< 1 Samuel 31 >

1 Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa.
ופלשתים נלחמים בישראל וינסו אנשי ישראל מפני פלשתים ויפלו חללים בהר הגלבע
2 Àwọn Filistini sì ń lépa Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Filistini sì pa Jonatani àti Abinadabu, àti Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu.
וידבקו פלשתים את שאול ואת בניו ויכו פלשתים את יהונתן ואת אבינדב ואת מלכישוע--בני שאול
3 Ìjà náà sì burú fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà.
ותכבד המלחמה אל שאול וימצאהו המורים אנשים בקשת ויחל מאד מהמורים
4 Saulu sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.” Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Saulu mú idà, ó sì ṣubú lù ú.
ויאמר שאול לנשא כליו שלף חרבך ודקרני בה פן יבואו הערלים האלה ודקרני והתעללו בי ולא אבה נשא כליו כי ירא מאד ויקח שאול את החרב ויפל עליה
5 Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si rí i pé Saulu kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀.
וירא נשא כליו כי מת שאול ויפל גם הוא על חרבו וימת עמו
6 Saulu sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.
וימת שאול ושלשת בניו ונשא כליו גם כל אנשיו ביום ההוא--יחדו
7 Nígbà ti àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó wà lápá kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jordani, rí pé àwọn ọkùnrin Israẹli sá, àti pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fi ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.
ויראו אנשי ישראל אשר בעבר העמק ואשר בעבר הירדן כי נסו אנשי ישראל וכי מתו שאול ובניו ויעזבו את הערים וינסו ויבאו פלשתים וישבו בהן
8 Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filistini dé láti bọ́ nǹkan tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gilboa.
ויהי ממחרת ויבאו פלשתים לפשט את החללים וימצאו את שאול ואת שלשת בניו נפלים בהר הגלבע
9 Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Filistini káàkiri, láti máa sọ ọ́ ní gbangba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrín àwọn ènìyàn.
ויכרתו את ראשו ויפשטו את כליו וישלחו בארץ פלשתים סביב לבשר בית עצביהם--ואת העם
10 Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Aṣtoreti: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Beti-Ṣani.
וישימו את כליו בית עשתרות ואת גויתו תקעו בחומת בית שן
11 Nígbà tí àwọn ará Jabesi Gileadi sì gbọ́ èyí tí àwọn Filistini ṣe sí Saulu.
וישמעו אליו ישבי יביש גלעד את אשר עשו פלשתים לשאול
12 Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Saulu, àti òkú àwọn ọmọ bíbí rẹ̀ kúrò lára odi Beti-Ṣani, wọ́n sì wá sí Jabesi, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.
ויקומו כל איש חיל וילכו כל הלילה ויקחו את גוית שאול ואת גוית בניו מחומת בית שן ויבאו יבשה וישרפו אתם שם
13 Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi tamariski ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ ní ọjọ́ méje.
ויקחו את עצמתיהם ויקברו תחת האשל ביבשה ויצמו שבעת ימים

< 1 Samuel 31 >