< 1 Samuel 19 >
1 Saulu sọ fún Jonatani ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣùgbọ́n Jonatani fẹ́ràn Dafidi púpọ̀
사울이 그아들 요나단과 그 모든 신하에게 다윗을 죽이라 말하였더니 사울의 아들 요나단이 다윗을 심히 기뻐하므로
2 Jonatani sì kìlọ̀ fún Dafidi pé, “Baba mi Saulu wá ọ̀nà láti pa ọ́, kíyèsi ara rẹ di òwúrọ̀ ọ̀la; lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀, kí o sì sá pamọ́ sí ibẹ̀.
그가 다윗에게 고하여 가로되 `내 부친 사울이 너를 죽이기를 꾀하시느니라 그러므로 이제 청하노니 아침에 조심하여 은밀한 곳에 숨어 있으라
3 Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”
내가 나가서 너 있는 들에서 내 부친 곁에 서서 네 일을 내 부친과 말하다가 무엇을 보거든 네게 알게 하리라' 하고
4 Jonatani sọ̀rọ̀ rere nípa Dafidi fún Saulu baba rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Má ṣe jẹ́ kí ọba kí ó ṣe ohun tí kò dára fún Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀; nítorí tí kò ṣẹ̀ ọ́, ohun tí ó sì ṣe pé ọ púpọ̀.
요나단이 그 아비 사울에게 다윗을 포장하여 가로되 `원컨대 왕은 신하 다윗에게 범죄치 마옵소서 그는 왕께 득죄하지 아니하였고 그가 왕께 행한 일은 심히 선함이니이다
5 Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu nígbà tí ó pa Filistini. Olúwa ṣẹ́ ogun ńlá fún gbogbo Israẹli, ìwọ rí i inú rẹ dùn. Ǹjẹ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe dẹ́ṣẹ̀ sí Dafidi aláìṣẹ̀, tí ìwọ yóò fi pa á láìnídìí?”
그가 자기 생명을 아끼지 아니하고 블레셋 사람을 죽였고 여호와께서는 온 이스라엘을 위하여 큰 구원을 이루셨으므로 왕이 이를 보고 기뻐하셨거늘 어찌 무고히 다윗을 죽여 무죄한 피를 흘려 범죄하려 하시나이까?'
6 Saulu fetísí Jonatani, ó sì búra báyìí, “Níwọ́n ìgbà tí Olúwa bá ti ń bẹ láààyè, a kì yóò pa Dafidi.”
사울이 요나단의 말을 듣고 맹세하되 `여호와께서 사시거니와 그가 죽임을 당치 아니하리라'
7 Nítorí náà Jonatani pe Dafidi, ó sì sọ gbogbo àjọsọ wọn fún un. Ó sì mú un wá fún Saulu, Dafidi sì wà lọ́dọ̀ Saulu gẹ́gẹ́ bí i ti tẹ́lẹ̀.
요나단이 다윗을 불러 그 모든 일을 알게 하고 그를 사울에게로 인도하니 그가 사울 앞에 여전히 있으니라
8 Lẹ́ẹ̀kan an sí i ogun tún wá, Dafidi sì jáde lọ, ó sì bá àwọn ara Filistini jà. Ó sì pa wọn pẹ̀lú agbára, wọ́n sì sálọ níwájú u rẹ̀.
전쟁이 다시 있으므로 다윗이 나가서 블레셋 사람들과 싸워 그들을 크게 도륙하매 그들이 그 앞에서 도망하니라
9 Ṣùgbọ́n ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí orí Saulu bí ó ti jókòó ní ilé e rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Bí Dafidi sì ti fọn ohun èlò orin olókùn,
사울이 손에 단창을 가지고 그 집에 앉았을 때에 여호와의 부리신 악신이 사울에게 접하였으므로 다윗이 손으로 수금을 탈 때에
10 Saulu sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dafidi yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Saulu ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dafidi sì fi ara pamọ́ dáradára.
사울이 단창으로 다윗을 벽에 박으려 하였으나 그는 사울의 앞을 피하고 사울의 창은 벽에 박힌지라 다윗이 그 밤에 도피하매
11 Saulu rán ènìyàn sí ilé Dafidi láti ṣọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Mikali, ìyàwó Dafidi kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a yóò pa ọ́.”
사울이 사자들을 다윗의 집에 보내어 그를 지키다가 아침에 그를 죽이게 하려 한지라 다윗의 아내 미갈이 다윗에게 일러 가로되 `당신이 이 밤에 당신의 생명을 구하지 아니하면 내일에는 죽임을 당하리라' 하고
12 Nígbà náà Mikali sì gbé Dafidi sọ̀kalẹ̀ ó sì fi aṣọ bò ó.
미갈이 다윗을 창에서 달아 내리우매 그가 도망하여 피하니라
13 Mikali gbé ère ó sì tẹ́ e lórí ibùsùn, ó sì fi irun ewúrẹ́ sí ibi orí rẹ̀.
미갈이 우상을 취하여 침상에 뉘고 염소털로 엮은 것을 그 머리에 씌우고 의복으로 그것을 덮었더니
14 Nígbà ti Saulu rán ènìyàn láti lọ fi agbára mú Dafidi, Mikali wí pé, “Ó rẹ̀ ẹ́.”
사울이 사자들을 보내어 다윗을 잡으려 하매 미갈이 가로되 `그가 병들었느니라'
15 Nígbà náà ni Saulu rán ọkùnrin náà padà láti lọ wo Dafidi ó sì sọ fún wọn pé, “Mú wa fún mi láti orí ibùsùn rẹ̀ kí èmi kí ó le pa á.”
사울이 또 사자들을 보내어 다윗을 보라 하며 이르되 `그를 침상채 내게로 가져오라 내가 그를 죽이리라'
16 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà wọlé, ère ni ó bá lórí ibùsùn àti irun ewúrẹ́ ní orí ère náà.
사자들이 들어가 본즉 침상에 우상이 있고 염소털로 엮은 것이 그 머리에 있었더라
17 Saulu wí fún Mikali pé, “Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí báyìí tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sálọ tí ó sì bọ́?” Mikali sọ fún un pé, “Ó wí fún mi, ‘Jẹ́ kí èmi ó lọ. Èéṣe tí èmi yóò fi pa ọ́?’”
사울이 미갈에게 이르되 `너는 어찌하여 이처럼 나를 속여 내 대적을 놓아 피하게 하였느냐?' 미갈이 사울에게 대답하되 `그가 내게 이르기를 나를 놓아 가게 하라 어찌하여 나로 너를 죽이게 하겠느냐 하더이다' 하니라
18 Nígbà tí Dafidi ti sálọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama ó sì sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe fún un. Òun àti Samuẹli lọ sí Naioti láti dúró níbẹ̀.
다윗이 도피하여 라마로 가서 사무엘에게로 나아가서 사울이 자기에게 행한 일을 다 고하였고 다윗과 사무엘이 나욧으로 가서 거하였더라
19 Ọ̀rọ̀ sì tọ Saulu wá pé, “Dafidi wà ní Naioti ní Rama,”
혹이 사울에게 고하여 가로되 `다윗이 라마 나욧에 있더이다' 하매
20 Saulu sì rán àwọn ènìyàn láti fi agbára mú Dafidi wá ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọtẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Samuẹli dúró níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá sórí àwọn arákùnrin Saulu àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀.
사울이 다윗을 잡으려 사자들을 보내었더니 그들이 선지자 무리의 예언하는 것과 사무엘이 그들의 수령으로 선 것을 볼 때에 하나님의 신이 사울의 사자들에게 임하매 그들도 예언을 한지라
21 Wọ́n sì sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń sọtẹ́lẹ̀. Saulu tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní sọtẹ́lẹ̀.
혹이 그것을 사울에게 고하매 사울이 다른 사자들을 보내었더니 그들도 예언을 한고로 사울이 세번째 다시 사자들을 보내었더니 그들도 예언을 한지라
22 Nígbẹ̀yìn, òun fúnra rẹ̀ sì lọ sí Rama ó sì dé ibi àmù ńlá kan ní Seku. Ó sì béèrè, “Níbo ni Samuẹli àti Dafidi wà?” Wọ́n wí pé, “Wọ́n wà ní ìrékọjá ní Naioti ní Rama.”
이에 사울도 라마로 가서 세구에 있는 큰 우물에 이르러 물어 가로되 `사무엘과 다윗이 어디 있느냐?' 혹이 가로되 `라마 나욧에 있나이다'
23 Saulu sì lọ sí Naioti ni Rama. Ṣùgbọ́n, Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e lórí ó sì ń lọ lọ́nà, ó sì ń sọtẹ́lẹ̀ títí tí ó fi dé Naioti.
사울이 라마 나욧으로 가니라 하나님의 신이 그에게도 임하시니 그가 라마 나욧에 이르기까지 행하며 예언을 하였으며
24 Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Saulu náà wà lára àwọn wòlíì ni?”
그가 또 그 옷을 벗고 사무엘 앞에서 예언을 하며 종일 종야에 벌거벗은 몸으로 누웠었더라 그러므로 속담에 이르기를 `사울도 선지자 중에 있느냐?' 하니라