< 2 Corinthians 3 >
1 Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe?
2 Ẹ̀yin fúnra yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.
3 Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.
4 Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run,
5 kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà,
6 Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.
7 Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ);
8 yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?
9 Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.
10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.
11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!
12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.
13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ.
14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.
15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkígbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn.
16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.
17 Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà.
18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.