< 2 Chronicles 23 >

1 Ní ọdún keje, Jehoiada fi agbára rẹ̀ hàn. O dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún kan, Asariah ọmọ Jerohamu, Iṣmaeli ọmọ Jehohanani Asariah ọmọ Obedi, Maaseiah ọmọ Adaiah àti Elisafati ọmọ Sikri.
En el séptimo año, Joiada se fortaleció y tomó en alianza con él a los jefes de centenas: Azarías hijo de Jeroham, Ismael hijo de Johanán, Azarías hijo de Obed, Maasías hijo de Adaías y Elisafat hijo de Zicri.
2 Wọ́n lọ sí gbogbo Juda, wọ́n sì pe àwọn ará Lefi àti àwọn olórí àwọn ìdílé àwọn ará Israẹli láti gbogbo àwọn ìlú jọ. Nígbà tí wọ́n wá sí Jerusalẹmu.
Ellos recorrieron Judá y reunieron a los levitas de todas las ciudades de Judá y a los jefes de familia de Israel, y llegaron a Jerusalén.
3 Gbogbo ìpéjọ náà dá májẹ̀mú pẹ̀lú ọba ní ilé Ọlọ́run. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ọmọkùnrin ọba yóò jẹ ọba, bí Olúwa ti ṣèlérí nípa àwọn ìran Dafidi.
Toda la asamblea hizo un pacto con el rey en la casa de Dios. Joiada les dijo: “He aquí que el hijo del rey debe reinar, como Yahvé ha dicho respecto a los hijos de David.
4 Nísinsin yìí èyí ni ohun tí ó yẹ kí ó ṣe, ìdámẹ́ta àlùfáà yín àti àwọn ará Lefi tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi ni kí ó bojútó àwọn ìlẹ̀kùn.
Esto es lo que debéis hacer: una tercera parte de vosotros, los que entran en sábado, de los sacerdotes y de los levitas, serán guardianes de los umbrales.
5 Ìdámẹ́ta yín níbi ààfin ọba àti ìdámẹ́ta níbi ẹnu odi ìdásílẹ̀ àti gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí ó wà ní àgbàlá ààfin ilé Olúwa.
Una tercera parte estará en la casa del rey, y otra tercera parte en la puerta de la fundación. Todo el pueblo estará en los atrios de la casa de Yahvé.
6 Kò sí ẹnìkan tí ó gbọdọ̀ wọ inú ilé Olúwa yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi tí a rán ní iṣẹ́ ìsìn. Wọ́n lè wọlé nítorí tí a ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ọkùnrin mìíràn ni kí wọn ó sọ ohun tí Olúwa ti yàn fún wọn.
Pero que nadie entre en la casa de Yahvé, sino los sacerdotes y los que ejercen el ministerio de los levitas. Ellos entrarán, porque son santos, pero todo el pueblo seguirá las instrucciones de Yahvé.
7 Àwọn ará Lefi gbọdọ̀ wà ní ìdúró ṣinṣin yí ọba ká. Olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé Olúwa ni kí ẹ pa. Ẹ dúró ti ọba níbikíbi tí ó bá lọ.”
Los levitas rodearán al rey, cada uno con sus armas en la mano. El que entre en la casa, que lo maten. Acompañen al rey cuando entre y cuando salga”.
8 Àwọn ará Lefi àti gbogbo ọkùnrin Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti paláṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀, àwọn tí wọ́n lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n ń kúrò ní ibi iṣẹ́. Nítorí Jehoiada àlùfáà kò ì tí tú ìpín kankan sílẹ̀.
Los levitas y todo Judá hicieron, pues, todo lo que mandó el sacerdote Joiada. Cada uno tomó a sus hombres, los que debían entrar en sábado, con los que debían salir en sábado, pues el sacerdote Joiada no despidió el turno.
9 Jehoiada àlùfáà, sì fi ọ̀kọ̀ àti asà, àti àpáta wọ̀n-ọn-nì, tí ó jẹ́ ti ọba Dafidi tí wọn wà ní ilé Ọlọ́run, fún àwọn balógun ọ̀rọ̀ọ̀rún.
El sacerdote Joiada entregó a los capitanes de centenas las lanzas, las rodelas y los escudos que habían sido del rey David y que estaban en la casa de Dios.
10 Ó sì to gbogbo àwọn ènìyàn ti ọba káàkiri, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, láti apá ọ̀tún ilé náà títí dé apá òsì ilé náà, lẹ́bàá pẹpẹ àti lẹ́bàá ilé náà.
Puso a todo el pueblo, cada uno con su arma en la mano, desde el lado derecho de la casa hasta el lado izquierdo, cerca del altar y de la casa, alrededor del rey.
11 Jehoiada àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mú ọmọkùnrin ọba jáde wá wọ́n sì gbé adé sórí rẹ̀; wọ́n mú ẹ̀dà májẹ̀mú kan fún un. Wọ́n sì kéde rẹ̀ lọ́ba. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, wọ́n sì kígbe pé, “Kí ọba kí ó pẹ́!”
Entonces sacaron al hijo del rey, le pusieron la corona, le dieron la alianza y lo hicieron rey. Joiada y sus hijos lo ungieron, y dijeron: “¡Viva el rey!”.
12 Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.
Cuando Atalía oyó el ruido del pueblo que corría y alababa al rey, entró con la gente en la casa de Yahvé.
13 Ó sì wò, sì kíyèsi, ọba dúró ní ibùdó rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afùnpè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn. Nígbà náà ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”
Entonces ella miró, y he aquí que el rey estaba de pie junto a su columna a la entrada, con los capitanes y los trompetistas junto al rey. Todo el pueblo del país se alegró y tocó las trompetas. Los cantores también tocaban instrumentos musicales y dirigían los cantos de alabanza. Entonces Atalía se rasgó las vestiduras y dijo: “¡Traición! ¡Traición!”
14 Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé, “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé Olúwa.”
El sacerdote Joiada sacó a los capitanes de centenas que estaban al frente del ejército y les dijo: “Sacadla entre las filas, y el que la siga, que lo maten a espada.” Porque el sacerdote dijo: “No la maten en la casa de Yahvé”.
15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ẹṣin ti ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀.
Así que le abrieron paso. Ella se dirigió a la entrada de la puerta de los caballos a la casa del rey; y allí la mataron.
16 Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa.
Joiada hizo un pacto entre él, todo el pueblo y el rey, para que fueran pueblo de Yahvé.
17 Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.
Todo el pueblo fue a la casa de Baal, la derribó, rompió sus altares y sus imágenes en pedazos, y mató a Matán, el sacerdote de Baal, ante los altares.
18 Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ.
Joiada designó a los funcionarios de la casa de Yahvé bajo la mano de los sacerdotes levitas, que David había distribuido en la casa de Yahvé, para que ofrecieran los holocaustos de Yahvé, como está escrito en la ley de Moisés, con alegría y con cantos, tal como lo había ordenado David.
19 Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé.
Puso a los porteros en las puertas de la casa de Yahvé, para que no entrara nadie impuro en nada.
20 Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́.
Tomó a los jefes de centenas, a los nobles, a los gobernantes del pueblo y a toda la gente del país, e hizo bajar al rey de la casa de Yahvé. Entraron por la puerta superior a la casa del rey, y pusieron al rey en el trono del reino.
21 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, ìlú náà sì dákẹ́ rọ́rọ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà.
Entonces todo el pueblo del país se alegró, y la ciudad se tranquilizó. Habían matado a Atalía con la espada.

< 2 Chronicles 23 >