< 1 Kings 5 >
1 Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo.
Now when Hiram king of Tyre heard that Solomon had been anointed king in his father’s place, he sent envoys to Solomon; for Hiram had always been a friend of David.
2 Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé,
And Solomon relayed this message to Hiram:
3 “Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.
“As you are well aware, due to the wars waged on all sides against my father David, he could not build a house for the Name of the LORD his God until the LORD had put his enemies under his feet.
4 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe.
But now the LORD my God has given me rest on every side, and there is no adversary or crisis.
5 Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’
So behold, I plan to build a house for the Name of the LORD my God, according to what the LORD said to my father David: ‘I will put your son on your throne in your place, and he will build the house for My Name.’
6 “Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi kedari Lebanoni fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Sidoni.”
Now therefore, order that cedars of Lebanon be cut down for me. My servants will be with your servants, and I will pay your servants whatever wages you set, for you know that there are none among us as skilled in logging as the Sidonians.”
7 Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”
When Hiram received Solomon’s message, he rejoiced greatly and said, “Blessed be the LORD this day! He has given David a wise son over this great people!”
8 Hiramu sì ránṣẹ́ sí Solomoni pé, “Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi kedari àti ní ti igi firi.
Then Hiram sent a reply to Solomon, saying: “I have received your message; I will do all you desire regarding the cedar and cypress timber.
9 Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun Ńlá títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”
My servants will haul the logs from Lebanon to the Sea, and I will float them as rafts by sea to the place you specify. There I will separate the logs, and you can take them away. And in exchange, you can meet my needs by providing my household with food.”
10 Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un,
So Hiram provided Solomon with all the cedar and cypress timber he wanted,
11 Solomoni sì fún Hiramu ní ogún ẹgbẹ̀rún òsùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún òsùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún.
and year after year Solomon would provide Hiram with 20,000 cors of wheat as food for his household, as well as 20,000 baths of pure olive oil.
12 Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.
And the LORD gave Solomon wisdom, as He had promised him. There was peace between Hiram and Solomon, and the two of them made a treaty.
13 Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn.
Then King Solomon conscripted a labor force of 30,000 men from all Israel.
14 Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà.
He sent them to Lebanon in monthly shifts of 10,000 men, so that they would spend one month in Lebanon and two months at home. And Adoniram was in charge of the forced labor.
15 Solomoni sì ní ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè,
Solomon had 70,000 porters and 80,000 stonecutters in the mountains,
16 àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà.
not including his 3,300 foremen who supervised the workers.
17 Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀.
And the king commanded them to quarry large, costly stones to lay the foundation of the temple with dressed stones.
18 Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.
So Solomon’s and Hiram’s builders, along with the Gebalites, quarried the stone and prepared the timber and stone for the construction of the temple.