< 2 Chronicles 9 >

1 Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ nípa òkìkí Solomoni, ó sì wá sí Jerusalẹmu láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè tí ó le. Ó dé pẹ̀lú ẹgbẹ́ ńlá kan pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye wúrà, àti òkúta iyebíye, ó wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni ó sì sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ní lọ́kàn rẹ̀.
ומלכת שבא שמעה את שמע שלמה ותבוא לנסות את שלמה בחידות בירושלם בחיל כבד מאד וגמלים נשאים בשמים וזהב לרב ואבן יקרה ותבוא אל שלמה ותדבר עמו את כל אשר היה עם לבבה׃
2 Solomoni sì dá a lóhùn gbogbo ìbéèrè rẹ̀; kò sì sí èyíkéyìí tí kò lè ṣe àlàyé fún.
ויגד לה שלמה את כל דבריה ולא נעלם דבר משלמה אשר לא הגיד לה׃
3 Nígbà tí ayaba Ṣeba rí ọgbọ́n Solomoni àti pẹ̀lú ilé tí ó ti kọ́,
ותרא מלכת שבא את חכמת שלמה והבית אשר בנה׃
4 oúnjẹ tí ó wà lórí tábìlì rẹ̀, àti ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti dídúró àwọn ìránṣẹ́ nínú aṣọ wọn, àti àwọn agbọ́tí nínú aṣọ wọn àti ẹbọ sísun tí ó ṣe ní ilé Olúwa, ó sì dá a lágara fún ìyàlẹ́nu.
ומאכל שלחנו ומושב עבדיו ומעמד משרתיו ומלבושיהם ומשקיו ומלבושיהם ועליתו אשר יעלה בית יהוה ולא היה עוד בה רוח׃
5 Ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn tí mo gbọ́ ní ìlú mi nípa iṣẹ́ rẹ àti ọgbọ́n rẹ, òtítọ́ ni.
ותאמר אל המלך אמת הדבר אשר שמעתי בארצי על דבריך ועל חכמתך׃
6 Ṣùgbọ́n èmi kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́ àyàfi ìgbà tí mó dé ibí tí mo sì ri pẹ̀lú ojú mi. Nítòótọ́, kì í tilẹ̀ ṣe ìdájọ́ ìdajì títóbi ọgbọ́n rẹ ní a sọ fún mi: ìwọ ti tàn kọjá òkìkí tí mo gbọ́.
ולא האמנתי לדבריהם עד אשר באתי ותראינה עיני והנה לא הגד לי חצי מרבית חכמתך יספת על השמועה אשר שמעתי׃
7 Báwo ni inú àwọn ọkùnrin rẹ ìbá ṣe dùn tó! Báwo ní dídùn inú àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí n dúró nígbà gbogbo níwájú rẹ láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ!
אשרי אנשיך ואשרי עבדיך אלה העמדים לפניך תמיד ושמעים את חכמתך׃
8 Ìyìn ló yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ní inú dídùn nínú rẹ tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ láti jẹ ọba fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run rẹ fún Israẹli láti fi ìdí wọn kalẹ̀ láéláé, ó sì ti fi ọ́ ṣe ọba lórí wọn, láti ṣe ìdájọ́ àti òtítọ́.”
יהי יהוה אלהיך ברוך אשר חפץ בך לתתך על כסאו למלך ליהוה אלהיך באהבת אלהיך את ישראל להעמידו לעולם ויתנך עליהם למלך לעשות משפט וצדקה׃
9 Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tí ì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣeba fi fún ọba Solomoni.
ותתן למלך מאה ועשרים ככר זהב ובשמים לרב מאד ואבן יקרה ולא היה כבשם ההוא אשר נתנה מלכת שבא למלך שלמה׃
10 Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.
וגם עבדי חירם ועבדי שלמה אשר הביאו זהב מאופיר הביאו עצי אלגומים ואבן יקרה׃
11 Ọba sì lo igi algumu náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Kò sì ṣí irú rẹ̀ tí a ti rí rí ní ilẹ̀ Juda.
ויעש המלך את עצי האלגומים מסלות לבית יהוה ולבית המלך וכנרות ונבלים לשרים ולא נראו כהם לפנים בארץ יהודה׃
12 Ọba Solomoni fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ohun tí ó béèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.
והמלך שלמה נתן למלכת שבא את כל חפצה אשר שאלה מלבד אשר הביאה אל המלך ותהפך ותלך לארצה היא ועבדיה׃
13 Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ǹtì,
ויהי משקל הזהב אשר בא לשלמה בשנה אחת שש מאות וששים ושש ככרי זהב׃
14 láì tí ì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Solomoni.
לבד מאנשי התרים והסחרים מביאים וכל מלכי ערב ופחות הארץ מביאים זהב וכסף לשלמה׃
15 Ọba Solomoni sì ṣe igba asà wúrà lílù; ẹgbẹ̀ta ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà sí ọ̀kánkán asà.
ויעש המלך שלמה מאתים צנה זהב שחוט שש מאות זהב שחוט יעלה על הצנה האחת׃
16 Ó sì ti ṣe ọ̀ọ́dúnrún kékeré ṣékélì tí a fi òlùlù wúrà, pẹ̀lú ọ̀ọ́dúnrún ṣékélì wúrà nínú àpáta kọ̀ọ̀kan. Ọba sì kó wọn sínú ààfin ti ó wà ní igbó Lebanoni.
ושלש מאות מגנים זהב שחוט שלש מאות זהב יעלה על המגן האחת ויתנם המלך בבית יער הלבנון׃
17 Nígbà náà ọba sì ṣe ìtẹ́ pẹ̀lú eyín erin ńlá kan ó sì fi wúrà tó mọ́ bò ó.
ויעש המלך כסא שן גדול ויצפהו זהב טהור׃
18 Ìtẹ́ náà sì ní àtẹ̀gùn mẹ́fà, àti pẹ̀lú àpótí ìtìsẹ̀ wúrà kan ni a dè mọ́ ọn. Ní ìhà méjèèjì ibi ìjókòó ní ó ní ìgbọ́wọ́lé, pẹ̀lú kìnnìún tí ó dúró lẹ́bàá olúkúlùkù wọn.
ושש מעלות לכסא וכבש בזהב לכסא מאחזים וידות מזה ומזה על מקום השבת ושנים אריות עמדים אצל הידות׃
19 Kìnnìún méjìlá dúró lórí àtẹ̀gùn mẹ́ta, ọ̀kan àti ní ìhà olúkúlùkù àtẹ̀gùn kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti ṣe rí fún ìjọba mìíràn.
ושנים עשר אריות עמדים שם על שש המעלות מזה ומזה לא נעשה כן לכל ממלכה׃
20 Gbogbo ohun èlò mímú ìjọba Solomoni ọba ni ó jẹ́ kìkì wúrà, àti gbogbo ohun èlò ààfin ní igbó Lebanoni ni ó jẹ́ wúrà mímọ́. Kò sì ṣí èyí tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkan kan ní gbogbo ọjọ́ Solomoni.
וכל כלי משקה המלך שלמה זהב וכל כלי בית יער הלבנון זהב סגור אין כסף נחשב בימי שלמה למאומה׃
21 Ọba ní ọkọ̀ tí a fi ń tajà tí àwọn ọkùnrin Hiramu ń bojútó. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ó máa ń padà, ó ń gbé wúrà àti fàdákà àti eyín erin àti ìnàkí.
כי אניות למלך הלכות תרשיש עם עבדי חורם אחת לשלוש שנים תבואנה אניות תרשיש נשאות זהב וכסף שנהבים וקופים ותוכיים׃
22 Ọba Solomoni sì tóbi nínú ọláńlá àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba tí ó kù lórí ilẹ̀ ayé lọ.
ויגדל המלך שלמה מכל מלכי הארץ לעשר וחכמה׃
23 Gbogbo àwọn ọba ayé ń wá ojúrere lọ́dọ̀ Solomoni láti gbọ́n ọgbọ́n tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn rẹ̀.
וכל מלכי הארץ מבקשים את פני שלמה לשמע את חכמתו אשר נתן האלהים בלבו׃
24 Ní ọdọọdún, olúkúlùkù ẹni tí o wá mú ẹ̀bùn ohun èlò wúrà àti fàdákà àti aṣọ ìbora, ìhámọ́ra, àti tùràrí, àti ẹṣin àti ìbáaka wá.
והם מביאים איש מנחתו כלי כסף וכלי זהב ושלמות נשק ובשמים סוסים ופרדים דבר שנה בשנה׃
25 Solomoni sì ní ẹgbàajì ilé fún àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́, àti ẹgbàá mẹ́fà àwọn ẹṣin, tí ó fi pamọ́ nínú ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ nínú Jerusalẹmu.
ויהי לשלמה ארבעת אלפים אריות סוסים ומרכבות ושנים עשר אלף פרשים ויניחם בערי הרכב ועם המלך בירושלם׃
26 Ó sì jẹ ọba lórí gbogbo àwọn ọba láti odò Eufurate títí dé ilé àwọn ará Filistini àti títí ó fi dé agbègbè ti Ejibiti.
ויהי מושל בכל המלכים מן הנהר ועד ארץ פלשתים ועד גבול מצרים׃
27 Ọba sì sọ fàdákà dàbí òkúta ní Jerusalẹmu, àti igi kedari ni ó sì ṣe bí igi sikamore, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
ויתן המלך את הכסף בירושלם כאבנים ואת הארזים נתן כשקמים אשר בשפלה לרב׃
28 A sì mú àwọn ẹṣin Solomoni wa láti ilẹ̀ òkèrè láti Ejibiti àti láti gbogbo ìlú.
ומוציאים סוסים ממצרים לשלמה ומכל הארצות׃
29 Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati?
ושאר דברי שלמה הראשנים והאחרונים הלא הם כתובים על דברי נתן הנביא ועל נבואת אחיה השילוני ובחזות יעדי החזה על ירבעם בן נבט׃
30 Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún
וימלך שלמה בירושלם על כל ישראל ארבעים שנה׃
31 Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
וישכב שלמה עם אבתיו ויקברהו בעיר דויד אביו וימלך רחבעם בנו תחתיו׃

< 2 Chronicles 9 >