< 2 Kings 11 >

1 Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run.
茲にアハジアの母アタリヤその子の死たるを見て起て王の種を盡く滅したりしが
2 Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti arábìnrin Ahasiah, mú Joaṣi ọmọ Ahasiah, ó sì jí i lọ kúrò láàrín àwọn ọmọ-aládébìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataliah; bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.
ヨラム王の女にしてアハジアの姉妹なるヱホシバといふ者アハジアの子ヨアシを王の子等の殺さるる者の中より竊みとり彼とその乳母を夜着の室にいれて彼をアタリヤに匿したれば終にころされざりき
3 Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ náà.
ヨアシは彼とともに六年ヱホバの家に隱れてをりアタリヤ國を治めたり
4 Ní ọdún keje, Jehoiada ránṣẹ́ ó sí mú àwọn olórí lórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, pẹ̀lú àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.
第七年にいたりヱホヤダ人を遣して近衛兵の大將等を招きよせヱホバの家にきたりて己に就しめ彼等と契約を結び彼らにヱホバの家にて誓をなさしめて王の子を見し
5 Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún ṣíṣọ́ ààfin ọba.
かれらに命じて言ふ汝等がなすべき事は是なり汝等安息日に入きたる者は三分の一は王の家をまもり
6 Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn huri, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní ṣíṣọ́ ilé tí a kọ́,
三分の一はスル門にをり三分の一は近衛兵の後の門にをるべし斯なんぢら宮殿をまもりて人をいるべからず
7 àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.
また凡て汝等安息日に出ゆく者はその二手ともにヱホバの家において王をまもるべし
8 Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbọdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”
すなはち汝らおのおの武器を手にとりて王を環て立べし凡てその列を侵す者をば殺すべし汝等又王の出る時にも入る時にも王とともにをるべし
9 Olórí àwọn ọ̀rọ̀ọ̀rún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti pa á láṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jehoiada àlùfáà.
是においてその將官等祭司ヱホヤダが凡て命ぜしごとくにおこなへり即ちかれらおのおの其手の人の安息日に入くべき者と安息日に出ゆくべき者とを率て祭司ヱホヤダに至りしかば
10 Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn àpáta tí ó ti jẹ́ ti ọba Dafidi tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
祭司はヱホバの殿にあるダビデ王の槍と楯を大將等にわたせり
11 Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́bàá pẹpẹ àti ilé ìhà gúúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà.
近衛兵はおのおの手に武器をとりて王の四周にをり殿の右の端より左の端におよびて壇と殿にそひて立つ
12 Jehoiada mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”
ヱホヤダすなはち王子を進ませて之に冠冕をいただかせ律法をわたし之を王となして之に膏をそそぎければ人衆手を拍て王長壽かれと言り
13 Nígbà tí Ataliah gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
茲にアタリヤ近衛兵と民の聲を聞きヱホバの殿にいりて民の所にいたり
14 Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn balógun àti àwọn afùnpè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀, wọ́n sì ń fun ìpè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataliah fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”
見るに王は常例のごとくに高座の上に立ち其傍に大將等と喇叭手立をり又國の民みな喜びて喇叭を吹をりしかばアタリヤ其衣を裂て反逆なり反逆なりと叫べり
15 Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.”
時に祭司ヱホヤダ大將等と軍勢の士官等に命じてこれに言ふ彼をして列の間をとほりて出しめよ彼に從がふ者をば劍をもて殺せと前にも祭司は彼をヱホバの家に殺すべからずと言おけり
16 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á.
是をもて彼のために路をひらきければ彼王の家の馬道をとほりゆきしが遂に其處に殺されぬ
17 Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú.
斯てヱホヤダはヱホと王と民の間にその皆ヱホバの民とならんといふ契約を立しめたり亦王と民の間にもこれを立しめたり
18 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ. Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
是をもて國の民みなバアルの家にいりてこれを毀ちその壇とその像を全く打碎きバアルの祭司マツタンをその壇の前に殺せり而して祭司ヱホバの家に監督者を設けたり
19 Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú ààyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.
ヱホヤダすなはち大將等と近衛兵と國の諸の民を率てヱホバの家より王をみちびき下り近衛兵の門の途よりして王の家にいたり王の位に坐せしめたり
20 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, ìlú náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà náà ní ààfin ọba.
斯有しかば國の民はみな喜びて邑は平穩なりきアタリヤは王の家に殺されぬ
21 Joaṣi jẹ́ ọmọ ọdún méje nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.
ヨアシは位に即し時七歳なりき

< 2 Kings 11 >