< 2 Chronicles 8 >

1 Lẹ́yìn ogún ọdún lásìkò ìgbà tí Solomoni kọ́ ilé Olúwa àti ilé òun fúnra rẹ̀.
It had taken twenty years for Solomon to build the Temple of the Lord and his own palace.
2 Solomoni tún ìlú tí Hiramu ti fi fún un kọ́, ó sì kó àwọn ọmọ Israẹli jọ níbẹ̀ kí wọn kí ó lè máa gbé nínú ibẹ̀.
Solomon rebuilt the towns Hiram had given him, and sent Israelites to live there.
3 Nígbà náà Solomoni lọ sí Hamati-Ṣoba ó sì borí rẹ̀.
Then Solomon attacked Hamath-zobah and captured it.
4 Ó sì tún kọ́ Tadmori ní aginjù àti gbogbo ìlú ìṣúra tí ó ti kọ́ ní Hamati.
He built Tadmor in the wilderness and also built all the storehouse towns in Hamath.
5 Ó sì tún kọ́ òkè Beti-Horoni àti ìsàlẹ̀ Beti-Horoni gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi, pẹ̀lú ògiri àti pẹ̀lú ìlẹ̀kùn àti ọ̀pá ìdábùú.
He rebuilt Upper and Lower Beth-horon, fortified cities with walls and barred gates,
6 Àti gẹ́gẹ́ bí Baalati àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti gbogbo ìlú fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn ẹṣin rẹ̀ ohunkóhun tí ó bá yẹ ní kókó ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo àyíká agbègbè tí ó ń darí.
and also Baalath. He built all the storehouse towns that belonged to him, and all the towns where he kept his chariots and horses. He built everything he wanted to in Jerusalem, Lebanon, and throughout his entire kingdom.
7 Gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kúrò láti ara àwọn ará Hiti, ará Amori, ará Peresi, ará Hifi àti ará Jebusi àwọn ènìyàn wọ̀nyí wọn kì í ṣe àwọn ará Israẹli,
There were some people who remained in the land: the Hittites, Amorites, Perizzites, Hivites, and Jebusites—people who were not Israelites.
8 èyí ni wí pé, àwọn ọmọ wọn tí ó kù sílé ní ilẹ̀ náà, tí àwọn ọmọ Israẹli kò parun àwọn ni Solomoni bu iṣẹ́ ìrú fún títí di òní yìí.
They were the remaining descendants of the peoples that the Israelites had not destroyed. Solomon made them work as forced laborers, as they are to this day.
9 Ṣùgbọ́n Solomoni kò mú ọmọ ọ̀dọ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, wọn jẹ́ ọ̀gágun rẹ̀, olùdarí àwọn oníkẹ̀kẹ́ àti olùdarí kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.
But Solomon did not make any of the Israelites work as slaves. Instead, they were his military men, his officers, and commanders of his chariots and horsemen.
10 Wọ́n sì tún jẹ́ olórí aláṣẹ fún ọba Solomoni, àádọ́ta ó lé nígba àwọn alákòóso lórí àwọn ènìyàn.
They were also King Solomon's chief officers, 250 men who supervised the people.
11 Solomoni gbé ọmọbìnrin Farao sókè láti ìlú Dafidi lọ sí ibi tí ó ti kọ́ fún un, nítorí ó wí pé, “Aya mi kò gbọdọ̀ gbé nínú ilé Dafidi ọba Israẹli nítorí ibi tí àpótí ẹ̀rí Olúwa bá tí wọ̀, ibi mímọ́ ni.”
Solomon moved Pharaoh's daughter from the City of David to the palace he had built for her. For he said, “My wife cannot live in the palace of David king of Israel, because wherever the Ark of the Lord has gone are holy places.”
12 Lórí pẹpẹ Olúwa tí ó ti kọ́ níwájú ìloro náà, Solomoni sì rú ẹbọ sísun sí Olúwa,
Then Solomon presented burnt offerings to the Lord on the altar of the Lord he had built in front of the Temple's porch.
13 nípa ìlànà ojoojúmọ́ fún ẹbọ rírú tí a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mose wá fún ọjọ́ ìsinmi, oṣù tuntun àti lẹ́rìn mẹ́ta lọ́dún, ní àjọ àìwúkàrà, ní àjọ ọ̀sẹ̀ méje àti àjọ àgọ́.
He followed the requirement for daily offerings as Moses had ordered for Sabbaths, new moons, and the three annual festivals—the Festival of Unleavened Bread, the Festival of Weeks, and the Festival of Shelters.
14 Ní pípamọ́ pẹ̀lú ìlànà baba rẹ̀ Dafidi, ó sì yan ipa àwọn àlùfáà fún iṣẹ́ wọn àti àwọn ọmọ Lefi láti jẹ́ adarí láti máa yin àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ àwọn àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìlànà ojoojúmọ́. Ó sì tún yàn àwọn olùṣọ́nà nípa pípín sí olúkúlùkù ẹnu-ọ̀nà, nítorí èyí ni Dafidi ènìyàn Ọlọ́run ti paláṣẹ.
Following the instructions of his father David, he assigned the divisions of the priests for their service, and the Levites in their responsibilities to offer praise, and to help the priests in their daily duties. He also assigned gatekeepers by their divisions at each gate as David, the man of God, had instructed.
15 Wọn kò sì yà kúrò nínú àṣẹ ọba sí àwọn àlùfáà tàbí sí àwọn ọmọ Lefi, nínú ohunkóhun, àti pẹ̀lú ti ìṣúra.
They followed David's instructions exactly regarding the priests, the Levites, and anything to do with the treasuries.
16 Gbogbo iṣẹ́ Solomoni ni a gbé jáde láti ọjọ́ ìfi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀ títí ó fi di ọjọ́ ìparí. Bẹ́ẹ̀ ni ilé Olúwa sì parí.
This is how all Solomon's work was carried out, from the day the foundation was laid for the Lord's Temple until it was finished. So the Lord's Temple was completed.
17 Nígbà náà ni Solomoni lọ sí Esioni-Geberi àti Elati ní Edomu létí òkun.
After this Solomon went to Ezion-geber and to Eloth on the coast of the land of Edom.
18 Hiramu sì fi ọ̀kọ̀ ránṣẹ́ sì i nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó mòye Òkun. Èyí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Solomoni, lọ sí Ofiri wọ́n sì gbé àádọ́ta lé ní irinwó tálẹ́ǹtì wúrà wá, padà èyí tí wọ́n sì mú tọ ọba Solomoni wá.
Hiram sent him ships under the command of his own officers, along with experienced sailors. They went with Solomon's men to Ophir where they loaded 450 talents of gold, which they then brought back to King Solomon.

< 2 Chronicles 8 >