< 2 Kings 1 >
1 Lẹ́yìn ikú Ahabu, Moabu ṣọ̀tẹ̀ sí Israẹli.
亚哈死后,摩押背叛以色列。
2 Nísinsin yìí Ahasiah ti ṣubú láàrín fèrèsé láti òkè yàrá rẹ̀ tí ó wà ní Samaria, ó sì fi ara pa. Ó sì rán oníṣẹ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni, bóyá èmi ó lè rí ìwòsàn ìfarapa yìí.”
亚哈谢在撒马利亚,一日从楼上的栏杆里掉下来,就病了;于是差遣使者说:“你们去问以革伦的神巴力·西卜,我这病能好不能好。”
3 Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa wí fún Elijah ará Tiṣibi pé, “Lọ sókè kí o lọ bá ìránṣẹ́ ọba Samaria kí o sì béèrè lọ́wọ́ wọn, ‘Ṣé nítorí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni ẹ̀yìn fi jáde lọ ṣèwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu òrìṣà Ekroni?’
但耶和华的使者对提斯比人以利亚说:“你起来,去迎着撒马利亚王的使者,对他们说:‘你们去问以革伦神巴力·西卜,岂因以色列中没有 神吗?’
4 Nítorí náà ohun tí Olúwa sọ ní èyí, ‘Ìwọ kò ní kúrò lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé. Dájúdájú ìwọ yóò kú!’” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ.
所以耶和华如此说:‘你必不下你所上的床,必定要死!’”以利亚就去了。
5 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà padà sí ọ̀dọ̀ ọba, ó béèrè ní ọwọ́ wọn pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi tètè padà wá?”
使者回来见王,王问他们说:“你们为什么回来呢?”
6 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin kan wá láti pàdé wa, ó sì wí fún wa pé, ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ ọba tí ó rán an yín kí ẹ sì wí fún un pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli ni o fi ń rán àwọn ènìyàn láti lọ ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni? Nítorí náà ìwọ kò ní fi orí ibùsùn tí ìwọ dùbúlẹ̀ lé sílẹ̀. Láìsí àní àní ìwọ yóò kùú!”’”
使者回答说:“有一个人迎着我们来,对我们说:‘你们回去见差你们来的王,对他说:耶和华如此说,你差人去问以革伦神巴力·西卜,岂因以色列中没有 神吗?所以你必不下所上的床,必定要死。’”
7 Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín?”
王问他们说:“迎着你们来告诉你们这话的,是怎样的人?”
8 Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.” Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.”
回答说:“他身穿毛衣,腰束皮带。”王说:“这必是提斯比人以利亚。”
9 Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Elijah lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’”
于是,王差遣五十夫长,带领五十人去见以利亚,他就上到以利亚那里;以利亚正坐在山顶上。五十夫长对他说:“神人哪,王吩咐你下来!”
10 Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
以利亚回答说:“我若是神人,愿火从天上降下来,烧灭你和你那五十人!”于是有火从天上降下来,烧灭五十夫长和他那五十人。
11 Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Elijah. Balógun náà sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba sọ, ‘Sọ̀kalẹ̀ kánkán!’”
王第二次差遣一个五十夫长,带领五十人去见以利亚。五十夫长对以利亚说:“神人哪,王吩咐你快快下来!”
12 “Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀.
以利亚回答说:“我若是神人,愿火从天上降下来,烧灭你和你那五十人!”于是 神的火从天上降下来,烧灭五十夫长和他那五十人。
13 Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ!
王第三次差遣一个五十夫长,带领五十人去。这五十夫长上去,双膝跪在以利亚面前,哀求他说:“神人哪,愿我的性命和你这五十个仆人的性命在你眼前看为宝贵!
14 Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!”
已经有火从天上降下来,烧灭前两次来的五十夫长和他们各自带的五十人;现在愿我的性命在你眼前看为宝贵!”
15 Angẹli Olúwa sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba.
耶和华的使者对以利亚说:“你同着他下去,不要怕他!”以利亚就起来,同着他下去见王,
16 Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí, ‘Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí?’ Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!”
对王说:“耶和华如此说:‘你差人去问以革伦神巴力·西卜,岂因以色列中没有 神可以求问吗?所以你必不下所上的床,必定要死!’”
17 Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda.
亚哈谢果然死了,正如耶和华借以利亚所说的话。因他没有儿子,他兄弟约兰接续他作王,正在犹大王约沙法的儿子约兰第二年。
18 Àti ní ti gbogbo àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìjọba Ahasiah, àti ohun tí ó ṣe, ṣe a kò ha kọ wọ́n sí inú ìwé ọdọọdún ti àwọn ọba Israẹli?
亚哈谢其余所行的事都写在以色列诸王记上。