< 1 Thessalonians 2 >
1 Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán.
αυτοι γαρ οιδατε αδελφοι την εισοδον ημων την προς υμας οτι ου κενη γεγονεν
2 Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle.
αλλα προπαθοντες και υβρισθεντες καθως οιδατε εν φιλιπποις επαρρησιασαμεθα εν τω θεω ημων λαλησαι προς υμας το ευαγγελιον του θεου εν πολλω αγωνι
3 Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè.
η γαρ παρακλησις ημων ουκ εκ πλανης ουδε εξ ακαθαρσιας ουτε εν δολω
4 Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò.
αλλα καθως δεδοκιμασμεθα υπο του θεου πιστευθηναι το ευαγγελιον ουτως λαλουμεν ουχ ως ανθρωποις αρεσκοντες αλλα τω θεω τω δοκιμαζοντι τας καρδιας ημων
5 A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa.
ουτε γαρ ποτε εν λογω κολακειας εγενηθημεν καθως οιδατε ουτε εν προφασει πλεονεξιας θεος μαρτυς
6 A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín.
ουτε ζητουντες εξ ανθρωπων δοξαν ουτε αφ υμων ουτε απο αλλων δυναμενοι εν βαρει ειναι ως χριστου αποστολοι
7 Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀,
αλλ εγενηθημεν ηπιοι εν μεσω υμων ως αν τροφος θαλπη τα εαυτης τεκνα
8 bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìyìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa.
ουτως ομειρομενοι υμων ευδοκουμεν μεταδουναι υμιν ου μονον το ευαγγελιον του θεου αλλα και τας εαυτων ψυχας διοτι αγαπητοι ημιν γεγενησθε
9 Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín.
μνημονευετε γαρ αδελφοι τον κοπον ημων και τον μοχθον νυκτος γαρ και ημερας εργαζομενοι προς το μη επιβαρησαι τινα υμων εκηρυξαμεν εις υμας το ευαγγελιον του θεου
10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
υμεις μαρτυρες και ο θεος ως οσιως και δικαιως και αμεμπτως υμιν τοις πιστευουσιν εγενηθημεν
11 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀
καθαπερ οιδατε ως ενα εκαστον υμων ως πατηρ τεκνα εαυτου παρακαλουντες υμας και παραμυθουμενοι
12 ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.
και μαρτυρομενοι εις το περιπατησαι υμας αξιως του θεου του καλουντος υμας εις την εαυτου βασιλειαν και δοξαν
13 Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
δια τουτο και ημεις ευχαριστουμεν τω θεω αδιαλειπτως οτι παραλαβοντες λογον ακοης παρ ημων του θεου εδεξασθε ου λογον ανθρωπων αλλα καθως εστιν αληθως λογον θεου ος και ενεργειται εν υμιν τοις πιστευουσιν
14 Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù,
υμεις γαρ μιμηται εγενηθητε αδελφοι των εκκλησιων του θεου των ουσων εν τη ιουδαια εν χριστω ιησου οτι τα αυτα επαθετε και υμεις υπο των ιδιων συμφυλετων καθως και αυτοι υπο των ιουδαιων
15 àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn
των και τον κυριον αποκτειναντων ιησουν και τους ιδιους προφητας και ημας εκδιωξαντων και θεω μη αρεσκοντων και πασιν ανθρωποις εναντιων
16 nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.
κωλυοντων ημας τοις εθνεσιν λαλησαι ινα σωθωσιν εις το αναπληρωσαι αυτων τας αμαρτιας παντοτε εφθασεν δε επ αυτους η οργη εις τελος
17 Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín.
ημεις δε αδελφοι απορφανισθεντες αφ υμων προς καιρον ωρας προσωπω ου καρδια περισσοτερως εσπουδασαμεν το προσωπον υμων ιδειν εν πολλη επιθυμια
18 Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà.
διο ηθελησαμεν ελθειν προς υμας εγω μεν παυλος και απαξ και δις και ενεκοψεν ημας ο σατανας
19 Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni?
τις γαρ ημων ελπις η χαρα η στεφανος καυχησεως η ουχι και υμεις εμπροσθεν του κυριου ημων ιησου [ χριστου ] εν τη αυτου παρουσια
20 Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.
υμεις γαρ εστε η δοξα ημων και χαρα