< 1 Samuel 12 >

1 Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín.
ויאמר שמואל אל כל ישראל הנה שמעתי בקלכם לכל אשר אמרתם לי ואמליך עליכם מלך׃
2 Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí.
ועתה הנה המלך מתהלך לפניכם ואני זקנתי ושבתי ובני הנם אתכם ואני התהלכתי לפניכם מנערי עד היום הזה׃
3 Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni àmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”
הנני ענו בי נגד יהוה ונגד משיחו את שור מי לקחתי וחמור מי לקחתי ואת מי עשקתי את מי רצותי ומיד מי לקחתי כפר ואעלים עיני בו ואשיב לכם׃
4 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
ויאמרו לא עשקתנו ולא רצותנו ולא לקחת מיד איש מאומה׃
5 Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.” Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
ויאמר אליהם עד יהוה בכם ועד משיחו היום הזה כי לא מצאתם בידי מאומה ויאמר עד׃
6 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti.
ויאמר שמואל אל העם יהוה אשר עשה את משה ואת אהרן ואשר העלה את אבתיכם מארץ מצרים׃
7 Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.
ועתה התיצבו ואשפטה אתכם לפני יהוה את כל צדקות יהוה אשר עשה אתכם ואת אבותיכם׃
8 “Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.
כאשר בא יעקב מצרים ויזעקו אבותיכם אל יהוה וישלח יהוה את משה ואת אהרן ויוציאו את אבתיכם ממצרים וישבום במקום הזה׃
9 “Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà.
וישכחו את יהוה אלהיהם וימכר אתם ביד סיסרא שר צבא חצור וביד פלשתים וביד מלך מואב וילחמו בם׃
10 Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’
ויזעקו אל יהוה ויאמר חטאנו כי עזבנו את יהוה ונעבד את הבעלים ואת העשתרות ועתה הצילנו מיד איבינו ונעבדך׃
11 Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.
וישלח יהוה את ירבעל ואת בדן ואת יפתח ואת שמואל ויצל אתכם מיד איביכם מסביב ותשבו בטח׃
12 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín.
ותראו כי נחש מלך בני עמון בא עליכם ותאמרו לי לא כי מלך ימלך עלינו ויהוה אלהיכם מלככם׃
13 Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín.
ועתה הנה המלך אשר בחרתם אשר שאלתם והנה נתן יהוה עליכם מלך׃
14 Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára
אם תיראו את יהוה ועבדתם אתו ושמעתם בקלו ולא תמרו את פי יהוה והיתם גם אתם וגם המלך אשר מלך עליכם אחר יהוה אלהיכם׃
15 ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.
ואם לא תשמעו בקול יהוה ומריתם את פי יהוה והיתה יד יהוה בכם ובאבתיכם׃
16 “Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín!
גם עתה התיצבו וראו את הדבר הגדול הזה אשר יהוה עשה לעיניכם׃
17 Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”
הלוא קציר חטים היום אקרא אל יהוה ויתן קלות ומטר ודעו וראו כי רעתכם רבה אשר עשיתם בעיני יהוה לשאול לכם מלך׃
18 Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.
ויקרא שמואל אל יהוה ויתן יהוה קלת ומטר ביום ההוא ויירא כל העם מאד את יהוה ואת שמואל׃
19 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”
ויאמרו כל העם אל שמואל התפלל בעד עבדיך אל יהוה אלהיך ואל נמות כי יספנו על כל חטאתינו רעה לשאל לנו מלך׃
20 Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa.
ויאמר שמואל אל העם אל תיראו אתם עשיתם את כל הרעה הזאת אך אל תסורו מאחרי יהוה ועבדתם את יהוה בכל לבבכם׃
21 Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n.
ולא תסורו כי אחרי התהו אשר לא יועילו ולא יצילו כי תהו המה׃
22 Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀.
כי לא יטש יהוה את עמו בעבור שמו הגדול כי הואיל יהוה לעשות אתכם לו לעם׃
23 Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́.
גם אנכי חלילה לי מחטא ליהוה מחדל להתפלל בעדכם והוריתי אתכם בדרך הטובה והישרה׃
24 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín, ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín.
אך יראו את יהוה ועבדתם אתו באמת בכל לבבכם כי ראו את אשר הגדל עמכם׃
25 Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”
ואם הרע תרעו גם אתם גם מלככם תספו׃

< 1 Samuel 12 >