< 2 Kings 10 >
1 Nísinsin yìí, Ahabu ṣì ní àádọ́rin ọmọkùnrin ní ìdílé rẹ̀ ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni, Jehu kọ lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samaria: sí àwọn oníṣẹ́ Jesreeli, sí àwọn àgbàgbà àti sí àwọn olùtọ́jú àwọn ọmọ Ahabu. Ó wí pé,
亚哈有七十个儿子在撒马利亚。耶户写信送到撒马利亚,通知耶斯列的首领,就是长老和教养亚哈众子的人,说:
2 “Ní kété tí lẹ́tà bá ti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ ọ̀gá rẹ wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ sì ní àwọn kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹṣin, ìlú olódi kan pẹ̀lú ohun ìjà,
“你们那里既有你们主人的众子和车马、器械、坚固城,
3 yan èyí tí ó dára àti èyí tí ó níye jùlọ nínú àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ, kí o sì gbé e lé orí ìtẹ́ baba a rẹ̀. Nígbà náà, kí o sì jà fún ilé ọ̀gá à rẹ.”
接了这信,就可以在你们主人的众子中选择一个贤能合宜的,使他坐他父亲的位,你们也可以为你们主人的家争战。”
4 Ṣùgbọ́n ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wí pé, “Tí ọba méjì kò bá le kojú ìjà sí i, báwo ni a ṣẹ le è ṣe é?”
他们却甚惧怕,彼此说:“二王在他面前尚且站立不住,我们怎能站得住呢?”
5 Bẹ́ẹ̀ ẹni tí ń ṣe olórí ilé, ẹni tí ń ṣe olórí ìlú ńlá, àwọn àgbàgbà àti àwọn olùtọ́jú náà rán iṣẹ́ yìí sí Jehu, pé, “Ìránṣẹ́ rẹ ni àwa jẹ́ pẹ̀lú, àwa yóò ṣe ohunkóhun tí o bá sọ. Àwa kì yóò yan ẹnikẹ́ni gẹ́gẹ́ bí ọba; ìwọ ṣe ohunkóhun tí o rò pé ó dára jù lójú rẹ.”
家宰、邑宰,和长老,并教养众子的人,打发人去见耶户,说:“我们是你的仆人,凡你所吩咐我们的都必遵行,我们不立谁作王,你看怎样好就怎样行。”
6 Nígbà náà ni Jehu kọ lẹ́tà kejì sí wọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jesreeli ní ìwòyí ọ̀la.” Nísinsin yìí, àwọn ọmọ-aládé àádọ́rin ọkùnrin, ń bẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ńlá ìlú náà tí ń tọ́ wọn.
耶户又给他们写信说:“你们若归顺我,听从我的话,明日这时候,要将你们主人众子的首级带到耶斯列来见我。”那时王的儿子七十人都住在教养他们那城中的尊贵人家里。
7 Nígbà tí ìwé náà dé ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ ọba tí gbogbo wọ́n jẹ́ àádọ́rin wọ́n sì pa gbogbo wọn. Wọ́n gbé orí wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jehu ní Jesreeli.
信一到,他们就把王的七十个儿子杀了,将首级装在筐里,送到在耶斯列的耶户那里。
8 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jehu, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ ọba náà wá.” Nígbà náà Jehu pàṣẹ, “Ẹ tò wọ́n ní òkìtì méjì ní àtiwọ ẹnu ibodè ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”
有使者来告诉耶户说:“他们将王众子的首级送来了。”耶户说:“将首级在城门口堆作两堆,搁到明日。”
9 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jehu jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí?
次日早晨,耶户出来,站着对众民说:“你们都是公义的,我背叛我主人,将他杀了;这些人却是谁杀的呢?
10 Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Ahabu tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah.”
由此可知,耶和华指着亚哈家所说的话一句没有落空,因为耶和华借他仆人以利亚所说的话都成就了。”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa gbogbo ẹni tí ó kù Jesreeli ní ilé Ahabu, pẹ̀lúpẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.
凡亚哈家在耶斯列所剩下的人和他的大臣、密友、祭司,耶户尽都杀了,没有留下一个。
12 Jehu jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Samaria. Ní Beti-Ekedi tí àwọn olùṣọ́-àgùntàn.
耶户起身往撒马利亚去。在路上、牧人剪羊毛之处,
13 Jehu pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Ahasiah ọba Juda, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?” Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Ahasiah, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti màmá ayaba.”
遇见犹大王亚哈谢的弟兄,问他们说:“你们是谁?”回答说:“我们是亚哈谢的弟兄,现在下去要问王和太后的众子安。”
14 “Mú wọn láààyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láààyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Beti-Ekedi, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.
耶户吩咐说:“活捉他们!”跟从的人就活捉了他们,将他们杀在剪羊毛之处的坑边,共四十二人,没有留下一个。
15 Nígbà tí a sì jáde níbẹ̀, ó rí Jehonadabu ọmọ Rekabu ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀, ó sì súre fún un, ó sì wí fún pé, “Ọkàn rẹ ha ṣe déédé bí ọkàn mi ti rí sí ọkàn rẹ?” Jehonadabu dáhùn wí pé, “Èmi wà.” Jehu wí pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ ọ̀ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe pẹ̀lú, Jehu sì fà á lọ́wọ́ sókè sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú kẹ̀kẹ́.
耶户从那里前行,恰遇利甲的儿子约拿达来迎接他,耶户问他安,对他说:“你诚心待我像我诚心待你吗?”约拿达回答说:“是。”耶户说:“若是这样,你向我伸手”,他就伸手;耶户拉他上车。
16 Jehu wí pé, “Wá pẹ̀lú mi, kí o sì rí ìtara mi fún Olúwa.” Nígbà náà ó jẹ́ kí ó gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
耶户说:“你和我同去,看我为耶和华怎样热心”;于是请他坐在车上,
17 Nígbà tí Jehu wá sí Samaria, ó pa gbogbo àwọn tí a fi kalẹ̀ ní ìdílé Ahabu; ó pa wọ́n run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ sí Elijah.
到了撒马利亚,就把撒马利亚的亚哈家剩下的人都杀了,直到灭尽,正如耶和华对以利亚所说的。
18 Nígbà náà, Jehu kó gbogbo àwọn ènìyàn jọ, ó sì wí fún wọn pé, “Ahabu sin Baali díẹ̀; ṣùgbọ́n Jehu yóò sìn ín púpọ̀.
耶户招聚众民,对他们说:“亚哈事奉巴力还冷淡,耶户却更热心。
19 Nísinsin yìí, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Baali jọ fún mi, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo àlùfáà rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọ̀kan kí ó kù, nítorí èmí yóò rú ẹbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti wá, kò ní wà láààyè mọ́.” Ṣùgbọ́n Jehu fi ẹ̀tàn ṣe é, kí ó lè pa àwọn òjíṣẹ́ Baali run.
现在我要给巴力献大祭。应当叫巴力的众先知和一切拜巴力的人,并巴力的众祭司,都到我这里来,不可缺少一个;凡不来的必不得活。”耶户这样行,是用诡计要杀尽拜巴力的人。
20 Jehu wí pé, “ẹ pe àpéjọ ní ìwòyí ọ̀la fún Baali.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kéde rẹ.
耶户说:“要为巴力宣告严肃会!”于是宣告了。
21 Nígbà náà, Jehu rán ọ̀rọ̀ káàkiri Israẹli, gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Baali sì wá: kò sí ẹnìkan tí ó dúró lẹ́yìn. Wọ́n kún ilé tí a kọ́ fún òrìṣà títí tí ó fi kún láti ìkangun èkínní títí dé èkejì.
耶户差人走遍以色列地;凡拜巴力的人都来齐了,没有一个不来的。他们进了巴力庙,巴力庙中从前边直到后边都满了人。
22 Jehu sì sọ fún olùṣọ́ pé, “Kí ó mú aṣọ ìgúnwà wá fún gbogbo àwọn òjíṣẹ́ Baali.” Bẹ́ẹ̀ ni ó mú aṣọ ìgúnwà jáde wá fún wọn.
耶户吩咐掌管礼服的人说:“拿出礼服来,给一切拜巴力的人穿。”他就拿出礼服来给了他们。
23 Nígbà náà, Jehu àti Jehonadabu ọmọ Rekabu lọ sí inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali. Jehu sì wí fún àwọn òjíṣẹ́ Baali pé, “Wò ó yíká, kí o sì rí i pé kò sí ìránṣẹ́ Olúwa kankan pẹ̀lú yín níbí—kìkì òjíṣẹ́ Baali.”
耶户和利甲的儿子约拿达进了巴力庙,对拜巴力的人说:“你们察看察看,在你们这里不可有耶和华的仆人,只可容留拜巴力的人。”
24 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọ inú ilé lọ láti lọ rú ẹbọ àti ẹbọ sísun. Nísinsin yìí Jehu ti rán ọgọ́rin ọkùnrin sí ìta pẹ̀lú ìkìlọ̀ yìí: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọkùnrin tí mo ń gbé sí ọwọ́ yín ó sálọ, yóò jẹ́ ẹ̀mí yín fún ẹ̀mí rẹ.”
耶户和约拿达进去,献平安祭和燔祭。 耶户先安派八十人在庙外,吩咐说:“我将这些人交在你们手中,若有一人脱逃,谁放的必叫他偿命!”
25 Ní kété tí Jehu ti parí ṣíṣe ẹbọ sísun, ó pàṣẹ fún àwọn olùṣọ́ àti àwọn ìjòyè: “Wọlé lọ, kí o sì pa wọ́n, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó sálọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gé wọn lulẹ̀ pẹ̀lú idà. Àwọn olùṣọ́ àti ìjòyè ju ara wọn síta, wọ́n sì wọ inú ojúbọ ti ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali.
耶户献完了燔祭,就出来吩咐护卫兵和众军长说:“你们进去杀他们,不容一人出来!”护卫兵和军长就用刀杀他们,将尸首抛出去,便到巴力庙的城去了,
26 Wọ́n gbé òkúta bíbọ náà jáde láti inú ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali, wọ́n sì jó o.
将巴力庙中的柱像都拿出来烧了;
27 Wọ́n fọ́ òkúta bíbọ ti Baali náà túútúú, wọ́n sì ya ilé òrìṣà Baali bolẹ̀. Àwọn ènìyàn sì ń lò ó fún ilé ìgbẹ́ títí di ọjọ́ òní.
毁坏了巴力柱像,拆毁了巴力庙作为厕所,直到今日。
28 Bẹ́ẹ̀ ni Jehu pa sí sin Baali run ní Israẹli.
这样,耶户在以色列中灭了巴力。
29 Bí ó ti wù kí ó rí, Jehu kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá—ti sí sin ẹgbọrọ màlúù wúrà ní Beteli àti Dani.
只是耶户不离开尼八的儿子耶罗波安使以色列人陷在罪里的那罪,就是拜伯特利和但的金牛犊。
30 Olúwa sì sọ fún Jehu pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”
耶和华对耶户说:“因你办好我眼中看为正的事,照我的心意待亚哈家,你的子孙必接续你坐以色列的国位,直到四代。”
31 Síbẹ̀ Jehu kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu èyí tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá.
只是耶户不尽心遵守耶和华—以色列 神的律法,不离开耶罗波安使以色列人陷在罪里的那罪。
32 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Israẹli kù. Hasaeli fi agbára jẹ ọba lórí àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo agbègbè wọn.
在那些日子,耶和华才割裂以色列国,使哈薛攻击以色列的境界,
33 Ìlà-oòrùn ti Jordani ni gbogbo ilẹ̀ ti Gileadi (ẹ̀kún ilẹ̀ ti ará Gadi, Reubeni, àti Manase) láti Aroeri, tí ó wà létí kòtò Arnoni láti ìhà Gileadi sí Baṣani.
乃是约旦河东、基列全地,从靠近亚嫩谷边的亚罗珥起,就是基列和巴珊的迦得人、吕便人、玛拿西人之地。
34 Fún ti òmíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jehu, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
耶户其余的事,凡他所行的和他的勇力都写在以色列诸王记上。
35 Jehu sinmi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Samaria Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
耶户与他列祖同睡,葬在撒马利亚;他儿子约哈斯接续他作王。
36 Àkókò tí Jehu fi jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.
耶户在撒马利亚作以色列王二十八年。