< 2 Corinthians 6 >

1 Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán.
As God’s fellow workers, then, we urge you not to receive God’s grace in vain.
2 Nítorí o wí pé, “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ, àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.” Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.
For He says: “In the time of favor I heard you, and in the day of salvation I helped you.” Behold, now is the time of favor; now is the day of salvation!
3 Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀-òdì sí.
We put no obstacle in anyone’s way, so that no one can discredit our ministry.
4 Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,
Rather, as servants of God we commend ourselves in every way: in great endurance; in troubles, hardships, and calamities;
5 nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀.
in beatings, imprisonments, and riots; in labor, sleepless nights, and hunger;
6 Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.
in purity, knowledge, patience, and kindness; in the Holy Spirit and in sincere love;
7 Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì.
in truthful speech and in the power of God; with the weapons of righteousness in the right hand and in the left;
8 Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́,
through glory and dishonor, slander and praise; viewed as imposters, yet genuine;
9 bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,
as unknown, yet well-known; dying, and yet we live on; punished, yet not killed;
10 bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.
sorrowful, yet always rejoicing; poor, yet making many rich; having nothing, and yet possessing everything.
11 Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín.
We have spoken freely to you, Corinthians. Our hearts are open wide.
12 Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́yìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa.
It is not our affection, but yours, that is restrained.
13 Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.
As a fair exchange, I ask you as my children: Open wide your hearts also.
14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn?
Do not be unequally yoked with unbelievers. For what partnership can righteousness have with wickedness? Or what fellowship does light have with darkness?
15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́?
What harmony is there between Christ and Belial? Or what does a believer have in common with an unbeliever?
16 Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé: “Èmi á gbé inú wọn, èmi o sì máa rìn láàrín wọn, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
What agreement can exist between the temple of God and idols? For we are the temple of the living God. As God has said: “I will dwell with them and walk among them, and I will be their God, and they will be My people.”
17 Nítorí náà, “Ẹ jáde kúrò láàrín wọn, kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀, ni Olúwa wí. Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́; Èmi ó sì gbà yín.”
“Therefore come out from among them and be separate, says the Lord. Touch no unclean thing, and I will receive you.”
18 Àti, “Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi, ní Olúwa Olódùmarè wí.”
And: “I will be a Father to you, and you will be My sons and daughters, says the Lord Almighty.”

< 2 Corinthians 6 >