< 2 Chronicles 10 >

1 Rehoboamu sì lọ sí Ṣekemu nítorí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ti lọ síbẹ̀ láti fi jẹ ọba.
וילך רחבעם שכמה כי שכם באו כל ישראל להמליך אתו
2 Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ẹni ti ó wà ní Ejibiti, níbi tí ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọba Solomoni ó sì padà láti Ejibiti.
ויהי כשמע ירבעם בן נבט והוא במצרים אשר ברח מפני שלמה המלך--וישב ירבעם ממצרים
3 Bẹ́ẹ̀ ni nígbà náà ó sì ránṣẹ́ sí Jeroboamu àti òun àti gbogbo àwọn Israẹli lọ sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu wọ́n sì wí fún pé,
וישלחו ויקראו לו ויבא ירבעם וכל ישראל וידברו אל רחבעם לאמר
4 “Baba rẹ gbé àjàgà tí ó wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ mú un fúyẹ́, iṣẹ́ líle àti àjàgà wúwo tí ó gbé ka orí wa, àwa yóò sì sìn ọ́.”
אביך הקשה את עלנו ועתה הקל מעבודת אביך הקשה ומעלו הכבד אשר נתן עלינו--ונעבדך
5 Rehoboamu sì dáhùn pé, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn náà sì lọ.
ויאמר אלהם עוד שלשת ימים--ושובו אלי וילך העם
6 Nígbà náà ni ọba Rehoboamu fi ọ̀ràn lọ̀ àwọn àgbàgbà tí ó ti ń sin baba rẹ̀ Solomoni nígbà ayé rẹ̀, ó sì bi wọ́n léèrè pe, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe gbà mí ní ìmọ̀ràn láti dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí lóhùn?”
ויועץ המלך רחבעם את הזקנים אשר היו עמדים לפני שלמה אביו בהיתו חי לאמר איך אתם נועצים להשיב לעם הזה דבר
7 Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ìre fún wọn, kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.”
וידברו אליו לאמר אם תהיה לטוב להעם הזה ורציתם ודברת אלהם דברים טובים--והיו לך עבדים כל הימים
8 Ṣùgbọ́n Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn náà tí àwọn àgbàgbà fi fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn ọmọ ọkùnrin tí ó ti dàgbàsókè pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n sì ń dúró níwájú rẹ̀.
ויעזב את עצת הזקנים אשר יעצהו ויועץ את הילדים אשר גדלו אתו העמדים לפניו
9 Ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ìmọ̀ràn yín? Báwo ni kí a ṣe dá àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí wọ́n wí fún mi pé, ‘Mú kí àjàgà tí baba rẹ gbé lé wa kí ó fúyẹ́ díẹ̀.’”
ויאמר אלהם מה אתם נועצים ונשיב דבר את העם הזה אשר דברו אלי לאמר הקל מן העל אשר נתן אביך עלינו
10 Àwọn ọ̀dọ́mọdé tí ó ti dàgbà pẹ̀lú rẹ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí ó wí fún ọ wí pé, ‘Baba rẹ gbé àjàgà wúwo lórí wa, ṣùgbọ́n mú àjàgà wa fúyẹ́,’ wí fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi kékeré, ó nípọn ju ìbàdí baba mi lọ.
וידברו אתו הילדים אשר גדלו אתו לאמר כה תאמר לעם אשר דברו אליך לאמר אביך הכביד את עלנו ואתה הקל מעלינו כה תאמר אלהם קטני עבה ממתני אבי
11 Baba mi gbé àjàgà wúwo ka orí yín; èmi yóò sì tún mú kí ó wúwo sì í. Baba mi fi pàṣán nà yín; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.’”
ועתה אבי העמיס עליכם על כבד ואני אסיף על עלכם אבי יסר אתכם בשוטים ואני בעקרבים
12 Ní ọjọ́ kẹta Jeroboamu àti gbogbo ènìyàn sì padà sí ọ̀dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí ọba ti sọ, “Ẹ padà wá sọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ kẹta.”
ויבא ירבעם וכל העם אל רחבעם ביום השלשי כאשר דבר המלך לאמר שובו אלי ביום השלשי
13 Nígbà náà ni ọba dá wọn lóhùn ní ọ̀nà líle. Rehoboamu ọba sì kọ̀ ìmọ̀ràn àwọn àgbàgbà sílẹ̀,
ויענם המלך קשה ויעזב המלך רחבעם את עצת הזקנים
14 Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; èmi yóò sì mú kí ó wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèe.”
וידבר אלהם כעצת הילדים לאמר אכביד את עלכם ואני אסיף עליו אבי יסר אתכם בשוטים ואני בעקרבים
15 Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì fetísí àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jeroboamu ọmọ Nebati nípasẹ̀ Ahijah ará Ṣilo.
ולא שמע המלך אל העם כי היתה נסבה מעם האלהים--למען הקים יהוה את דברו אשר דבר ביד אחיהו השלוני אל ירבעם בן נבט
16 Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.
וכל ישראל כי לא שמע המלך להם וישיבו העם את המלך לאמר מה לנו חלק בדויד ולא נחלה בבן ישי איש לאהליך ישראל עתה ראה ביתך דויד וילך כל ישראל לאהליו
17 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé ní ìlú Juda, Rehoboamu ń jẹ ọba lórí wọn.
ובני ישראל הישבים בערי יהודה--וימלך עליהם רחבעם
18 Ọba Rehoboamu rán Adoniramu jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Rehoboamu, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jerusalẹmu.
וישלח המלך רחבעם את הדרם אשר על המס וירגמו בו בני ישראל אבן וימת והמלך רחבעם התאמץ לעלות במרכבה לנוס ירושלם
19 Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli sì wà ní ìṣọ̀tẹ̀ lórí ilé Dafidi títí fi di òní yìí.
ויפשעו ישראל בבית דויד עד היום הזה

< 2 Chronicles 10 >