< 2 Chronicles 3 >

1 Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè.
Then Solomon began building the Temple of the Lord in Jerusalem on Mount Moriah, where the Lord appeared to his father David. This was the place that David had provided—the former threshing floor of Ornan the Jebusite.
2 Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.
Solomon began construction on the second day of the second month in his fourth year as king.
3 Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́.
The size of the foundation Solomon laid for the Temple of God was sixty cubits long and twenty cubits wide, (according to the old cubit measurement).
4 Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́. Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà.
The front porch that ran across the width of the Temple was twenty cubits long and twenty cubits high. He covered the inside of the porch with pure gold.
5 Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.
He paneled the main room with cypress overlaid with fine gold, with images of palm trees and chains.
6 Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu.
He decorated the Temple with beautiful gems, and with gold he imported from Parvaim.
7 Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.
He covered the beams, thresholds, walls, and doors of the Temple with gold, and he carved cherubim on the walls.
8 Ó kọ́ Ibi Mímọ́ Jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára.
He made the room of the Most Holy Place to correspond with the width of the Temple—twenty cubits long and twenty cubits wide. He covered the interior with six hundred talents of fine gold.
9 Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.
The weight of the nails was one shekel for every fifty shekels of gold.
10 Ní Ibi Mímọ́ Jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.
He made for the Most Holy Place two wooden cherubim covered with gold.
11 Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.
The wingspan of the cherubim together was twenty cubits. One wing of the first cherub was five cubits long and touched one Temple wall, while its other wing, also five cubits long, and touched the second cherub.
12 Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
In similar fashion, one wing of the second cherub was five cubits long and touched one Temple wall, while its other wing, also five cubits long, and touched the first cherub.
13 Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá náà.
So the wingspan of these cherubim together was twenty cubits. They stood on their feet, facing the main room.
14 Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.
He made the veil of blue, purple, and crimson embroidery on fine linen, with images of cherubim on it.
15 Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.
He made two columns for the front of the Temple, thirty-five cubits, each having a capital five cubits high.
16 Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rùn-ún pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà
He made chains like in the Most Holy Place and he placed them on top of the columns. He also made one hundred ornamental pomegranates and attached them to each chain.
17 Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.
He set up the columns in front of the Temple, one on the south, and one on the north. The column on the south he named Jachin, and the column on the north he named Boaz.

< 2 Chronicles 3 >