< 1 Samuel 8 >

1 Nígbà tí Samuẹli di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Israẹli.
When Samuel was old, he made his sons judges over Israel.
2 Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Joẹli àti orúkọ èkejì a máa jẹ́ Abijah, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Beerṣeba.
The name of his firstborn was Joel, and the name of his second son was Abijah. They were judges in Beersheba.
3 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.
His sons did not walk in his ways, but chased after dishonest gain. They took bribes and perverted justice.
4 Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama.
Then all the elders of Israel gathered together and came to Samuel at Ramah.
5 Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ, nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”
They said to him, “Look, you are old, and your sons do not walk in your ways. Appoint for us a king to judge us like all the nations.”
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa,” èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa.
But it displeased Samuel when they said, “Give us a king to judge us.” So Samuel prayed to Yahweh.
7 Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé, “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn.
Yahweh said to Samuel, “Obey the voice of the people in everything they say to you; for they have not rejected you, but they have rejected me from being king over them.
8 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ.
They are acting now the same as they did since the day I brought them out of Egypt, forsaking me, and serving other gods, and so they are also doing to you.
9 Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”
Now listen to them; but warn them solemnly and let them know the way the king will rule over them.”
10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀.
So Samuel told all the words of Yahweh to the people who were asking for a king.
11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.
He said, “This will be the practice of the king who will reign over you. He will take your sons and appoint them to his chariots and to be his horsemen, and to run before his chariots.
12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.
He will appoint for himself captains of thousands and captains of fifties. He will make some plow his ground, some reap his harvest, and some make his weapons of war and the equipment for his chariots.
13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà.
He will also take your daughters to be perfumers, cooks, and bakers.
14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
He will take the very best of your fields, your vineyards, and your olive orchards, and give them to his servants.
15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀.
He will take a tenth of your grain and of your vineyards and give to his officers and his servants.
16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀.
He will take your male servants and your female servants and the best of your young men and your donkeys; he will put them all to work for him.
17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀.
He will take the tenth of your flocks, and you will be his slaves.
18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
Then on that day you will cry out because of your king whom you have chosen for yourselves; but Yahweh will not answer you on that day.”
19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa?
But the people refused to listen to Samuel; they said, “No! There must be a king over us
20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
so that we might be like all the other nations, and so that our king may judge us and go out before us and fight our battles.”
21 Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa.
When Samuel heard all the words of the people he repeated them in the ears of Yahweh.
22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.” Nígbà náà, Samuẹli sọ fún àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”
Yahweh said to Samuel, “Obey their voice and cause someone to be king for them.” So Samuel said to the men of Israel, “Every man must go to his own city.”

< 1 Samuel 8 >