< 1 Peter 3 >

1 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn.
ཧེ ཡོཥིཏཿ, ཡཱུཡམཔི ནིཛསྭཱམིནཱཾ ཝཤྱཱ བྷཝཏ ཏཐཱ སཏི ཡདི ཀེཙིད྄ ཝཱཀྱེ ཝིཤྭཱསིནོ ན སནྟི ཏརྷི
2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín.
ཏེ ཝིནཱཝཱཀྱཾ ཡོཥིཏཱམ྄ ཨཱཙཱརེཎཱརྠཏསྟེཥཱཾ པྲཏྱཀྵེཎ ཡུཥྨཱཀཾ སབྷཡསཏཱིཏྭཱཙཱརེཎཱཀྲཥྚུཾ ཤཀྵྱནྟེ།
3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;
ཨཔརཾ ཀེཤརཙནཡཱ སྭརྞཱལངྐཱརདྷཱརཎོན པརིཙྪདཔརིདྷཱནེན ཝཱ ཡུཥྨཱཀཾ ཝཱཧྱབྷཱུཥཱ ན བྷཝཏུ,
4 ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.
ཀིནྟྭཱིཤྭརསྱ སཱཀྵཱད྄ བཧུམཱུལྱཀྵམཱཤཱནྟིབྷཱཝཱཀྵཡརཏྣེན ཡུཀྟོ གུཔྟ ཨཱནྟརིཀམཱནཝ ཨེཝ།
5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn.
ཡཏཿ པཱུཪྻྭཀཱལེ ཡཱཿ པཝིཏྲསྟྲིཡ ཨཱིཤྭརེ པྲཏྱཱཤཱམཀུཪྻྭན྄ ཏཱ ཨཔི ཏཱདྲྀཤཱིམེཝ བྷཱུཥཱཾ དྷཱརཡནྟྱོ ནིཛསྭཱམིནཱཾ ཝཤྱཱ ཨབྷཝན྄།
6 Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.
ཏཐཻཝ སཱརཱ ཨིབྲཱཧཱིམོ ཝཤྱཱ སཏཱི ཏཾ པཏིམཱཁྱཱཏཝཏཱི ཡཱུཡཉྩ ཡདི སདཱཙཱརིཎྱོ བྷཝཐ ཝྱཱཀུལཏཡཱ ཙ བྷཱིཏཱ ན བྷཝཐ ཏརྷི ཏསྱཱཿ ཀནྱཱ ཨཱདྷྭེ།
7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.
ཧེ པུརུཥཱཿ, ཡཱུཡཾ ཛྙཱནཏོ དུརྦྦལཏརབྷཱཛནཻརིཝ ཡོཥིདྦྷིཿ སཧཝཱསཾ ཀུརུཏ, ཨེཀསྱ ཛཱིཝནཝརསྱ སཧབྷཱགིནཱིབྷྱཏཱབྷྱཿ སམཱདརཾ ཝིཏརཏ ཙ ན ཙེད྄ ཡུཥྨཱཀཾ པྲཱརྠནཱནཱཾ བཱདྷཱ ཛནིཥྱཏེ།
8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
ཝིཤེཥཏོ ཡཱུཡཾ སཪྻྭ ཨེཀམནསཿ པརདུཿཁཻ རྡུཿཁིཏཱ བྷྲཱཏྲྀཔྲམིཎཿ ཀྲྀཔཱཝནྟཿ པྲཱིཏིབྷཱཝཱཤྩ བྷཝཏ།
9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.
ཨནིཥྚསྱ པརིཤོདྷེནཱནིཥྚཾ ནིནྡཱཡཱ ཝཱ པརིཤོདྷེན ནིནྡཱཾ ན ཀུཪྻྭནྟ ཨཱཤིཥཾ དཏྟ ཡཏོ ཡཱུཡམ྄ ཨཱཤིརདྷིཀཱརིཎོ བྷཝིཏུམཱཧཱུཏཱ ཨིཏི ཛཱནཱིཐ།
10 Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
ཨཔརཉྩ, ཛཱིཝནེ པྲཱིཡམཱཎོ ཡཿ སུདིནཱནི དིདྲྀཀྵཏེ། པཱཔཱཏ྄ ཛིཧྭཱཾ མྲྀཥཱཝཱཀྱཱཏ྄ སྭཱདྷརཽ ས ནིཝརྟྟཡེཏ྄།
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
ས ཏྱཛེད྄ དུཥྚཏཱམཱརྒཾ སཏྐྲིཡཱཉྩ སམཱཙརེཏ྄། མྲྀགཡཱཎཤྩ ཤཱནྟིཾ ས ནིཏྱམེཝཱནུདྷཱཝཏུ།
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”
ལོཙནེ པརམེཤསྱོནྨཱིལིཏེ དྷཱརྨྨིཀཱན྄ པྲཏི། པྲཱརྠནཱཡཱཿ ཀྲྀཏེ ཏེཥཱཿ ཏཙྪྲོཏྲེ སུགམེ སདཱ། ཀྲོདྷཱསྱཉྩ པརེཤསྱ ཀདཱཙཱརིཥུ ཝརྟྟཏེ།
13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere?
ཨཔརཾ ཡདི ཡཱུཡམ྄ ཨུཏྟམསྱཱནུགཱམིནོ བྷཝཐ ཏརྷི ཀོ ཡུཥྨཱན྄ ཧིཾསིཥྱཏེ?
14 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.”
ཡདི ཙ དྷརྨྨཱརྠཾ ཀླིཤྱདྷྭཾ ཏརྷི དྷནྱཱ བྷཝིཥྱཐ། ཏེཥཱམ྄ ཨཱཤངྐཡཱ ཡཱུཡཾ ན བིབྷཱིཏ ན ཝིངྐྟ ཝཱ།
15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.
མནོབྷིཿ ཀིནྟུ མནྱདྷྭཾ པཝིཏྲཾ པྲབྷུམཱིཤྭརཾ། ཨཔརཉྩ ཡུཥྨཱཀམ྄ ཨཱནྟརིཀཔྲཏྱཱཤཱཡཱསྟཏྟྭཾ ཡཿ ཀཤྩིཏ྄ པྲྀཙྪཏི ཏསྨཻ ཤཱནྟིབྷཱིཏིབྷྱཱམ྄ ཨུཏྟརཾ དཱཏུཾ སདཱ སུསཛྫཱ བྷཝཏ།
16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi.
ཡེ ཙ ཁྲཱིཥྚདྷརྨྨེ ཡུཥྨཱཀཾ སདཱཙཱརཾ དཱུཥཡནྟི ཏེ དུཥྐརྨྨཀཱརིཎཱམིཝ ཡུཥྨཱཀམ྄ ཨཔཝཱདེན ཡཏ྄ ལཛྫིཏཱ བྷཝེཡུསྟདརྠཾ ཡུཥྨཱཀམ྄ ཨུཏྟམཿ སཾཝེདོ བྷཝཏུ།
17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.
ཨཱིཤྭརསྱཱབྷིམཏཱད྄ ཡདི ཡུཥྨཱབྷིཿ ཀླེཤཿ སོཌྷཝྱསྟརྷི སདཱཙཱརིབྷིཿ ཀླེཤསཧནཾ ཝརཾ ན ཙ ཀདཱཙཱརིབྷིཿ།
18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.
ཡསྨཱད྄ ཨཱིཤྭརསྱ སནྣིདྷིམ྄ ཨསྨཱན྄ ཨཱནེཏུམ྄ ཨདྷཱརྨྨིཀཱཎཱཾ ཝིནིམཡེན དྷཱརྨྨིཀཿ ཁྲཱིཥྚོ ྅པྱེཀཀྲྀཏྭཿ པཱཔཱནཱཾ དཎྜཾ བྷུཀྟཝཱན྄, ས ཙ ཤརཱིརསམྦནྡྷེ མཱརིཏཿ ཀིནྟྭཱཏྨནཿ སམྦནྡྷེ པུན རྫཱིཝིཏོ ྅བྷཝཏ྄།
19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú,
ཏཏྶམྦནྡྷེ ཙ ས ཡཱཏྲཱཾ ཝིདྷཱཡ ཀཱརཱབདྡྷཱནཱམ྄ ཨཱཏྨནཱཾ སམཱིཔེ ཝཱཀྱཾ གྷོཥིཏཝཱན྄།
20 àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ.
པུརཱ ནོཧསྱ སམཡེ ཡཱཝཏ྄ པོཏོ ནིརམཱིཡཏ ཏཱཝད྄ ཨཱིཤྭརསྱ དཱིརྒྷསཧིཥྞུཏཱ ཡདཱ ཝྱལམྦཏ ཏདཱ ཏེ྅ནཱཛྙཱགྲཱཧིཎོ྅བྷཝན྄། ཏེན པོཏོནཱལྤེ྅རྠཱད྄ ཨཥྚཱཝེཝ པྲཱཎིནསྟོཡམ྄ ཨུཏྟཱིརྞཱཿ།
21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi.
ཏནྣིདརྴནཉྩཱཝགཱཧནཾ (ཨརྠཏཿ ཤཱརཱིརིཀམལིནཏཱཡཱ ཡསྟྱཱགཿ ས ནཧི ཀིནྟྭཱིཤྭརཱཡོཏྟམསཾཝེདསྱ ཡཱ པྲཏཛྙཱ སཻཝ) ཡཱིཤུཁྲཱིཥྚསྱ པུནརུཏྠཱནེནེདཱནཱིམ྄ ཨསྨཱན྄ ཨུཏྟཱརཡཏི,
22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
ཡཏཿ ས སྭརྒཾ གཏྭེཤྭརསྱ དཀྵིཎེ ཝིདྱཏེ སྭརྒཱིཡདཱུཏཱཿ ཤཱསཀཱ བལཱནི ཙ ཏསྱ ཝཤཱིབྷཱུཏཱ ཨབྷཝན྄།

< 1 Peter 3 >