< 2 Kings 14 >

1 Ní ọdún kejì tí Jehoaṣi ọmọ Joahasi ọba Israẹli, Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba.
El año segundo de Jeoás, hijo de Joacaz, rey de Israel, comenzó a reinar Amasías, hijo de Joás, rey de Judá.
2 Ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani; ó wá láti Jerusalẹmu.
Tenía 25 años cuando comenzó a reinar, y reinó 29 años en Jerusalén. El nombre de su madre fue Joadán, de Jerusalén.
3 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i Dafidi baba a rẹ̀ tí ṣe. Nínú ohun gbogbo, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ baba a rẹ̀ Joaṣi.
Hizo lo recto ante Yavé, aunque no como David, su antepasado. Hizo conforme a todo lo que hizo Joás su padre.
4 Àwọn ibi gíga bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí i kúrò, àwọn ènìyàn sì tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.
Sin embargo, los lugares altos no fueron quitados, porque el pueblo aún sacrificaba y quemaba incienso en los lugares altos.
5 Lẹ́yìn tí ó ti fi ọwọ́ gbá ìjọba rẹ̀ mú gbọingbọin, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n ti pa baba a rẹ̀ ọba.
Sucedió que cuando el reino se afirmó en sus manos, mató a los esclavos que asesinaron a su padre el rey.
6 Síbẹ̀ kò pa ọmọ àwọn apànìyàn náà. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ sínú ìwé òfin Mose níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kì yóò pa baba nítorí àwọn ọmọ, tàbí àwọn ọmọ nítorí àwọn baba; olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
Pero no mató a los hijos de los asesinos, según lo escrito en el Rollo de la Ley de Moisés, donde Yavé mandó: No morirán los padres por los hijos, ni los hijos morirán por los padres, sino que cada cual morirá por su pecado.
7 Òun ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ará Edomu ní àfonífojì iyọ̀, ó sì fi agbára mú Sela nínú ogun, tí ó ń pè é ní Jokteeli, orúkọ tí ó ní títí di òní.
Él mató a 10.000 de Edom en el valle de la Sal. Durante la guerra conquistó Sela y la llamó Jocteel, hasta hoy.
8 Nígbà náà, Amasiah rán àwọn ìránṣẹ́ sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu ọba Israẹli pẹ̀lú ìpèníjà: “Wá, jẹ́ kí á wo ara wa ní ojú.”
Amasías envió mensajeros a Jeoás, hijo de Joacaz, hijo de Jehú, rey de Israel, y le dijo: ¡Ven, veámonos las caras!
9 Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì sí Amasiah ọba Juda: “Òṣùṣú kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí kedari ní Lebanoni, ‘Fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó.’ Nígbà náà ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin tinú igbó ní Lebanoni wá pẹ̀lú ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ òṣùṣú náà mọ́lẹ̀.
Jeoás, rey de Israel, envió a decir a Amasías, rey de Judá: El cardo del Líbano envió a decir al cedro del Líbano: Da tu hija como esposa a mi hijo. Pasó una fiera salvaje del Líbano y pisoteó el cardo.
10 Ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n, nísinsin yìí ìwọ ṣe ìgbéraga. Ògo nínú ìṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n dúró nílé! Kí ni ó dé tí o fi ń wá wàhálà tí o sì fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”
Ciertamente derrotaste a Edom, y tu corazón se enalteció. ¡Ufánate de eso y quédate en tu casa! ¿Por qué provocas una calamidad en la que puedes caer tú y Judá contigo?
11 Bí ó ti wù kí ó rí Amasiah kò ní tẹ́tí, bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi ọba Israẹli sì dojúkọ ọ́. Òun àti Amasiah ọba Juda kọjú sí ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda.
Pero Amasías no escuchó, por lo cual Jeoás, rey de Israel, salió y se vieron las caras, él y Amasías, rey de Judá, en Bet-semes, que es de Judá.
12 A kó ipa ọ̀nà Juda nípasẹ̀ Israẹli, gbogbo àwọn ọkùnrin sì sálọ sí ilé e rẹ̀.
Judá fue derrotado por Israel, y huyeron cada uno a su tienda.
13 Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Jehoaṣi, ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà, Jehoaṣi lọ sí Jerusalẹmu, ó sì lọ wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ìlẹ̀kùn Efraimu sí ibi igun ìlẹ̀kùn. Ìpín kan tí ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ irinwó ìgbọ̀nwọ́.
Jeoás, rey de Israel, capturó a Amasías, rey de Judá, hijo de Joás, hijo de Ocozías, en Bet-semes. Entró en Jerusalén y rompió el muro de Jerusalén desde la puerta de Efraín hasta la puerta de la esquina, 180 metros en total.
14 Ó mú gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun tí ó rí nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti níbi ìfowópamọ́ sí nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn ògo, ó sì dá wọn padà sí Samaria.
Después tomó todo el oro, la plata y todos los utensilios que estaban en la Casa de Yavé y en los tesoros de la casa real. Tomó rehenes y volvió a Samaria.
15 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jehoaṣi, gbogbo ohun tí ó ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí rẹ̀, pẹ̀lú ogun rẹ̀ sí Amasiah ọba Juda, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
El resto de los hechos que realizó Jeoás, su valor y cómo luchó contra Amasías, rey de Judá, ¿no están escritos en el rollo de las Crónicas de los reyes de Israel?
16 Jehoaṣi sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sí Samaria pẹ̀lú àwọn ọba Israẹli. Jeroboamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Jeoás descansó con sus antepasados, y fue sepultado en Samaria con los reyes de Israel. Reinó en su lugar su hijo Jeroboam.
17 Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli.
Amasías, hijo de Joás, rey de Judá, vivió 15 años después de la muerte de Jeoás, hijo de Joacaz, rey de Israel.
18 Fún ti ìyókù iṣẹ́ rẹ̀ nígbà ìjọba Amasiah, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda?
Los demás hechos de Amasías, ¿no están escritos en el rollo de las Crónicas de los reyes de Judá?
19 Wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi, ṣùgbọ́n wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀.
Conspiraron contra él en Jerusalén. Él huyó a Laquis, pero lo persiguieron hasta Laquis, y allí lo mataron.
20 Wọ́n gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin, a sì sin ín sí Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, ní ìlú ńlá ti Dafidi.
Lo llevaron a Jerusalén sobre caballos, y fue sepultado con sus antepasados en la Ciudad de David.
21 Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn Juda mú Asariah tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Wọ́n sì ṣe é ní ọba ní ìrọ́pò baba rẹ̀ Amasiah.
Entonces todo el pueblo de Judá tomó a Azarías, quien tenía 16 años, y lo llevaron a reinar en lugar de su padre Amasías.
22 Òun ni ẹni tí ó tún Elati kọ́, ó sì dá a padà sí Juda lẹ́yìn tí Amasiah ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
Él reedificó Elat y la restituyó a Judá, después que el rey descansó con sus antepasados.
23 Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún tí Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda, Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ọba Israẹli di ọba ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọ̀kànlélógójì ọdún.
El año 15 de Amasías, hijo de Joás, rey de Judá, comenzó a reinar Jeroboam, hijo de Jeoás, rey de Israel, en Samaria, y reinó 41 años.
24 Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati. Èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.
Hizo lo malo ante Yavé, y no se apartó de todos los pecados de Jeroboam, hijo de Nabat, con los cuales estimuló a pecar a Israel.
25 Òun ni ẹni tí ó ti dá àwọn ààlà Israẹli padà láti Lebo-Hamati sí òkú aginjù. Ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ Jona ọmọ Amittai, wòlíì láti Gati-Heferi.
Él restableció la frontera de Israel desde la entrada de Hamat hasta el mar del Arabá, según la Palabra de Yavé, ʼElohim de Israel, que dio por medio de su esclavo Jonás, hijo de Amitay, el profeta de Gat-hefer.
26 Olúwa ti rí ìpọ́njú Israẹli pé, ó korò gidigidi, nítorí kò sí ẹrú tàbí òmìnira tàbí olùrànlọ́wọ́ kan fún Israẹli.
Pues Yavé vio la amarga aflicción de Israel, la cual padecían tanto esclavos como libres, sin que alguien ayudara a Israel.
27 Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Israẹli láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi.
Yavé determinó no borrar el nombre de Israel de debajo del cielo. Por eso los libró por mano de Jeroboam, hijo de Joás.
28 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jeroboamu, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn agbára rẹ, bí ó ti jagun sí, àti bí ó ti gba Damasku àti Hamati, tí í ṣe ti Juda, padà fún Israẹli, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
Todo lo que hizo Jeroboam, su valor con que luchó y cómo recuperó a Damasco y a Hamat (que fueron de Judá) para Israel, ¿no están escritos en el rollo de las Crónicas de los reyes de Israel?
29 Jeroboamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Israẹli Sekariah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Jeroboam descansó con sus antepasados, con los reyes de Israel, y su hijo Zacarías reinó en su lugar.

< 2 Kings 14 >