< 1 Kings 17 >

1 Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”
And Elijah the Tishbite, from the inhabitants of Gilead, said to Ahab, “As the Lord lives, the God of Israel, in whose sight I stand, there shall not be dew or rain during these years, except by the words of my mouth.”
2 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Elijah wá pé,
And the word of the Lord came to him, saying:
3 “Kúrò níhìn-ín, kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani.
“Withdraw from here, and go toward the east, and hide at the torrent Cherith, which is opposite the Jordan.
4 Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.”
And there you shall drink from the torrent. And I have instructed the ravens to feed you there.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀.
Therefore, he went and acted in accord with the word of the Lord. And going away, he settled by the torrent Cherith, which is opposite the Jordan.
6 Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.
And the ravens carried bread and flesh to him in the morning, and likewise bread and flesh in the evening. And he drank from the torrent.
7 Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà.
But after some days, the torrent dried up. For it had not rained upon the earth.
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé,
Then the word of the Lord came to him, saying:
9 “Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.”
“Rise up, and go to Zarephath of the Sidonians, and dwell there. For I have instructed a widowed woman there to feed you.”
10 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”
He rose up and went away to Zarephath. And when he had arrived at the gate of the city, he saw the widowed woman collecting wood, and he called to her. And he said to her, “Give me a little water in a vessel, so that I may drink.”
11 Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”
And as she was going to bring it, he called out after her, saying, “Bring me also, I beg you, a morsel of bread in your hand.”
12 Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà, bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”
And she responded: “As the Lord your God lives, I have no bread, except a handful of flour in a jar, and a little oil in a bottle. See, I am collecting a couple of sticks, so that I may go in and make it for myself and my son, so that we may eat it and die.”
13 Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.
And Elijah said to her: “Do not be afraid. But go and do as you have said. Yet truly, first make for me, from the same flour, a little bread baked under ashes, and bring it to me. Then afterward, make some for yourself and for your son.
14 Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’”
For thus says the Lord, the God of Israel: ‘The jar of flour will not fail, nor the bottle of oil be diminished, until the day when the Lord will grant rain upon the face of the earth.’”
15 Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́.
She went and acted in accord with the word of Elijah. And he ate, and she and her household ate. And from that day,
16 Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Elijah sọ.
the jar of flour did not fail, and the bottle of oil was not diminished, in accord with the word of the Lord, which he had spoken by the hand of Elijah.
17 Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣe àìsàn, àìsàn náà sì le tó bẹ́ẹ̀, tí ó fi kú.
Now it happened that, after these things, the son of the woman who was the mother of the family became ill. And the sickness was very powerful, so that no breath remained in him.
18 Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Kí lo ní sí mi, ènìyàn Ọlọ́run? Ìwọ ha tọ̀ mí wá láti mú ẹ̀ṣẹ̀ mi wá sí ìrántí, àti láti pa mí ní ọmọ?”
Therefore, she said to Elijah: “What is there between you and me, O man of God? Have you entered to me, so that my iniquities would be remembered, and so that you would put to death my son?”
19 Elijah sì wí fún un pé, “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Ó sì yọ ọ́ jáde ní àyà rẹ̀, ó sì gbé e lọ sí iyàrá òkè ilé níbi tí òun ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn tirẹ̀.
And Elijah said to her, “Give your son to me.” And he took him from her bosom, and he carried him to an upper room, where he himself was staying. And he placed him on his own bed.
20 Nígbà náà ni ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ ha mú ibi wá bá opó náà pẹ̀lú lọ́dọ̀ ẹni tí èmi ń ṣe àtìpó, nípa pípa ọmọ rẹ̀?”
And he cried out to the Lord, and he said, “O Lord, my God, have you even afflicted the widow by whom I am, in a sense, sustained, so that you would put to death her son?”
21 Nígbà náà ni ó sì na ara rẹ̀ lórí ọmọdé náà ní ẹ̀ẹ̀mẹta, ó sì ké pe Olúwa pé, “Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ẹ̀mí ọmọdé yìí kí ó tún padà tọ̀ ọ́ wá!”
And he stretched himself out beside the boy three times. And he cried out to the Lord and said, “O Lord, my God, let the soul of this boy, I beg you, return to his body.”
22 Olúwa sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí.
And the Lord heeded the voice of Elijah. And the soul of the boy returned to him, and he revived.
23 Elijah sì mú ọmọdé náà, ó sì gbé e sọ̀kalẹ̀ láti inú yàrá òkè náà wá sínú ilé. Ó sì fi lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́; Elijah sì wí pé, “Wò ó, ọmọ rẹ yè!”
And Elijah took the boy, and he brought him down from the upper room to the lower part of the house. And he gave him to his mother. And he said to her, “See, your son lives.”
24 Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ẹnu rẹ.”
And the woman said to Elijah: “By this, I now realize that you are a man of God, and that the word of the Lord in your mouth is true.”

< 1 Kings 17 >