< 2 Chronicles 25 >
1 Amasiah jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani, ó wá láti Jerusalẹmu.
Amaziah was twenty-five years old when he became king, and he reigned in Jerusalem twenty-nine years. His mother’s name was Jehoaddan; she was from Jerusalem.
2 Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn.
And he did what was right in the eyes of the LORD, but not wholeheartedly.
3 Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba.
As soon as the kingdom was firmly in his grasp, Amaziah executed the servants who had murdered his father the king.
4 Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn, olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”
Yet he did not put their sons to death, but acted according to what is written in the Law, in the Book of Moses, where the LORD commanded: “Fathers must not be put to death for their children, and children must not be put to death for their fathers; each is to die for his own sin.”
5 Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú.
Then Amaziah gathered the people of Judah and assigned them according to their families to commanders of thousands and of hundreds. And he numbered those twenty years of age or older throughout Judah and Benjamin and found 300,000 chosen men able to serve in the army, bearing the spear and shield.
6 Ó sì yá ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà.
He also hired 100,000 mighty warriors from Israel for a hundred talents of silver.
7 Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “Ọba, àwọn ọ̀wọ́ ogun láti Israẹli kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Israẹli kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Efraimu.
But a man of God came to him and said, “O king, do not let the army of Israel go with you, for the LORD is not with Israel—not with any of the Ephraimites.
8 Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”
Even if you go and fight bravely in battle, God will make you stumble before the enemy, for God has power to help and power to overthrow.”
9 Amasiah sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́ ogun àwọn ọmọ Israẹli ń kọ́?” Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.”
Amaziah asked the man of God, “What should I do about the hundred talents I have given to the army of Israel?” And the man of God replied, “The LORD is able to give you much more than this.”
10 Bẹ́ẹ̀ ni Amasiah, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Efraimu ká. Ó sì rán wọn lọ ilé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Juda, wọ́n sì padà lọ ilé pẹ̀lú ìbínú ńlá.
So Amaziah dismissed the troops who had come to him from Ephraim and sent them home. And they were furious with Judah and returned home in great anger.
11 Nígbà náà, Amasiah ko ogun rẹ jọ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lọ sí àfonífojì iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn ọkùnrin Seiri.
Amaziah, however, summoned his strength and led his troops to the Valley of Salt, where he struck down 10,000 men of Seir,
12 Àwọn ọkùnrin Juda pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá láààyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.
and the army of Judah also captured 10,000 men alive. They took them to the top of a cliff and threw them down so that all were dashed to pieces.
13 Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Amasiah ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Juda láti Samaria sí Beti-Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.
Meanwhile the troops that Amaziah had dismissed from battle raided the cities of Judah, from Samaria to Beth-horon. They struck down 3,000 people and carried off a great deal of plunder.
14 Nígbà tí Amasiah padà láti ibi pípa àwọn ará Edomu, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn Seiri padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rú ẹbọ fún wọn.
When Amaziah returned from the slaughter of the Edomites, he brought back the gods of the Seirites, set them up as his own gods, bowed before them, and burned sacrifices to them.
15 Ìbínú Olúwa ru sí Amasiah, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn tiwọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”
Therefore the anger of the LORD burned against Amaziah, and He sent him a prophet, who said, “Why have you sought this people’s gods, which could not deliver them from your hand?”
16 Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgba ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.”
While he was still speaking, the king asked, “Have we made you the counselor to the king? Stop! Why be struck down?” So the prophet stopped, but he said, “I know that God has determined to destroy you, because you have done this and have not heeded my advice.”
17 Lẹ́yìn tí Amasiah ọba Juda ti béèrè lọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé, “Wá bá mi lójúkojú.”
Then Amaziah king of Judah took counsel and sent word to the king of Israel Jehoash son of Jehoahaz, the son of Jehu. “Come, let us meet face to face,” he said.
18 Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “Koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀.
But Jehoash king of Israel replied to Amaziah king of Judah: “A thistle in Lebanon sent a message to a cedar in Lebanon, saying, ‘Give your daughter to my son in marriage.’ Then a wild beast in Lebanon came along and trampled the thistle.
19 Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”
You have said, ‘Look, I have defeated Edom,’ and your heart has become proud and boastful. Now stay at home. Why should you stir up trouble so that you fall—you and Judah with you?”
20 Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu.
But Amaziah would not listen, for this had come from God in order to deliver them into the hand of Jehoash, because they had sought the gods of Edom.
21 Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda.
So Jehoash king of Israel advanced, and he and Amaziah king of Judah faced each other at Beth-shemesh in Judah.
22 Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.
And Judah was routed before Israel, and every man fled to his own home.
23 Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí irinwó ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.
There at Beth-shemesh, Jehoash king of Israel captured Amaziah king of Judah, the son of Joash, the son of Jehoahaz. Then Jehoash brought him to Jerusalem and broke down the wall of Jerusalem from the Ephraim Gate to the Corner Gate—a section of four hundred cubits.
24 Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria.
He took all the gold and silver and all the articles found in the house of God with Obed-edom and in the treasuries of the royal palace, as well as some hostages. Then he returned to Samaria.
25 Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli.
Amaziah son of Joash king of Judah lived for fifteen years after the death of Jehoash son of Jehoahaz king of Israel.
26 Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Amasiah láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli?
As for the rest of the acts of Amaziah, from beginning to end, are they not written in the Book of the Kings of Judah and Israel?
27 Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀.
From the time that Amaziah turned from following the LORD, a conspiracy was formed against him in Jerusalem, and he fled to Lachish. But men were sent after him to Lachish, and they killed him there.
28 A gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Juda.
They carried him back on horses and buried him with his fathers in the City of Judah.