< 2 Corinthians 4 >
1 Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara,
δια τουτο εχοντες την διακονιαν ταυτην καθως ηλεηθημεν ουκ εκκακουμεν
2 ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.
αλλ απειπαμεθα τα κρυπτα της αισχυνης μη περιπατουντες εν πανουργια μηδε δολουντες τον λογον του θεου αλλα τη φανερωσει της αληθειας συνιστωντες εαυτους προς πασαν συνειδησιν ανθρωπων ενωπιον του θεου
3 Ṣùgbọ́n báyìí, bí ìyìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé.
ει δε και εστιν κεκαλυμμενον το ευαγγελιον ημων εν τοις απολλυμενοις εστιν κεκαλυμμενον
4 Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. (aiōn )
εν οις ο θεος του αιωνος τουτου ετυφλωσεν τα νοηματα των απιστων εις το μη αυγασαι αυτοις τον φωτισμον του ευαγγελιου της δοξης του χριστου ος εστιν εικων του θεου (aiōn )
5 Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu.
ου γαρ εαυτους κηρυσσομεν αλλα χριστον ιησουν κυριον εαυτους δε δουλους υμων δια ιησουν
6 Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi.
οτι ο θεος ο ειπων εκ σκοτους φως λαμψαι ος ελαμψεν εν ταις καρδιαις ημων προς φωτισμον της γνωσεως της δοξης του θεου εν προσωπω ιησου χριστου
7 Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.
εχομεν δε τον θησαυρον τουτον εν οστρακινοις σκευεσιν ινα η υπερβολη της δυναμεως η του θεου και μη εξ ημων
8 A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù.
εν παντι θλιβομενοι αλλ ου στενοχωρουμενοι απορουμενοι αλλ ουκ εξαπορουμενοι
9 A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run.
διωκομενοι αλλ ουκ εγκαταλειπομενοι καταβαλλομενοι αλλ ουκ απολλυμενοι
10 Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa.
παντοτε την νεκρωσιν του κυριου ιησου εν τω σωματι περιφεροντες ινα και η ζωη του ιησου εν τω σωματι ημων φανερωθη
11 Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú.
αει γαρ ημεις οι ζωντες εις θανατον παραδιδομεθα δια ιησουν ινα και η ζωη του ιησου φανερωθη εν τη θνητη σαρκι ημων
12 Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín.
ωστε ο μεν θανατος εν ημιν ενεργειται η δε ζωη εν υμιν
13 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ.
εχοντες δε το αυτο πνευμα της πιστεως κατα το γεγραμμενον επιστευσα διο ελαλησα και ημεις πιστευομεν διο και λαλουμεν
14 Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín,
ειδοτες οτι ο εγειρας τον κυριον ιησουν και ημας δια ιησου εγερει και παραστησει συν υμιν
15 Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
τα γαρ παντα δι υμας ινα η χαρις πλεονασασα δια των πλειονων την ευχαριστιαν περισσευση εις την δοξαν του θεου
16 Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, síbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di tuntun lójoojúmọ́.
διο ουκ εκκακουμεν αλλ ει και ο εξω ημων ανθρωπος διαφθειρεται αλλ ο εσωθεν ανακαινουται ημερα και ημερα
17 Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayé tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa. (aiōnios )
το γαρ παραυτικα ελαφρον της θλιψεως ημων καθ υπερβολην εις υπερβολην αιωνιον βαρος δοξης κατεργαζεται ημιν (aiōnios )
18 Níwọ́n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé. (aiōnios )
μη σκοπουντων ημων τα βλεπομενα αλλα τα μη βλεπομενα τα γαρ βλεπομενα προσκαιρα τα δε μη βλεπομενα αιωνια (aiōnios )