< 2 Chronicles 11 >

1 Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ilé Juda àti Benjamini jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Israẹli jà kí ó lè mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.
ויבא רחבעם ירושלם ויקהל את בית יהודה ובנימן מאה ושמונים אלף בחור עשה מלחמה--להלחם עם ישראל להשיב את הממלכה לרחבעם
2 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé,
ויהי דבר יהוה אל שמעיהו איש האלהים לאמר
3 “Wí fún Rehoboamu ọmọ Solomoni ọba Juda, sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní Juda àti Benjamini,
אמר אל רחבעם בן שלמה מלך יהודה--ואל כל ישראל ביהודה ובנימן לאמר
4 ‘Èyí ní ohun tí Olúwa wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ láti lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jeroboamu.
כה אמר יהוה לא תעלו ולא תלחמו עם אחיכם שובו איש לביתו--כי מאתי נהיה הדבר הזה וישמעו את דברי יהוה וישבו מלכת אל ירבעם
5 Rehoboamu ń gbe ní Jerusalẹmu ó sì kọ́ àwọn ìlú fún olódi ní Juda.
וישב רחבעם בירושלם ויבן ערים למצור ביהודה
6 Bẹtilẹhẹmu, Etamu, Tekoa,
ויבן את בית לחם ואת עיטם ואת תקוע
7 Beti-Suri, Soko, Adullamu,
ואת בית צור ואת שוכו ואת עדלם
8 Gati, Meraṣa Sifi,
ואת גת ואת מרשה ואת זיף
9 Adoraimu, Lakiṣi, Aseka
ואת אדורים ואת לכיש ואת עזקה
10 Sora, Aijaloni, àti Hebroni. Wọ̀nyí ni àwọn ìlú ìdáàbòbò ní Juda àti Benjamini.
ואת צרעה ואת אילון ואת חברון אשר ביהודה ובבנימן ערי מצרות
11 Ó sì mú àwọn ìlú olódi lágbára, ó sì fi àwọn balógun sínú wọn àti àkójọ oúnjẹ, àti òróró àti ọtí wáìnì.
ויחזק את המצורות ויתן בהם נגידים ואצרות מאכל ושמן ויין
12 Àti ní olúkúlùkù ìlú ni ó fi asà àti ọ̀kọ̀ sí, ó sì mú wọn lágbára gidigidi, ó sì ní Juda àti Benjamini lábẹ́ rẹ̀.
ובכל עיר ועיר צנות ורמחים ויחזקם להרבה מאד ויהי לו יהודה ובנימן
13 Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi, láti gbogbo ẹ̀yà wọn jákèjádò Israẹli wà ní ẹ̀bá rẹ̀.
והכהנים והלוים אשר בכל ישראל--התיצבו עליו מכל גבולם
14 Àwọn ará Lefi fi ìgbèríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Juda àti Jerusalẹmu nítorí Jeroboamu àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà Olúwa.
כי עזבו הלוים את מגרשיהם ואחזתם וילכו ליהודה ולירושלם כי הזניחם ירבעם ובניו מכהן ליהוה
15 Ó sì yan àwọn àlùfáà tirẹ̀ fún àwọn ibi gíga wọ̀n-ọn-nì, àti fún àwọn ère òbúkọ, àti fún ẹgbọrọ màlúù tí ó ṣe.
ויעמד לו כהנים לבמות ולשעירים ולעגלים אשר עשה
16 Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Israẹli tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tẹ̀lé àwọn ará Lefi lọ sí Jerusalẹmu láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run baba a wọn.
ואחריהם מכל שבטי ישראל הנתנים את לבבם לבקש את יהוה אלהי ישראל--באו ירושלם לזבוח ליהוה אלהי אבותיהם
17 Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí.
ויחזקו את מלכות יהודה ויאמצו את רחבעם בן שלמה לשנים שלוש כי הלכו בדרך דויד ושלמה--לשנים שלוש
18 Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.
ויקח לו רחבעם אשה--את מחלת בן (בת) ירימות בן דויד אביהיל בת אליאב בן ישי
19 Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jeuṣi, Ṣemariah àti Sahamu.
ותלד לו בנים--את יעוש ואת שמריה ואת זהם
20 Nígbà náà, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, tí ó bí Abijah fún Attai, Sisa àti Ṣelomiti.
ואחריה לקח את מעכה בת אבשלום ותלד לו את אביה ואת עתי ואת זיזא ואת שלמית
21 Rehoboamu fẹ́ràn Maaka ọmọbìnrin Absalomu ju èyíkéyìí nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.
ויאהב רחבעם את מעכה בת אבשלום מכל נשיו ופילגשיו--כי נשים שמונה עשרה נשא ופילגשים ששים ויולד עשרים ושמונה בנים--וששים בנות
22 Rehoboamu yan Abijah ọmọ Maaka láti jẹ́ olóyè ọmọ-aládé láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.
ויעמד לראש רחבעם את אביה בן מעכה לנגיד באחיו--כי להמליכו
23 Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́n díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákèjádò ká àwọn agbègbè Juda àti Benjamini àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá olódi. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì fẹ́ ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.
ויבן ויפרץ מכל בניו לכל ארצות יהודה ובנימן לכל ערי המצרות ויתן להם המזון לרב וישאל המון נשים

< 2 Chronicles 11 >