀.
Lorsque le roi arriva de Damas, il vit l'autel; il s'approcha de l'autel et y fit des offrandes.
13 Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà.
Il brûla son holocauste et son offrande, versa sa libation et fit aspersion sur l'autel du sang de ses sacrifices de prospérité.
14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.
Il fit venir l'autel d'airain qui était devant l'Éternel, de l'avant de la maison, entre son autel et la maison de l'Éternel, et le plaça au nord de son autel.
15 Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn, ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.”
Le roi Achaz donna cet ordre au prêtre Urie: « Sur le grand autel, brûlez l'holocauste du matin, l'offrande du soir, l'holocauste du roi et son offrande, ainsi que l'holocauste de tous les habitants du pays, leur offrande et leurs libations, et répandez-y tout le sang de l'holocauste et tout le sang du sacrifice; mais l'autel d'airain sera pour moi un lieu de consultation. »
16 Báyìí ni Uriah àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ahasi ọba pàṣẹ.
Le prêtre Urie fit ainsi, selon tout ce que le roi Achaz avait ordonné.
17 Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́.
Le roi Achaz coupa les panneaux des socles, enleva la cuvette de dessus, enleva la mer de dessus les bœufs de bronze qui étaient dessous, et la posa sur un pavé de pierre.
18 Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba Asiria.
Il enleva le chemin couvert pour le sabbat qu'on avait construit dans la maison, et l'entrée extérieure du roi dans la maison de Yahvé, à cause du roi d'Assyrie.
19 Àti ìyókù ìṣe Ahasi tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda?
Le reste des actes d'Achaz, qu'il fit, n'est-il pas écrit dans le livre des Chroniques des rois de Juda?
20 Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Achaz se coucha avec ses pères et fut enterré avec ses pères dans la ville de David; et Ézéchias, son fils, régna à sa place.

< 2 Kings 16 >