< 1 Kings 4 >
1 Solomoni ọba sì jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli.
King Solomon was king over all Israel.
2 Àwọn wọ̀nyí sì ni ìjòyè rẹ̀: Asariah ọmọ Sadoku àlùfáà:
These were his officials: Azariah son of Zadok was the priest.
3 Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú;
Elihoreph and Ahijah sons of Shisha, were secretaries. Jehoshaphat son of Ahilud was the recorder.
4 Benaiah ọmọ Jehoiada ni olórí ogun; Sadoku àti Abiatari ni àwọn àlùfáà;
Benaiah son of Jehoiada was over the army. Zadok and Abiathar were priests.
5 Asariah ọmọ Natani ni olórí àwọn agbègbè; Sabudu ọmọ Natani, àlùfáà àti olùgba ọba ní ìmọ̀ràn;
Azariah son of Nathan was over the officers. Zabud son of Nathan was a priest and the king's friend.
6 Ahiṣari ni olùtọ́jú ààfin; Adoniramu ọmọ Abida ni ó ń ṣe olórí iṣẹ́-ìlú.
Ahishar was over the household. Adoniram son of Abda was over the men who were subjected to forced labor.
7 Solomoni sì tún ní ìjòyè méjìlá lórí gbogbo agbègbè Israẹli, tí wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Olúkúlùkù ní láti pèsè fún oṣù kan ní ọdún.
Solomon had twelve officers over all Israel, who provided food for the king and his household. Each man had to make provision for one month in the year.
8 Orúkọ wọn ni wọ̀nyí: Bene-Huri ní ìlú olókè Efraimu.
These were their names: Ben-Hur, in the hill country of Ephraim;
9 Bene-Dekeri ní Makasi, Ṣaalbimu, Beti-Ṣemeṣi, àti Eloni Beti-Hanani;
Ben-Deker in Makaz, Shaalbim, Beth Shemesh, and Elon Beth Hanan;
10 Bene-Hesedi, ní Aruboti (tirẹ̀ ni Soko àti gbogbo ilẹ̀ Heferi ń ṣe);
Ben-Hesed, in Arubboth (to him belonged Sokoh and all the land of Hepher);
11 Bene-Abinadabu, ní Napoti (Dori; òun ni ó fẹ́ Tafati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).
Ben-Abinadab, in all Naphoth Dor (he had Taphath the daughter of Solomon as his wife);
12 Baana ọmọ Ahiludi, ní Taanaki àti Megido, àti ní gbogbo Beti-Ṣeani tí ń bẹ níhà Saretani ní ìsàlẹ̀ Jesreeli, láti Beti-Ṣeani dé Abeli-Mehola títí dé ibi tí ń bẹ ní ìkọjá Jokimeamu.
Baana son of Ahilud, in Taanach and Megiddo, and all Beth Shan that is beside Zarethan below Jezreel, from Beth Shan to Abel Meholah as far as the other side of Jokmeam;
13 Ọmọ Geberi ní Ramoti Gileadi (tirẹ̀ ni àwọn ìletò Jairi ọmọ Manase tí ń bẹ ní Gileadi, tirẹ̀ sì ni agbègbè Argobu, tí ń bẹ ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú tí ó tóbi pẹ̀lú odi tí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ irin).
Ben-Geber, in Ramoth Gilead (to him belonged the towns of Jair son of Manasseh, that are in Gilead, and the region of Argob belonged to him, which is in Bashan, sixty great cities with walls and bronze gate bars);
14 Ahinadabu ọmọ Iddo ní Mahanaimu
Ahinadab son of Iddo, in Mahanaim;
15 Ahimasi ní Naftali (ó fẹ́ Basemati ọmọbìnrin Solomoni ní aya).
Ahimaaz, in Naphtali (he also married Basemath the daughter of Solomon as his wife);
16 Baana ọmọ Huṣai ní Aṣeri àti ní Aloti;
Baana son of Hushai, in Asher and Bealoth;
17 Jehoṣafati ọmọ Parua ni ó wà ní Isakari;
Jehoshaphat son of Paruah, in Issachar;
18 Ṣimei ọmọ Ela ni Benjamini;
Shimei son of Ela, in Benjamin;
19 Geberi ọmọ Uri ní Gileadi (orílẹ̀-èdè Sihoni ọba àwọn ará Amori àti orílẹ̀-èdè Ogu ọba Baṣani). Òun nìkan ni ìjòyè lórí ilẹ̀ náà.
and Geber son of Uri, in the land of Gilead, the country of Sihon king of the Amorites and of Og king of Bashan, and he was the only official who was in the land.
20 Àwọn ènìyàn Juda àti ti Israẹli pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí Òkun; wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń yọ ayọ̀.
Judah and Israel were as numerous as the sand by the sea. They were eating and drinking and were happy.
21 Solomoni sì ń ṣàkóso lórí gbogbo àwọn ìjọba láti odò Eufurate títí dé ilẹ̀ àwọn ará Filistini, àti títí dé etí ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń mú owó òde wá, wọ́n sì ń sin Solomoni ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
Solomon ruled over all the kingdoms from the River to the land of the Philistines and to the border of Egypt. They brought tribute and served Solomon all the days of his life.
22 Oúnjẹ Solomoni fún ọjọ́ kan jásí ọgbọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta òsùwọ̀n ìyẹ̀fun,
Solomon's provision for one day was thirty cors of fine flour and sixty cors of meal,
23 Màlúù mẹ́wàá tí ó sanra, àti ogún màlúù láti inú pápá wá, àti ọgọ́rùn-ún àgùntàn àti ewúrẹ́, láìka àgbọ̀nrín àti èsúró, àti ogbúgbu, àti ẹyẹ tí ó sanra.
ten fat oxen, twenty oxen out of the pastures, and one hundred sheep, besides deer, gazelles, roebucks, and fattened fowl.
24 Nítorí òun ni ó ṣàkóso lórí gbogbo agbègbè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn odò Eufurate, láti Tifisa títí dé Gasa, lórí gbogbo àwọn ọba ní ìhà ìhín odò, ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo ìlú tí ó yí i káàkiri.
For he had dominion over all the region on this side of the River, from Tiphsah as far as to Gaza, over all the kings on this side the River, and he had peace on all sides around him.
25 Nígbà ayé Solomoni, Juda àti Israẹli, láti Dani títí dé Beerṣeba, wọ́n ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀.
Judah and Israel lived in safety, every man under his vine and under his fig tree, from Dan to Beersheba, all the days of Solomon.
26 Solomoni sì ní ẹgbàajì ilé ẹṣin fún kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ẹgbàá mẹ́fà ẹlẹ́ṣin.
Solomon had forty thousand stalls of horses for his chariots, and twelve thousand horsemen.
27 Àwọn ìjòyè agbègbè, olúkúlùkù ní oṣù rẹ̀, ń pèsè oúnjẹ fún Solomoni ọba àti gbogbo àwọn tí ń wá sí ibi tábìlì ọba, wọ́n sì rí i pé ohun kankan kò ṣẹ́kù.
Those officials provided food for King Solomon and for all who came to King Solomon's table, every man in his month. They let nothing be lacking.
28 Wọ́n tún máa ń mú ọkà barle àti koríko fún ẹṣin àti fún ẹṣin sísáré wá pẹ̀lú sí ibi tí ó yẹ, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí ìlànà tirẹ̀.
They also brought to the proper place barley and straw for the chariot horses and riding horses, each one bringing in what he was able.
29 Ọlọ́run sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, àti òye ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, àti ìmọ̀ gbígbòòrò òye tí a kò le è fiwé iyanrìn tí ó wà létí Òkun.
God gave Solomon great wisdom and understanding, and wideness of understanding like the sand on the seashore.
30 Ọgbọ́n Solomoni sì pọ̀ ju ọgbọ́n ọkùnrin ìlà-oòrùn lọ, ó sì pọ̀ ju gbogbo ọgbọ́n Ejibiti lọ.
Solomon's wisdom exceeded the wisdom of all the people of the east and all the wisdom of Egypt.
31 Ó sì ní òye ju gbogbo ènìyàn lọ, ju Etani, ará Esra, àti Hemani àti Kalkoli, àti Darda àwọn ọmọ Maholi lọ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè yíká.
He was wiser than all men—than Ethan the Ezrahite, Heman, Kalkol, and Darda, the sons of Mahol—and his fame reached all the surrounding nations.
32 Ó sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta òwe, àwọn orin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé márùn-ún.
He spoke three thousand proverbs and his songs were one thousand and five in number.
33 Ó sì sọ̀rọ̀ ti igi, láti kedari tí ń bẹ ní Lebanoni dé Hísópù tí ń dàgbà lára ògiri. Ó sì tún sọ ti àwọn ẹranko àti ti àwọn ẹyẹ, àti ohun tí ń rákò àti ti ẹja.
He described the plants, from the cedar that is in Lebanon to the hyssop that grows out of the wall. He explained also about beasts, birds, creeping things, and fish.
34 Àwọn ènìyàn sì ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọba ayé láti wá gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.
People came from all the nations to hear the wisdom of Solomon. They came from all kings of the earth who had heard of his wisdom.