< 1 Thessalonians 1 >
1 Paulu, Sila àti Timotiu, A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalonika, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jesu Kristi: Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi kí ó jẹ́ tiyín.
Paul, Silvanus, and Timothy, To the church of the Thessalonians in God the Father and the Lord Jesus Christ: Grace and peace to you.
2 Gbogbo ìgbà ni a máa ń fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run nítorí yín, a sì ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo pẹ̀lú.
We always thank God for all of you, remembering you in our prayers
3 A ń rántí yin ni àìsimi nígbà gbogbo níwájú Ọlọ́run àti Baba nípa iṣẹ́ ìgbàgbọ́ yín, iṣẹ́ ìfẹ́ yín àti ìdúró ṣinṣin ìrètí yín nínú Jesu Kristi Olúwa wa.
and continually recalling before our God and Father your work of faith, your labor of love, and your enduring hope in our Lord Jesus Christ.
4 Àwa mọ̀ dájúdájú, ẹ̀yin olùfẹ́ wa, wí pé Ọlọ́run ti yàn yín fẹ́ fún ara rẹ̀.
Brothers who are beloved by God, we know that He has chosen you,
5 Nítorí pé, nígbà tí a mú ìyìnrere tọ̀ yín wà, kò rí bí ọ̀rọ̀ lásán tí kò ní ìtumọ̀ sí i yín, bí kò ṣe pẹ̀lú agbára, pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, pẹ̀lú ìdánilójú tó jinlẹ̀. Bí ẹ̀yin ti mọ irú ènìyàn tí àwa jẹ́ láàrín yín nítorí yín.
because our gospel came to you not only in word, but also in power, in the Holy Spirit, and with great conviction—just as you know we lived among you for your sake.
6 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá di aláwòkọ́ṣe wa àti ti Olúwa, ìdí ni pé, ẹ gba ẹ̀rí náà láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ayọ̀ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé, ó mú wàhálà àti ìbànújẹ́ wá fún yín.
And you became imitators of us and of the Lord when you welcomed the message with the joy of the Holy Spirit, in spite of your great suffering.
7 Tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin pàápàá fi di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ tó wà ní agbègbè Makedonia àti Akaia.
As a result, you have become an example to all the believers in Macedonia and Achaia.
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa ti gbilẹ̀ níbi gbogbo láti ọ̀dọ̀ yín láti agbègbè Makedonia àti Akaia lọ, ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run tàn káàkiri. Nítorí náà, a kò ni láti ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ fún wọn nípa rẹ̀.
For not only did the message of the Lord ring out from you to Macedonia and Achaia, but your faith in God has gone out to every place, so that we have no need to say anything more.
9 Ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i ròyìn fún wa bí ẹ ti gbà wá lálejò. Wọ́n ròyìn fún wa pẹ̀lú pé, ẹ ti yípadà kúrò nínú ìbọ̀rìṣà àti wí pé Ọlọ́run alààyè àti òtítọ́ nìkan ṣoṣo ni ẹ ń sìn,
For they themselves report what kind of welcome you gave us, and how you turned to God from idols to serve the living and true God
10 àti láti fi ojú ṣọ́nà fún ìpadàbọ̀ Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run wá, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú, Jesu, ẹni tí ó gbà wá lọ́wọ́ ìbínú tí ń bọ̀.
and to await His Son from heaven, whom He raised from the dead—Jesus our deliverer from the coming wrath.